×
Alaye nipa idajọ ibura pẹlu nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah, nigbati o maa n jẹ ẹbọ kekere ati nigbati o maa n jẹ ẹbọ nla.

    Ibura Pẹlu Nkan Miran

    Ti o Yatọ si Ọlọhun

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Lati ọwọ:

    Rafiu Adisa Bello

    Atunyewo:

    Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    الحلف بغير الله

    « بلغة اليوربا »

    كتبها:

    رفيع أديسا بلو

    مراجعة:

    حامد يوسف

    2015 - 1436

    Ibura Pẹlu Nkan Miran

    Ti o Yatọ si Ọlọhun

    Ohun ti o jẹ ojulowo isẹ ti Ọlọhun fi ran ojisẹ Rẹ anabi Muhammad ni sise Ọlọhun ni Ọkan soso, sise E ni aaso ati jijọsin fun Un ni Oun nikan. Idi niyi ti o fi jẹ wipe ojisẹ nla Muhammad se amojuto isẹ yii pupọ eyi tiise sise Ọlọhun ni Ọkan soso “At-taoheed”. Gbogbo ohun ti o ba jẹ wipe o le mu Musulumi kolu aala sise Ọlọhun ni Ọkan yi ni ojisẹ maa n kilọ fun awa ijọ rẹ, ti o si maa n le wa sa kuro nibẹ. Ninu awọn nkan wọnyi ni ibura pẹlu nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah.

    Idajọ ki Musulumi bura pẹlu nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun ni wipe iru ẹni bẹẹ ti se ẹbọ; nitoripe ohun ti o ba tobi ninu ẹmi ni a fi maa n bura, nkan kan kosi gbọdọ tobi lori ẹmi Musulumi ju Ọlọhun Allah lọ. Fun idi eyi, ẹniti o ba fi nkan miran bura, o da gẹgẹ bii wipe o ri nkan naa ni ohun ti o tobi ju Ọlọhun lọ ni, sise ẹbọ si Ọlọhun ni eleyi si n tumọ si. Ojisẹ Ọlọhun sọ wipe: “Ẹniyowu ti o ba bura pẹlu nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun, iru ẹni bẹẹ ti se ẹbọ si Ọlọhun tabi se aimoore si Ọlọhun” [1].

    Sugbọn ninu okodoro ọrọ ti o yẹ ki a mọ ni aaye yi ni wipe sise ẹbọ yii kiise ẹbọ nla tabi ẹbọ ti o tobi ti o le se okunfa ki Musulumi jade kuro ninu ẹsin, bikosepe ẹbọ kekere ni. Eri lori eleyi ni wipe ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] gbọ ti Umar ọmọ Khatab [Ki Ọlọhun yọnu si i] n bura, ti o n sọ wipe: Oun fi baba oun bura, ojisẹ Ọlọhun wa sọ wipe: “Dajudaju, Ọlọhun N kọ fun yin nibi ki ẹ maa fi awọn obi yin se ibura” [2]. Ojisẹ Ọlọhun sọ eleyi, kosi sọ wipe ẹniti o fi baba rẹ bura ti jade kuro ninu ẹsin Islam, bakannaa ni ko pa a lase wipe ki o se atunse Islam rẹ.

    Alfa agba Ibn Kọyyim sọ nigbati o n ka awọn iran ẹbọ kekere: ‘Ki ẹ lọ mọ nipa ẹbọ kekere, ninu apejuwe rẹ ni: sekarimi (tabi ele-awo), sise afihan si awọn eniyan ohun ti o yapa si nkan ti eniyan nse ninu tabi ni kọkọ, ibura pẹlu ẹlomiran ti o yatọ si Ọlọhun, bi ojisẹ Ọlọhun se sọ wipe: Ẹniyowu ti o ba bura pẹlu nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun, iru ẹni bẹẹ ti se ẹbọ’ [3].

    Bi o tilẹ jẹ wipe a sọ fun wa wipe ibura pẹlu ẹlomiran ti o yatọ si Ọlọhun ẹbọ kekere ni, sugbọn sibẹsibẹ Musulumi le bura pẹlu nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun ni igba miran ti ibura rẹ yi yoo si sọ ọ di ẹniti o ti jade kuro ninu ẹsin Islam, bawo ni eleyi yoo se sẹlẹ?

    Ti Musulumi ba bura pẹlu nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun, ti o wa je wipe nkan ti o fi bura naa tobi ninu ọkan rẹ gẹgẹ bii Ọlọhun se tobi ni ọkan rẹ tabi o tobi ni ọkan rẹ ju Ọlọhun lọ, nigbayi iru ẹni bẹẹ ti se ẹbọ ti o tobi eyi ti o le mu u kuro ninu ẹsin Islam.

    Alfa agba An-nawawiy [Ki Ọlọhun kẹ ẹ] sọ wipe: ‘Awọn alfa ninu masiabi wa sọ wipe: Ti ẹniti o fi nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun bura ba ni adisọkan wipe ohun ti oun fi bura tobi gẹgẹ bi Ọlọhun se tobi, iru ẹni bẹẹ ti se keeferi, o si ti se ẹbọ nla’ [4].

    Alfa agba Ibn Hajar [Ki Ọlọhun kẹ ẹ] naa sọ wipe: ‘Ti ẹniti o bura pẹlu nkan kan ba ni adisọkan wipe nkan naa tobi gẹgẹ bii adisọkan titobi ti o ni si Ọlọhun Allah, nigba naa iru ibura bẹẹ ti di eewọ, eni naa si ti di keferi pẹlu iru adisọkan bẹẹ’ [5].

    [1] Abu Daud: [3251], Tirmisi: [1535], Ahmad: [2/125].

    [2] Bukhari: [6108], Muslim: [1646].

    [3]Madaariju saalikiina: 1/344.

    [4] Raodọtu- tọọlibiina: 11/6.

    [5] Fathul baari: 11/540.