Awọn ohun ti kii jẹ ki Adua o gba
Àwọn ìsọ̀rí
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan
Full Description
Awọn ohun ti kii jẹ ki Adua o gba
[Yorùbá - يوربا ]
Lati ọwọ:
Dr.Mubarak Zakariya Al imam
Atunyẹwo:
Rafiu Adisa Bello
Hamid Yusuf
2015 - 1436
من موانع استجابة الدعاء
« بلغة اليوربا »
كتبها:
د. مبارك زكريا الإمام
مراجعة:
رفيع أديسا بلو
حامد يوسف
2015 - 1436
BISMILLAHIR RAHMANIR RAHEEM
Ọpọlọpọ eniyan nse adua, ti wọn ko ri apẹrẹ gbigba adua, ti o si jẹ wipe ọwọ ara wọn ni wọn fi da adua naa nu, nitoripe wọn nse awọn ohun ti o lodi si gbigba adua. Bẹẹ si ni Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ ti se ẹkunrẹrẹ alaye lori awọn ohun ti o le ma jẹ ki Ọlọhun gba adua eniyan. Eleyi ni koko ti a o se alaye rẹ ninu akọsilẹ yi, ki Ọlọhun se emi ati ẹyin ni ẹniti adua rẹ yoo gba.
Awọn ohun ti kii jẹ ki adua o gba:
Ninu awọn ohun ti kii jẹ ki adua o gba gẹgẹ bi Ọlọhun ati ojisẹ rẹ se sọ ni yi:
1- Ki Musulumi ma ni igbagbọ ati ifọkantan ninu Ọlọhun, iru ẹni yii yoo maa se adua pẹlu iye meji, ati ẹmi boya Ọlọhun l`egba adua oun.
2- Ki o jẹ pe inu haramu (awọn ohun ti Ọlọhun se ni eewọ) ni eniyan ti n jẹ ti o ti nmu. Gẹgẹ bii, owo ele, owo ẹyin ati abẹtẹlẹ, dukia ọmọ orukan, ati owo ti eniyan ri nibi isẹ ati okowo ti Ọlọhun ko fẹ, bii ọti, ẹlẹdẹ, ole, jibiti ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eleyi kii jẹ ki Ọlọhun gba adua Musulumi.
3- Ki Musulumi ma fi ọkan si adua ti o nse. Gẹgẹ bii ki o maa se nkan miran ni asiko ti o nse adua lọwọ, nitoripe ohun ti Ọlọhun fẹ nibi adua ni ki a dari ọkan ati ẹmi wa si ọdọ Oun (Ọlọhun), ki a si gbee jina si gbogbo nkan miran yatọ si Ọlọhun Alagbara, ni asiko ti a nse adua. Eleyi yoo jẹ ki Ọlọhun rii daju wipe Oun tobi ninu ẹmi wa ni ododo, yatọ si ọrọ ẹnu lasan. Idi niyi ti ojisẹ Ọlọhun fi sọpe: (Ọlọhun ko nii gba adua ẹniti ko ba fi ọkan si adua, ti o si muu ni awẹwa).
4- Ki ẹniti o nse adua o maa kanju lati ri gbigba adua. Ikanju gbigba adua jẹ ọkan ninu ohun ti o le ma jẹ ki Ọlọhun gba adua ẹda. Gẹgẹ bii kii eniyan o maa sọpe mo ti se adua titi Ọlọhun ko gbo adua mi, tabi ki o sọpe: o yẹ ki Ọlọhun ti gba adua mi lati igba ti mo ti n bẹ Ọlọhun, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ojisẹ Ọlọhun sọpe: (o daju wipe Ọlọhun yoo gba adua eniyan, pẹlu majẹmu ki eniyan ko ma se sọpe mo ti n se adua lati igba pipẹ, sugbọn Ọlọhun ko gbọ adua mi).
5- Ki eniyan o maa se igberaga si Ọlọhun ninu adua rẹ, gẹgẹ bii ki o sọpe: ti Ọlọhun ko ba se ohun ti mo fẹ titi asiko bayi, oun ko fẹ nkan naa mọ, tabi ki o sọpe: ti o ba jẹ pe Iwọ ni Ọlọhun ni otitọ, ti o si ni agbara, mofẹ ki O se nkan bayi fun mi, ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn isesi ikọja aaye ati igberaga si Ọlọhun Ọba. Eleyi ni ojisẹ Ọlọhun nkọ fun wa nigbati o n sọ pe: (ẹ mase maa pa Ọlọhun lasẹ, ẹ si ma la le E lọwọ, bikosepe ẹ tọrọ ohun ti ẹ ba fẹ ni ọdọ Ọlọhun, nitoripe ko si ẹniti o le halẹ mọ Ọlọhun tabi ti o le fi agidi gba nkan lọwọ rẹ).
6- Ki eniyan o maa se adua ti o le jẹ atako si ohun ti Ọlọhun n fẹ, tabi ki o maa fi adua rẹ beere ohun ti Ọlọhun ko fẹ. Gẹgẹ bii ki eniyan sọpe oun fẹ ki Ọlọhun se oun ni ojisẹ (anabi), tabi ki o maa beere lọdọ Ọlọhun ki iku o ma pa oun rara, abi ki eniyan o sẹ epe fun awọn obi rẹ, bakanna ni ki obi o sẹ epe fun ọmọ rẹ, ati ki a maa gbe ohun si oke (ariwo) fun adua, gbogbo awọn nkan wọnyi ni Ọlọhun ati ojisẹ rẹ ko fẹ ki a se. Gbogbo adua ti o ba ri bayi, Ọlọhun ko nii gba lọwọ ẹda.
7- Ki awọn eniyan kọ lati maa gba ara wọn ni iyanju lati se daada ti Ọlọhun fẹ, ki wọn si ma se ba ara wọn wi, nigbati wọn ba se aburu ti Ọlọhun ko fẹ, eyiti awọn onimimọ npe ni (al-amru bil ma`ruuf, wan- nahyu anil munkar). Eleyi wa ninu ọrọ ojisẹ Ọlọhun ti o sọ wipe: (ẹ maa pe ara yin lọ si ibi isẹ rere, ki ẹ si ma se gba ara yin laaye lati se ibajẹ, ti ẹ ba kọ, ti ẹ o se bẹẹ, ko nii pẹ; ko si nii jina ti Ọlọhun yoo fi mu iya wa ba yin lati sama (oke ọrun), ẹ o si maa pe Ọlọhun, sugbọn Ọlọhun ko ni gba adua yin).
Eleyi ni diẹ ninu awọn ohun ti o le mu ki Ọlọhun ko ma gba adua Musulumi.
Alfa agba ti orukọ rẹ njẹ ibnul Kọyyim sọ wipe: “ohun ti a le fi adua we ni nkan ija ti a fi nda oju ija kọ ọta, sugbọn nkan ija yi ko lee sisẹ, ayafi ki ẹniti o fẹ lo o ki o ni agbara, ki nkan ija naa o si ni alaafia ti o peye, pẹlu ki o ma si idiwọ kankan, ti mẹtẹẹta yi ba ti pe, ki a gba wipe ogun ti sẹ, adua yoo si di gbigba, sugbọn ti ikan ninu mẹtẹẹta ko ba si, ko si agbara lori ọta, ko le si oripa fun ohun ija”. [addau wad dawau: 26].
Nitorinaa, gbogbo ẹniti o ba nfẹ ki adua oun o maa gba, onitọhun gbọdọ mọ wipe oun ni isẹ lati se, Isẹ naa ni ki o se awọn ohun ti a ti sọ siwaju nipa okunfa ti adua fi maa n gba, ki o si jina si awọn ohun ti kii jẹ ki adua o gba, bẹẹ ni ki oun naa si duro deede lori ẹsin Ọlọhun. Ki o pa ofin Ọlọhun mọ, ki o si maa ranti Ọlọhun ni igba irọrun siwaju igba isoro, ki Ọlọhun o le baa gbọ tiẹ.