DIẸ NINU ADISỌKAN AWỌN ALASEJU NINU AWỌN SUUFI
Àwọn ìsọ̀rí
Full Description
DIẸ NINU ADISỌKAN AWỌN ALASEJU NINU AWỌN SUUFI
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Lati ọwọ:
Rafiu Adisa Bello
Atunyewo:
Hamid Yusuf
Abdul-hamiid Osiofit
2014 - 1436
من عقائد غلاة الصوفية
« بلغة اليوربا »
كتبها:
رفيع أديسا بلو
مراجعة:
حامد يوسف
عبد الحميد أوسوفيت
2015 - 1436
DIẸ NINU ADISỌKAN AWỌN ALASEJU NINU AWỌN SUUFI
Alakọkọ: Adisọkan wọn nipa Ojisẹ Ọlọhun:
Orisirisi adisọkan ni awọn alaseju ninu awọn suufi ni si ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a], o nbẹ ninu wọn ẹniti o gba wipe ojisẹ Ọlọhun ko de ipo ti awọn de atipe ko ni imọ ijinlẹ ti awọn waliyyi ninu suufi ni, gẹgẹ bi enikan ninu wọn ti orukọ rẹ njẹ Abu Yẹsiid Al-bustọọmi ti sọ: “Awa ti wọ inu odo kan ti o jẹ wipe awọn Anabi Ọlọhun duro si ẹti-bebe rẹ, ti wọn ko le wọ ọ”.
Bakannaa, awọn kan ninu wọn gba wipe Anabi wa Muhammad [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] ni olori aye, wọn tun sọ wipe Anabi gan an ni o wa ni ori itẹ ọla Al-‘arashi, ati wipe gbogbo sanma ati ilẹ ati itẹ Al-‘arashi ati aga ọla Ọlọhun Al-kursi lati ibi imọlẹ ojisẹ Ọlọhun Muhammad ni sise ẹda rẹ ti waye. Wọn tun maa n sọ wipe Anabi wa Muhammad ni ẹda alakọkọ ni aye yii, eleyi rinlẹ lati ọdọ ẹnikan ti orukọ rẹ njẹ Ibn ‘Arọbi ati awọn ti wọn n tẹle ilana rẹ.
O si n bẹ ninu awọn alaseju ninu awọn suufi yi ẹniti o jẹ wipe ko ni adisọkan awọn ohun ti a sọ siwaju yi, o gba wipe eniyan ti Ọlọhun Allah se ẹda rẹ ni Anabi wa Muhammad [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sugbọn sibẹsibẹ o maa n wa atẹgun lọ si ọdọ Ọlọhun pẹlu orukọ ojisẹ, eleyi si yapa si oju ọna awọn ti wọn n tẹle sunna ojisẹ Ọlọhun Ahlu sunna wal-jamaa’a.
Ẹlẹẹkeji: Adisọkan wọn si awọn ti a n pe ni waliyyul-lahi (Ọrẹ Ọlọhun):
Itumọ waliyyul-lahi ni ẹniti o fẹran Ọlọhun ti Ọlọhun naa si fẹran rẹ, majẹmu ti o maa n jẹ ki Musulumi di waliyyul-lahi ni ki o ni igbagbọ ti o yanju si Ọlọhun, ki o maa bẹru Ọlọhun, ki o si maa se isẹ rere ti Ọlọhun pasẹ rẹ ninu tira rẹ Alukuraani ati nibi sunna ojisẹ Rẹ.
Sugbọn ni ọdọ awọn alaseju ninu awọn suufi itumọ waliyyul-lahi yatọ si eleyi. Ninu awọn adisọkan ti awọn alaseju yii maa n ni si ẹniti wọn n pe ni waliyyul-lahi ni wipe awọn kan ninu wọn gba wipe ẹniti o jẹ waliyyul-lahi ni ọla ni ọdọ Ọlọhun ju Anabi Ọlọhun lọ!! O si n bẹ ninu wọn ẹniti o ni adisọkan wipe waliyyul-lahi se deede pẹlu Ọlọhun ninu awọn iroyin Rẹ!!! Wọn maa n sọ wipe waliyyul-lahi naa maa n da ẹda, o maa n pese jijẹ mimu, o maa n sọ oku di alaaye, o si maa n sọ alaaye di oku, bakannaa o maa n kopa ribiribi nibi idari aye.
O n bẹ ninu awọn alaseju yi bakannaa, ẹniti ko ni adisọkan yii, sugbọn ti o maa n fi waliyyul-lahi se alagata laarin rẹ si Ọlọhun Allah, yala nigbati wọn ba wa ni aye tabi lẹyin ti wọn ba ti ku tan.
Ni otitọ ati ni ododo, ohun ti o yẹ ki a fi ye ara wa gẹgẹ bii Musulumi, ẹniti o ni igbagbọ si Ọlọhun ati ojisẹ rẹ ni wipe gbogbo awọn adisọkan ti a sọ siwaju yi jinna tefetefe si adisọkan awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun Saabe, o si jinna si ohun ti Islam pe awa Musulumi si. Jijẹ waliyyul-lahi ninu ẹsin ododo da lori awọn n kan wọnyi:
- Ki eniyan jẹ Musulumi ti o ni igbagbọ ododo si gbogbo awọn origun igbagbọ mẹfẹẹfa.
- Ki o jẹ olubẹru Ọlọhun.
- Ki o maa se isẹ rere bi Ọlọhun se pasẹ rẹ ninu tira Rẹ Alukuraani ati nibi sunna ojisẹ Rẹ.
Ninu ẹsin ododo, waliyyu-lahi ko ni agbara kankan fun ara rẹ, ko le da nkankan se fun ara rẹ ayafi ohun ti Ọlọhun ba se fun un, bawo ni a se wa le sọ wipe yoo maa dari aye tabi se nkankan fun ẹlomiran!
Ọlọhun sọ wipe: {Sọ pe: Dajudaju, emi ko ni agbara lati se aburu kan tabi oore kan fun yin} [Suuratu Jinni: 21].
Ni ipari, a bẹ Ọlọhun ninu aanu rẹ ki o ma jẹ ki a sina, ki o si se wa ni ẹniti yoo le maa tẹle oju ọna ti ojisẹ Rẹ rin pẹlu awọn Saabe ti wọn fi ri ojurere Ọlọhun ni aye ati ọrun. Amin.