×
Akọsilẹ ti o n sọ nipa itumọ okun ibi, lẹhinnaa o tun se alaye ni ekunrẹrẹ awọn oore ti o wa nibi sise daadaa si awọn ẹbi ati aburu ti o wa nibi jija okun ẹbi.

    Ojuse Musulumi si Ẹbi rẹ

    [Yorùbá -يوربا ]

    Lati Ọwọ:

    Dr. Mubarak Zakariya Al imam

    Atunyẹwo:

    Rafiu Adisa Bello

    Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    مسؤولية المسلم نحو رَحِمِه.

    « بلغة اليوربا »

    كتبها:

    د. مبارك زكريا الإمام

    مراجعة:

    رفيع أديسا بلو

    حامد يوسف

    2015 - 1436

    BISMILLAHIR RAHMANIR RAHEEM

    Kinni o njẹ okun ibi tabi ẹbi rẹ?

    Okun ẹbi ni awọn ohun ti o so awọn eniyan papọ, gẹgẹ bii iya ati baba, iya iya ati baba baba, ọmọ ọkunrin tabi obinrin, awọn ẹbi baba ati iya, bakanna ni okun ibi nbẹ laarin ẹgbọn si aburo, laarin ọmọ iya kan naa , ati ọmọ baba kan naa (ọbakan), o si tun wa laarin ọmọ ẹgbọn ati ọmọ aburo, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn eniyan ti o jẹ pe inu iran kan naa ni wọn ti jade, o le jinna tabi ki o sun mọ.

    Kinni ojuse ti Islam nfẹ ki Musulumi o se si ẹbi rẹ?

    Islam mọ pataki ẹbi pupọ, idi niyi ti ko se fẹ ki o bajẹ rara, ti o si gbe ofin kalẹ, ti o si paa l’asẹ wipe: (Maa fun awọn alasun mọ rẹ ati awọn alaini ni ẹtọ wọn, ibi eleyi ni oore wa fun awọn ẹniti wọn fẹ ri oju rere Ọlọhun, ati wipe awọn ti wọn ba n se ohun ti a sọ yii, awọn ni wọn o ri ere jẹ ni ọdọ Ọlọhun) [Surat roomu: 38].

    Eleyi jẹ ki a mọ wipe ọranyan ni fun Musulumi lati maa se daada si ẹbi ati ibatan rẹ, ki o si maa fun onikaluku wọn ni ẹtọ wọn, bi o ba se ni agbara to, ati bi agbara rẹ ba se mọ.

    Bakanna ni Ọlọhun ti se ikilọ wipe okun ibi ko gbọdọ ja lati ọwọ wa, nigbati O n sọpe: (Ẹ bẹru Ọlọhun Ọba eyiti ẹ fi nbẹ ara yin, bakanna ki ẹ bẹru okun ibi, ki o ma ja lati ọdọ yin, dajudaju oju Ọlọhun to gbogbo yin). [Surat Nisaa: 1].

    Lẹyin ti Ọlọhun ti pa asẹ, ti o si se ikilọ, o gbe iya kalẹ fun ẹniti o ba ru ofin naa, ti ko si gbọ ikilọ, O sọ pe: (Ati wipe gbogbo awọn ti wọn ko mu adehun ati ileri Ọlọhun sẹ, ti wọn si tun ja okun ẹbi, eyi ti Ọlọhun pa asẹ ki wọn o maa so pọ, ki wọn si se daadaa si wọn, ti wọn si tun ba aye jẹ, awọn ti awi yii, Ọlọhun yoo gbe ikẹ jina si wọn, wọn ko si nii ri ile rere de si ni ọrun). [Surat ra`d: 25].

    Kinni anfaani ti a le ri ti a ba n se daada se ẹbi wa?

    Musulumi gbọdọ mọ daju wipe anfaani pupọ ni o wa ninu gbogbo asẹ ti Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ ba pa, anfaani ni ile aye ati ni ọrun, sugbọn kiise gbogbo anfaani yi ni a le mọ.

    Diẹ ninu awọn anfaani ti o wa fun sise daada si ẹbi niyi:

    1- O jẹ ọkan ninu amin ti a fi le mọ pe eniyan ni igbagbọ si Ọlọhun ati ọjọ ikẹyin. Anabi [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ pe: “… Ẹniti o ba ni igbagbọ si Ọlọhun ati ọjọ ikẹyin ki onitọhun maa se daada si ẹbi rẹ”.

    2- O jẹ okunfa ti arisiki eniyan yoo fi di pupọ, ti alubarika yoo fi wọ inu rẹ.

    3- O si tun jẹ okunfa ẹmi gigun fun eniyan, ti alubarika yoo fi wa ninu asiko ti eniyan yoo lo ni aye. Ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ pe: “Ẹniti o ba n fe ki Ọlọhun fun ohun ni ẹmi gigun ati arisiki ti o fẹ, ki onitọhun o maa se daada si ẹbi rẹ”.

    4- O jẹ ohun ti yoo gba eniyan silẹ ni ọdọ Ọlọhun. Ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ pe: “Gbogbo okun ibi ni yoo wa ni ọjọ ikẹyin, ti yoo si duro si iwaju awọn eniyan rẹ, ti yoo si maa jẹ ẹlẹri fun ẹni ti o ba se daada wipe o se daada si awọn ẹbi rẹ, bakanna ni yoo si maa jẹ alatako fun ẹniti ko ba se daada si ẹbi re wipe, ko se daada si awọn ẹbi rẹ”.

    5- O jẹ ọkan ninu ohun ti o le mu eniyan wọ aljannah. Ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ pe: “Ẹyin eniyan, ẹ maa salama si gbogbo ara yin, ki ẹ si maa fun awọn eniyan ni ounjẹ, ki ẹ si maa se daada si awọn ẹbi yin, ki ẹ si maa ki irun (nafilat) ni oru, ni asiko ti awọn eniyan ti sun asunwọra, ti ẹ ba se eleyi, pẹlu irọrun ni ẹ o fi wọ aljannah”.

    6- O jẹ ọkan ninu awọn ọna ti o maa n se okunfa ki Ọlọhun fẹran ẹru Rẹ, nitoripe Ọlọhun ni ifẹ si ki a se rere si ẹbi, ẹniti o ba n se rere si awọn ẹbi rẹ eyiti o jinna ati eyiti o sunmọ, Ọlọhun yoo ni ifẹ si ẹni naa.

    7- Ọlọhun ko ni d’oju ti ẹni ti o ba n se daada si ẹbi rẹ, eleyi wa ninu ọrọ ti iya wa Khadija [Ki Ọlọhun yọnu si i] sọ fun anabi nigbati o wa ninu ipaya ati ẹru jẹjẹ wipe: ‘Mo n fi Ọlọhun bura wipe Ọlọhun ko nii jẹ ki oju ti ọ ni igba kankan, nitoripe iwọ maa nse daada si awọn ẹbi rẹ…’.

    Ewu tabi aburu ti o wa nibi ki eniyan ma se daadaa si ẹbi?

    1- Ọlọhun ko ni gba gbogbo isẹ rere kankan lọwọ ẹniti o nse aburu si ẹbi rẹ. Anabi wa [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ pe: “Ọlọhun ko ni gba isẹ ẹni ti o n se aburu si ẹbi rẹ”.

    2- Ẹniti o ba n se aburu si ẹbi rẹ; ko ni ri ikẹ Ọlọhun, ibinu Ọlọhun ni yoo maa ri. Ọlọhun sọ pe: (Ati wipe gbogbo awọn ti wọn ko mu adehun ati ileri Ọlọhun sẹ, ti wọn si tun n ja okun ẹbi, eyi ti Ọlọhun pa asẹ ki wọn o maa so pọ, pẹlu ki wọn maa se daadaa si wọn, ti wọn si n ba aye jẹ, awọn ti a wi yii, Ọlọhun yoo gbe ikẹ jina si wọn, wọn o si nii ri ile rere de si ni ọrun). [Surat ra`d: 25].

    3- Ẹniti o ba n se aburu si ẹbi rẹ, ko ni wọ alujanna ni ọrun, gẹgẹ bi Anabi wa [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] se sọ pe: “Ẹniti o ba n se aburu si ẹbi rẹ, ko ni wọ aljannah”.

    4- Ẹniti o ba n se aburu si ẹbi rẹ, aye rẹ ko ni toro di ọjọ alẹ. Eleyi ni adehun ti Ọlọhun se fun okun ẹbi nigbati o da awọn ẹda tan, o sọ pe: (Idunu ni yoo jẹ fun ọ, ki n se daada si awọn ti wọn ba se daada si ọ - irẹ okun ibi-, ki nsi tun maa jẹ ki ọrọ awọn ti wọn ba se aburu si ọ; ki wọn ma ni isinmi).

    5- Ẹniti o ba n se rere si ẹbi rẹ, ko ni parun, ile rẹ ko si ni di ahoro, sugbọn ẹniti o ba n se aburu si ẹbi rẹ, iparun n bẹ fun un. Anabi wa [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ pe: “Sise rere si ẹbi ati ara adugbo, o maa n jẹ ki ilu kun” ni idakeji, aburu sise o maa n jẹ ki ilu di ahoro. [Sunan Tirmihi].

    6- O jẹ ohun ti eniyan o maa ri ẹsan gba lori rẹ ni kiakia lati aye, ki o to kan ẹsan ti ọrun. Anabi wa [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ pe: “Kosi ẹsẹ ti o to ki Ọlọhun tete fi iya rẹ jẹ eniyan ni ile aye siwaju ọrun, gẹgẹ bii ki eniyan se aburu si ẹbi rẹ”.

    Ni ipari, ki a mọ wipe daada sise si awọn ẹbi wa nikan kọ, bi ko se wipe a tun gbọdọ maa ni amumọra ati amojukuro ti wọn ba se aburu si wa, ki a si ma da rere ti a n se si wọn duro, eleyi ni ipo ti o ga julọ, anabi wa [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ pe: “Kiise ẹniti o fi rere san rere fun ẹbi rẹ ni a le sọ pe o nse daada si ẹbi, bi kose wipe ẹniti o ba nfi rere san aburu ti awọn ẹbi rẹ ba n se sii”.

    Nitori idi eleyi ki gbogbo Musulumi o pa ofin Ọlọhun mọ, ki a maa se daada si ẹbi wa.

    O se pataki ki awọn obi o se afihan awọn ẹbi wọn si awọn ọmọ wọn, ki wọn si maa mu wọn dani ni igbati wọn ba n lọ si ọdọ awọn ẹbi, eleyi ni yoo jẹ ki wọn o mọ awọn ẹbi baba ati iya wọn, ki a le ni anfaani lati mu asẹ Ọlọhun sẹ ni ododo, idi niyi ti anabi wa se sọ wipe: “Ẹ wa mimọ nipa awọn ti o jẹ iran tabi ẹbi yin, ki o le rọrun fun yin lati se daada si wọn”. [Tirmidhi:1979].