Pataki Iranti Ọlọhun
Àwọn ìsọ̀rí
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan
Full Description
Pataki iranti Ọlọhun
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Dr.Mubarak Zakariya Al imam
Atunyẹwo:
Rafiu Adisa Bello
2015 - 1436
أهمية ذكر الله
« بلغة اليوربا »
د. مبارك زكريا الإمام
مراجعة:
رفيع أديسا بلو
2015 - 1436
ỌLA ATI ANFAANI TI O WA NINU IRANTI ỌLỌHUN.
Gbogbo musulumi ni wọn gba wipe, Ọlọhun Allah ni o da awọn, ati gbogbo nkan ti o wa ni aye ati ọrun, Ọlọhun se awọn nkan wọnyii nitori idi pataki kan, ohun naa ni ki a le maa se ijọsin fun Oun nikan soso. Iranti Ọlọhun si jẹ ọkan pataki ninu ọna ti a fi le se ijọsin fun Ọlọhun.
KINNI ITUMỌ IRANTI ỌLỌHUN, BAWO NI A SI SE NSE E?
Itumọ iranti Ọlọhun ni ki eniyan ma gbagbe Ọlọhun, ni eyikeyi ipo ti o ba wa, gẹgẹ bi Ọlọhun se fẹ, ati ni ibamu si ilana ti anabi wa Muhammad (ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma a ba a) gbe kale.
Orisirisi ọna ni a le fi se iranti Ọlọhun, a le se iranti Ọlọhun pẹlu ọkan, gẹgẹ bii ki a maa woye si awọn isẹ ribiribi ti Ọlọhun se ninu aye, yala lara awa ẹda eniyan, ẹranko, oke, ilẹ, ibu odo ati bẹẹbẹẹ lọ, ninu awọn nkan ti Ọlọhun da.
Bakanna, a tun le fi ahan (ẹnu) se iranti Ọlọhun, ti a o maa sọ awọn gbolohun orisirisi jade lẹnu, gẹgẹ bii:
“laa ilaaha illallah”.
“subhaanallah walhamdulillah allahu akbar”.
“laa haola walaa kuwwata illa billahil aliyul adheem”. “hasbunallahu wa ni’mal wakil”.
“astagfirullah”.
“bismillah”.
“Alhamdulillah”. ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) sọ fun ọkan ninu awọn ọmọlẹyin rẹ wipe: (maa fi ahan rẹ se iranti Ọlọhun ni igba gbogbo) [1].
Bakannaa, Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma a ba a) tun sọ wipe: (Ẹniti o ba n ranti Ọlọhun ni ọdọ ara rẹ, Ọlọhun naa yoo maa ranti rẹ ni odo ara Rẹ, ẹniti o ba si n se iranti Ọlọhun laarin awọn ero kan (ọpọlọpọ eniyan), Ọlọhun naa yoo se iranti rẹ laarin awọn ero ti o dara, ti o si tun pọ ju tirẹ lọ) [2], iyen ni wipe Ọlọhun yoo maa se iranti ẹni naa laarin awọn malaika.
ỌLA TI O WA NINU IRANTI ỌLỌHUN.
Iranti Ọlọhun jẹ ọkan ninu awọn ọna ti Ọlọhun fẹ ki a fi maa sin Oun, o si tun jẹ ijọsin ti a le fi ara ati ọkan se. Ọlọhun pa lasẹ ninu Alukurani ninu ọpọlọpọ aaya Rẹ wipe ki a maa se iranti Oun.
Ojise Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma a ba a) naa se alaye ọla ti o wa fun iranti Ọlọhun. Ni bayi, a o sọ diẹ ninu awọn ọla ti o wa fun iranti Ọlọhun .
1- Iranti Ọlọhun jẹ ọkan ninu awọn ijọsin ti Ọlọhun nfẹ, ti O si pa awa Musulumi lasẹ wipe ki a maa se e. Ọlọhun sọ wipe: (Ẹ maa ranti Mi, Emi naa yoo maa ranti yin). [Suratul Bakora: 152].
2- Iranti Ọlọhun jẹ idi kan pataki ti Ọlọhun fi se ọti mimu ni eewọ, nitoripe ọti yoo gba iranti Ọlọhun sile lọwọ ọmuti, gẹgẹ bi o ti wa ninu Suuratul maaida, aaya (91).
3- Nitori iranti Rẹ ni Ọlọhun se pa a lasẹ wipe ki gbogbo awa ẹrusin Oun maa se ijọsin fun Oun.
4- Iranti Ọlọhun jẹ ijọsin kan ti Ọlọhun yoo fi iru rẹ se ẹsan fun ẹniti o ba se e, gẹgẹ bi Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) se sọ wipe : (Ẹniti o ba nranti Ọlọhun ni ọdọ ara rẹ, Ọlọhun naa yoo maa se iranti ẹni naa ni ọdọ ara Rẹ, ẹniti o ba nse iranti Ọlọhun laarin awọn ero kan (ọpọlọpọ eniyan), Ọlọhun naa yoo maa se iranti rẹ laarin awọn ero ti o dara, ti o si tun pọ ju tirẹ lọ), itumọ eleyi ni wipe Ọlọhun yoo maa se iranti ẹni naa laarin awọn malaika.
5- Ẹniti o ba nse iranti Ọlọhun ni ẹniti o wa laaye ni tootọ ati ni ododo, Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) sọ pe: (apejuwe ẹniti o nranti Ọlọhun ati ẹniti kii ranti Ọlọhun, o da gẹgẹ bii apejuwe alaaye ati oku) [3].
6- Iranti Ọlọhun jẹ ọkan ninu awọn nkan ti Ojisẹ Ọlọhun (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) maa nse ni gbogbo igba, ti o si maa nse awọn ọmọlẹyin rẹ ni ojukokoro si sise rẹ, eleyi si jẹ ẹri ti o rinlẹ lori pataki iranti Ọlọhun.
[1] Mustadrak ala as-sahiihaen: (1755).
[2] Mustadrak ala as-sahiihaen: (7689).
[3] Shihil Bukhari: (5955).