×
Fatwa yi je idahun si ibeere ti awon Musulumi maa n beere nipa lilo awon aaya Al-kurani lati fi se iwosan, yala ki eniyan ka a ni tabi ki o han si ori nkan ti o mo ki o si fo o, leyinnaa ki o mu u.

    IDAJO LILO AWON AAYA

    AL-KURANI FUN IWOSAN "RUKYA"

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia

    Eni ti o tumo re ni: Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    حكم الرقية بالآيات القرآنية

    « بلغة اليوربا »

    الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء

    في المملكة العربية السعودية

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    Idajo Lilo Awon Aaya Al-kurani Fun Iwosan (Rukya)

    Ibeere Eleekeji Fatwa (143)

    Ibeere:

    Ti eniyan kan ti ara re ko ya ba beere pe ki enikan ko awon aaya Al-kurani fun oun, ti eni naa wa ko o fun un si inu nkan ti o see fo, gege bii walaha, ti o si so fun wipe ki o mu u, nje eleyi leto bi?

    _______________________________________________

    Idahun:

    Irufe ibeere yi ti waye ri ni Daarul- iftaahi idahun re si niyi: Kiko awon aaya Al-kurani si inu takada tabi walaha ki eniyan wa fo o leyinnaa ki o mu u o leto ninu esin Islam. Oro Olohun- mimo fun Un- so wipe: {Awa so kale ninu Al-kurani ohun ti o je iwosan ati ike fun awon onigbagbo ododo} [Suuratu Israai: 82]. Fun idi eyi, Al-kurani je iwosan fun emi ati ara.

    Al-haakim ati Ibn Majah gba egba oro wa lati odo Ibn Mashood- ki Olohun yonu si i- wipe Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba- so bayi pe: (O di owo yin [eyin ijo mi] ki e maa se anfaani nibi awon nkan iwosan meji kan, awon naa ni: Oyin ati Al-kurani) [1].

    Bakannaa, ninu egba oro ti Ibn Majah gba wa lati odo Aliy- ki Olohun yonu si i- Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- so wipe: (Oogun ti o dara julo [fun iwosan emi ati ara] ohun naa ni Al-kurani) [2].

    Ibn sinniy naa gba egba oro kan wa lati odo Ibn Abbaas- ki Olohun yonu si i- o so wipe: "Ti ibimo ba nira fun obinrin aboyun, ki o mu takada [tabi nkan miran ti o le ko nkan si ara re] ti o si je ohun ti o mo, ki o wa ko awon aaya wonyi: {suuratu ahkoofi: 35}, {suuratu naasiaati: 46}, {suuratu yuusufu: 111}, leyinnaa ki o fo o, ki o wa fun aboyun naa mu, ki o si fon on si ikun re ati oju re". Bakannaa Ibn Koyyim- ki Olohun ke e- so wipe: "Khallaal so wipe: Abdullahi ibn Ahmad so pe: Mo ri baba mi [ti ise Imaam Ahmad] ti o maa nko fun obinrin aboyun ti ibimo re ba nira, o maa nko hadiisi Ibn Abbaasi yi si inu awo funfun ti o mo: (La ilaha illa Allahu Al-Haleem Al-Keriim, subhana-Llahi Robbil- Arshil- Keriim), {suuratu fatiha: 2}, {suuratu ahkoofi: 35}, {suuratu naasiaati: 46}" [3].

    Khallaal tun so wipe: "Abu bakr Al-marwasiy fun mi ni iro pe okunrin kan wa ba Abu Abdullahi [ti ise Imaam Ahmad] o wa so fun un pe: Mo pe ire Abu Abdullahi, se o le ko nkan kan fun obinrin aboyun kan ti ibimo re ti nira lati bii ojo meji, o wa so bayi pe: so fun oko re wipe ki o mu awo ijehun ti o tobi ti o si mo pelu eso saafaraan wa, mo wa ri i ti o nko awon aaya yii fun awon eniyan ni igba ti ko ni onka".

    Ibn Koyyim- ki Olohun ke e- tun so wipe: "Apa kan ninu awon eni isaaju ninu esin fi ara mo o pe ki eniyan ko awon aaya Al-kurani si ibi kan leyinnaa ki o fo o mu. Mujaaid so wipe: Ko si aburu nibi ki eniyan ko awon aaya Al-kurani leyinnaa ki o fo o, ki o si fun alaisan mu, beenaani Abu Kilaaba so".

    Awon Tira Ti A Se Anfaani Ninu Won:

    [1] Al-mustadrak (4/403), Sunan Ibn Majah (2/1142).

    [2] Sunan Ibn Majah (2/1158, 1169).

    [3] Saadul-ma'adi: (3/381).