Kinni o maa n jẹ ki Adua gba?
Àwọn ìsọ̀rí
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan
Full Description
Kinni o maa n jẹ ki Adua gba?
[Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Lati ọwọ:
Dr.Mubarak Zakariya Al imam
Atunyẹwo:
Rafiu Adisa Bello
Hamid Yusuf
2015 - 1436
ما هي أسباب استجابة الدعاء؟
« بلغة اليوربا »
كتبها:
د. مبارك زكريا الإمام
مراجعة:
رفيع أديسا بلو
حامد يوسف
2015 - 1436
Ninu ohun ti o yẹ ki Musulumi o mọ nipa adua ni wipe, awọn nkankan n bẹ ti o maa n jẹ ki Ọlọhun dahun si ibeere wa, bẹẹni awọn nkankan nbẹ ti o maa n se okunfa ki adua ki o ma gba, eleyi ni apa kan ninu awọn eniyan ko mọ, ti o fi jẹ wipe wọn ko ri amin wipe Ọlọhun n gba adua wọn. Otitọ ni wipe Ọlọhun setan lati gbọ ati lati gba adua ti awa ẹda ba n se, gẹgẹ bi Alukurani se fi idi rẹ mulẹ, ti ojisẹ Ọlọhun anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o maa ba a) naa si se alaye rẹ. Bẹẹni, sugbọn lẹyin ti a ba se awọn ohun ti o yẹ ki a se, ti a si jina si ohun ti ko yẹ ki a se. Idi niyi ti o fi jẹ pe idahun si ibeere wipe: kinni o maa n jẹ okunfa gbigba adua? ni a o mu ẹnu ba ninu iwe yi.
Awọn ohun ti o njẹ ki adua o gba
Ninu amin ifẹ Ọlọhun ati ojisẹ rẹ fun awa ẹda ni wipe wọn se ẹkunrẹrẹ alaye fun wa nipa awọn ohun ti o le mu ki Ọlọhun gba adua wa , ti ohun ti a nfẹ yoo fi to wa lọwọ. Ninu rẹ ni:
1- Ki a ni ikhlas fun Ọlọhun. Itumọ rẹ ni pe: ki o jẹ wipe oju rere Ọlọhun nikan ni a nwa, Oun nikan si ni a gba wipe o le se ohun ti a nfẹ, ko tun gbọdọ si nkankan ni kọrọ tabi gbangba ti a tun gbọdọ maa reti oore lọdọ rẹ yatọ si Ọlọhun Ọba wa Allah, bi o se le wu ki nkan naa ki o tobi to, yala Anabi ni, tabi malaika, tabi alijanu, tabi wolii kan, tabi baba ati iya wa, tabi alfa, tabi ọga wa.
2- Ki a pa ofin Ọlọhun mọ, pẹlu ki a maa se ohun ti o fẹ ki a maa se ninu awọn ijọsin, yala eyiti o jẹ ọranyan, tabi eyi ti o je asegbọrẹ ti kii se ọranyan. Ọlọhun fi eyi se majẹmu nigbati O n se adehun wipe Oun setan lati dahun si ibeere wa:
(وإذا سألك عبادي عني فإني قريب أجيب دعوة الداع إذا دعان فليستجيبوا لي وليؤمنوا بي لعلهم يرشدون)
Itumọ rẹ ni pe : (Nigbati awọn ẹrusin Mi ba bi ọ leere nipa Mi, dajudaju Emi nbẹ ni tosi, Emi n jẹ ipe olupe-ipe nigbati o ba pe Mi, nitorinaa ki awọn naa maa jẹ ipe Mi, ki wọn si gba Mi gbọ ki wọn le baa mọ ọna ti o tọ). [Suuratul bakọrah: 186].
3- Ki a ni igbagbọ ati afọkantan ninu Ọlọhun wipe ọkan soso ni, O si ni agbara lati se ohun ti a n beere, a ko si gbọdọ se iyemeji wipe Ọlọhun le gba adua wa, tabi ki a tun maa fi ọkan ro wipe nkankan n bẹ yatọ si Ọlọhun ti o tun le gba adua eniyan lẹyin Ọlọhun ti o da aye ati gbogbo ẹda, gẹgẹ bi o ti se wa ninu ọgba ọrọ Alukuraani ti a fi se ẹri siwaju wipe: (Emi n jẹ ipe olupe-ipe nigbati o ba pe Mi, nitorinaa ki awọn naa maa jẹ ipe Mi, ki wọn si gba Mi gbọ ki wọn le baa mọ ọna ti o tọ). [Suuratul bakọrah: 186].
4- Ki a rii daju wipe ounjẹ ati awọn nkan ti a n lo jẹ halaal, ati wipe ọna halaal ni a ti rii. Eleyi ni ọrọ ti ojisẹ Ọlọhun sọ fun sa`d ibn abi wakọọss latari wipe ki o le di ẹni ti adua rẹ yoo maa gba, anabi sọ fun pe: (rii daju wipe hallal ni o njẹ, ti o ba se bẹẹ, Ọlọhun yoo maa gba adua rẹ).
5- Ki a fi han si Ọlọhun wipe ni ododo ni a n fẹ oore lọdọ Rẹ, itumọ rẹ ni pe: ki a fi han pe a ni bukaata ni ododo, ki a ma se se bi ẹniti o ti to tan, boya nipa isesi wa, ijoko wa, tabi awọn gboloun ti a o maa sọ jade, ati ki a fi ọkan ati ara ba adua lọ, ki iwariri ati titobi Ọlọhun ti a nba sọrọ o maa han ni ara wa ni asiko ti a nse adua. Ninu ọna ti a le fi se eleyi ni: ki a sọ wipe: Iwọ Ọlọhun ni alagbara, emi ni ọlẹ, Iwọ ni Ọlọrọ, emi ni alaini, kosi ẹnikan ti o le ran mi lọwọ ayafi Iwọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ninu awọn ọrọ ti o le se afihan wipe Alagbara ni a n ba s’ọrọ. Eleyi gangan ni emi adua, ohun si ni nkan ti Ọlọhun fẹ lati maa ri ati lati gbọ l`ọdọ wa ti a ba nse adua, kii se ki a maa se adua ninu mọsalasi sugbọn ẹmi wa ti de ọja, ati ibi isẹ wa.
6- Ki a maa ranti awọn Musulumi ọmọ iya wa -ti wọn ko si pẹlu wa- ninu adua wa, eleyi yoo jẹ ki awọn malaika o maa se iru adua ti a nse fun awọn ọmọ iyaa wa fun awa naa, gẹgẹ bi anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o ma ba a) se sọ ninu ọrọ rẹ.
7- Ki a se adua ni ori irin ajo: anfaani nla ni eleyi jẹ, ti a ba wa ni irin ajo, ki a se adua pupọ, toripe anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o ma ba a) ti jẹ ki a mọ wipe ninu adua ti Ọlọhun ko nii kọ lati gba ni adua ti oni irin ajo ba se.
8- Ki a fi ọkan si adua, ki a ma se jẹ ki nkankan gbe ẹmi wa kuro nibẹ, gẹgẹ bii ki a maa se adua ki a tun maa fi ẹrọ ibanisọrọ “hand set” sere, tabi ki a maa wo erọ mohu-maworan “television”, tabi ki a maa da si ọrọ ti awọn eniyan n sọ ni ayika wa, eleyi ntumọ si wipe ko si ẹmi wa ninu adua ti a nse, atipe adua naa ko kawa lara, iwa omugọ ni o jẹ ki a maa se bẹẹ, ni asiko ti a nba Ọlọhun sọrọ.
9- Ki a fi awọn orukọ Ọlọhun ati awọn iroyin Rẹ se adua, gẹgẹ bii: Ya Allah, ya Rahman, ya Razzaq, ya Wahab, ya Azeez, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ninu awọn orukọ Ọlọhun ti o ba bukata wa mu.
10- Ki a fi awọn isẹ rere ti a ti se fun anfaani awọn ẹda Ọlọhun eyi ti a fi sunmọ Ọlọhun, ni kọrọ tabi gbangba, ti o jẹ pe tori Ọlọhun nikan ni a fi se e - ki a fi bẹ Ọlọhun. Gẹgẹ bii ẹniti a ran lọwọ, awọn ọmọ orukan ti a san owo ile-iwe wọn, opo ti a n fun ni owo osu, ẹniti a wa isẹ fun, mọsalaasi ti a kọ, kanga ti a gbẹ fun awọn eniyan, ati bẹẹbẹẹ lọ.
11- Ki a se adua ni iforikanlẹ ni ori irun, gẹgẹ bi anabi se jẹ ki a mọ wipe asiko yi ni eniyan sunmọ Ọlọhun julọ, nitorinaa ki a maa se adua pupọ, ki a si gba wipe Ọlọhun yoo gba adua wa, yoo si dahun awọn ibeere wa.
12- Ki a se adua nigbati adiẹ akukọ ba n kọ. Ojisẹ Ọlọhun lo sọpe: (Ti ẹ ba gbọ ti akukọ ba nkọ, ẹ tete maa se adua, ki ẹ beere oore lọdọ Ọlọhun, nitoripe malaika ikẹ ni ori ti o fi nkọ).
Bawo ni o se yẹ ki musulumi o se adua?
1- Ki o fi ọpe fun Ọlọhun ati asalatu bẹrẹ adua.
2- Ki o se aluwala ki o to bẹrẹ adua.
3- Ki o kọ oju si Kibla.
4- Ki o tẹ ọwọ mejeeji si ọdọ Ọlọhun.
5- Ki o kọkọ se adua fun araarẹ, ki o to se fun ẹlominran.
6- Ki o sọ asọyan ju ohun ti o n fẹ l`ọdọ Ọlọhun.
7- Ki o sun ẹkun si Ọlọhun.
8- Ki o ranti awọn ọmọ iya rẹ Musulumi ninu adua rẹ.
9- Ki o se adua ni pẹlẹpẹlẹ, ti ko ni ariwo.
10- Ki o sọ awọn asiko gbigba adua.
11- Ki o beere ohun ti o nfẹ ni ẹẹmẹta.
Eleyi jẹ diẹ ninu awọn okunfa gbigba adua ati ọna ti o yẹ ki Musulumi o fi maa se adua.
Ni ipari, o yẹ ki a mọ wipe ọna mẹta ni Ọlọhun maa n gba adua si, gẹgẹ bi ojisẹ Ọlọhun se sọ:
Alakọkọ: O le fun wa ni ohun ti a beere fun ninu adua wa.
Ẹlẹẹkeji: O le fi adua naa gbe aburu nla kan jinna si wa.
Ẹlẹẹkẹta: O le ba wa tọju adua naa di ọrun, ki o le baa wulo fun wa. Nitorina ti a ba n se adua, ki a mọ wipe ibi ti o ba wu Ọlọhun ni o le gba adua naa si, toripe Oun ni o mọ kọrọ ati gbangba, Oun ni o mọ ohun ti o kan ninu ọrọ aye wa, fun idi eyi, ti a ba ti se adua bi o se tọ ati bi o se yẹ, ki a gba wipe Ọlọhun ti gbọ, O si ti gba.
Wal hamdulillah Rabbil A’lamin.