×
Alaye nipa diẹ ninu awọn nkan ti o maa n se okunfa ki adadasilẹ tan kan ni awujọ gẹgẹ bii kikọlẹ awọn onimimọ lati fi ododo ẹsin mọ awọn eniyan, ati bẹẹ bẹẹ lọ

    NINU AWỌN OKUNFA ADADASILẸ

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Lati ọwọ:

    Rafiu Adisa Bello

    Atunyewo:

    Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    من أسباب انتشار البدع

    « بلغة اليوربا »

    كتبها:

    رفيع أديسا بلو

    مراجعة:

    حامد يوسف

    2015 - 1436

    Ninu Awọn Okunfa Adadasilẹ

    Adadasilẹ ni awọn okunfa ti o pọ ti o maa n jẹ ki o tan ka ni awujọ, diẹ ninu wọn ni yii:

    Alakọkọ: Kikọlẹ awọn onimimọ lati tọ awọn eniyan si ọna ti o tọ ati eyiti o yẹ lori ohun ti o jẹ ododo ẹsin ati ilana ojisẹ: Awọn ti a gba lero pẹlu onimimọ ni awọn ti wọn mọ ododo ẹsin, ti wọn kọ ẹkọ ti o yanju nipa ọrọ Ọlọhun ati ti ojisẹ Rẹ [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] ti o si ye wọn yekeyeke. Ohun ti ẹsin n beere fun lati ọdọ awọn wọnyi ni ki wọn maa se alaye ododo ẹsin fun awọn eniyan ni awujo, ki wọn jẹ ki awọn eniyan da ododo mọ yatọ si irọ. Sugbọn nigbati irufẹ awọn onimimọ yi ba ti kọlẹ lati se ojuse wọn ni awujọ, kosi iyemeji lori wipe awọn eniyan yoo maa ro wipe gbogbo ohun ti awọn n se naa ni ẹsin. Fun idi eyi ni o se jẹ wipe onimimọ ko gbọdọ maa woran nigbati awọn alaimọkan ba n se ohun ti ko ba ẹsin mu, nitoripe ti onimimọ ko ba ti sọrọ ti ko kọ fun wọn lati ma se nkan naa, wọn yoo maa lero wipe oju ọna ni awọn wa, ododo ẹsin ni awọn si n se.

    Elẹẹkeji: Isesi awọn ti wọn fi ara jọ onimimọ sugbọn ti wọn kii se onimimọ: Ninu ohun ti o yẹ ki a mọ dajudaju ni wipe ẹniti o ba mọ ofin Ọlọhun ti o si n lo o ni a n pe ni onimimọ, kii se gbogbo ẹniti o ba ti n wọ asọ ti o jọ ti awọn onimimọ, tabi o n se gẹgẹ bii ise wọn. Itumọ yi ti dapọ ti o si ti polukuru-musu ni awujọ wa, nitoripe ọpọlọpọ ni awọn ti wọn maa n se bii alufa ẹsin sugbọn ti o jẹ wipe wọn jinna tefetefe si ẹsin, ọgọọrọ eniyan ni wọn maa n se bii ẹni Ọlọhun, ọrẹ Ọlọhun, ti o si jẹ wipe ẹni esu ni wọn. Idi niyi ti o se jẹ wipe eniyan gbọdọ mọ iyatọ laarin awọn onimimọ tootọ ati awọn okurọ, onimimọ tootọ yoo maa tẹle asẹ Ọlọhun, yoo si maa jinna si awọn iwa ẹsẹ, bakannaa ni wipe sunna ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ola Ọlọhun ki o maa ba a] ni yoo jẹ ilana rẹ. Isesi awọn ti wọn fi ara jọ onimimọ yi ni awọn eniyan yoo maa wo, ti wọn ba n se awọn adadasilẹ ninu ẹsin, awọn ọgọọrọ eniyan ni awujọ yoo lero wipe ohun ti wọn n se ba ẹsin mu, ti wọn yoo si maa kọse wọn.

    Elẹẹkẹta: Atilẹyin awọn alasẹ fun adadasilẹ ati gbigbe e l’arugẹ nitoripe o wa ni ibamu pẹlu ifẹ inu wọn: Apakan ninu awọn olori ati alasẹ maa n se atilẹyin fun adadasilẹ, ti wọn si maa n gbe e l’arugẹ nitori aini agboye ẹsin wọn, eleyi si jẹ ọkan ninu awọn ohun ti o maa n se okunfa ki adadasilẹ tan ka ni awujọ.

    Apeere eleyi pọ ni awujọ wa, ninu rẹ ni gbigbe eere awọn eniyan pataki ti wọn ti ku si orita, eyiti wọn maa n na owo ribiribi si, ti o si jẹ wipe ninu awọn adadasilẹ ti o buru jai ni o jẹ. Ninu awon apeere miran ni sise ikunlọwọ ati atilẹyin fun awọn Suufi ati awọn ti wọn jọ wọn lati maa se ọjọ ibi anabi wa Muhammad ati ọjọ ibi awọn ti wọn maa n pe ni ọrẹ Ọlọhun (waliyyu). Apẹẹrẹ miran ni kikọ ile si ori itẹ (saaree) awọn eniyan ti wọn ni oripa ni awujọ lẹyin ti wọn ba ti ku tan, ti won yoo sọ aaye itẹ wọn di ibi ti awọn eniyan yoo maa se abẹwo si, ti awọn eniyan miran yoo si maa tọrọ adua ni ibẹ tabi se ijọsin fun Ọlọhun ni ibẹ, pẹlu ero wipe aaye naa ni oore ju ibomiran lọ nitori ẹniti wọn si oku rẹ sibẹ.

    Elẹẹkẹrin: Ki adadasilẹ di baraku fun awọn Musulumi kan, ki wọn si mu u ni alaada tabi isesi wọn, eyiti yoo se okunfa ki wọn ma le fi silẹ mọ, ti o jẹ wipe ẹniti o ba fẹ le wọn kuro nibẹ tabi gba a lọwọ wọn yoo dabi wipe o fẹ gba ẹmi wọn ni; nitoripe wọn ti sọ ọ di ojulowo ẹsin wọn.

    Elẹẹkarun: Ki adadasilẹ se deede ifẹ-inu apakan ninu awọn eniyan; nitoripe ifẹ-inu maa n se okunfa isina ni.

    Eleyi ni diẹ ninu awọn ohun ti o maa n jẹ ki adadasilẹ tan ka ni awujọ. Ki Ọlọhun tọ wa si ọna ododo ẹsin Rẹ. Amin.