×
Asepo ti o ni alubarika ni igbeyawo je laarin okunrin ati obinrin. Esin Islam gbe awon ilana kan kale fun Musulumi l’okunrin ati l’obinrin lati tele fun igbesi aye alayo. Eleyi ni ohun ti akosile yi so nipa re.

    IGBEYAWO NINU ISLAM

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    الزواج في الإسلام

    « بلغة اليوربا »

    رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    IGBEYAWO NINU ISLAM

    Itumo Igbeyawo:

    Igbeyawo ninu Islam je asopo ti o ni alubarika laarin okunrin kan ati obinrin kan, eyi ti yoo so enikookan ninu awon mejeeji di eleto enikeji re, ti won yoo si bere irin-ajo olojo gbooro ni ile aye yii. Won yoo wa bayi pelu ife ati ifowosowopo, enikan ninu won yoo maa ri ifokanbale lodo enikeji re, ti ibagbepo won yoo si maa fun awon mejeeji ni alaafia ati igbadun aye.

    Kinni Erogba Igbeyawo Ninu Islam?

    Erongba igbeyawo ninu Islam ni lati pile idile Musulumi. Idile Musulumi ni opomulero fun awujo Islam ti o dara, eyi ti awon eniyan re yoo je awon eniti won ni oripa rere ni ile aye, ti won yoo maa fi owo sowopo lori daadaa ati iberu Olohun, ti won yoo si maa sare alapantete lo sibi awon ise oloore.

    Kinni Opomulero Idile Musulumi Yi?

    Laisi iye meji nibe, obinrin rere ni opomulero fun idile Musulumi ti o dara, oun ni eekan re, oun naa si ni ipile re. Obinrin rere yi naa si ni igbadun aye fun okunrin, oun ni adun ti o ga ju fun okunrin ni aye yii, gege bi o ti se wa ninu hadiisi ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ti o so pe: "Ile aye yii ile igbadun ni, eyi ti o si dara julo ninu igbadun re naa ni obinrin rere". [Muslim].

    Olohun se eda okunrin ni eniti yoo maa se igbiyanju, ti yoo maa jade ni ile re ni aaro ti yoo si maa wa jije ati mimu fun awon ebi re ni ona ti o to ti o si ba ofin Olohun mu. Nigbati o ba nse awon igbiyanju wonyi, ki a bi ara wa leere, nje o ni bukaata si eniti yoo maa pese ona irorun fun un? Nje o ye ki o ni eniti yoo ran an lowo lati ri ifayabale ati isinmi bi?

    Idera nla ni o je fun okunrin ki o ri eniti yoo gbo bukaata yi fun un, idi niyi ti o se je wipe ojuse alakoko fun obinrin rere ni odo oko re ni ki o se ara re ni aaye isinmi fun oko re, ki o se ara re ni okunfa ifokanbale fu un.

    Igbesi aye toko-taya je irin-ajo kan ti o gun pupo, obinrin Musulumi si wa ni ipo olubanidowopo pelu oko re. Nigbati oro wa ri bayi, a je wipe olukuluku gbodo fi ara bale ki o si se suuru nigbati o ba fe s'esa iyawo tabi oko, wiwa oko tabi iyawo kii se ohun ikanju rara, ohun ti o gba pelepele ati ifarabale ni.

    Ti o ba je wipe okunrin s'esa iyawo re pelepele ati pelu ifarabale, ti obinrin naa si s'esa oko re pelu pelepele ati ifarabale ohun ti yoo je abajade eleyi ni idile alayo, nitoripe enikookan ninu won s'esa ohun ti o wu u, eyi ti yoo si se okunfa ki afijo wa laarin awon mejeeji nibi irisi, nibi ohun ti won fe ati nibi erongba won.

    Ninu ohun ti o lewu julo ni ki asise kan sele nibi ipilese igbesi aye toko-taya nitoripe eleyi maa nse okunfa ki ajosepo naa fi idi ﷺ‬'emi. Nibi iru igbesi aye toko-taya ti o ba ri bayi obinrin yoo ri wipe oun ko le fun oko oun ni ohun ti o l'eto si gege bii ife ti o jinle, ifokanbale ati beebee lo.

    Kinni Islam fe ki Okunrin se Nigbati o ba nwa Iyawo?

    Nitoripe esin Islam gbero rere ro Musulumi l'okunrin, idi niyi ti o se se e ni ojukokoro ti o si toka re si iru obinrin ti o ye ki o maa wa gege bii iyawo fun un, nitori ki igbadun le wa fun un ni aye yii, ti yoo si ni ifokanbale lati se ijosin fun Olohun re. Islam se okunrin ni ojukokoro si awon iroyin kan lara awon omobinrin Musulumi ti yoo fi ri eniyan rere lati fi se aya. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- so wipe: "Awon eniyan maa nfe obinrin nitori awon nkan merin kan: Nitori owo re, tabi nitori iran re, tabi nitori ewa re, tabi nitori esin re, se ojukokoro si eyi ti o l'esin ki o ma baa di eniti yoo m'ofo nigbeyin" [Bukhari: 5090, Muslim: 1466].

    Ninu Aponle Ti Esin Islam Se fun Obinrin:

    Ninu aponle ti esin Islam se fun obinrin ni wipe o fun un ni eto lati s'esa okunrin ti o ba feran lati je oko re. Ni otito, omobinrin ni bukaata si imoran lati odo awon obi re; nitoripe awon mejeeji ni iriri ju u lo nipa oro aye, bakanna ni won si mo ohun ti o wulo fun un ti o si le se e ni anfaani ju u lo, sugbon sibesibe esin Islam ko fun won ni ase lati je omobinrin won nipa wipe ki o fe eniti ko ba ni ife si. Awon oro ojise Olohun ti o duro gbagba ti omobinrin ti o si nfi eto re rinle lori alamori yi po pupo, ninu re ni:

    Hadiisi ti o wa lati odo Khansa' omo Khidaam ti o nso pe: Baba mi fi mi fun omo egbon re ti o si je eniti emi ko feran, eyi ti o mumi ke gbajari lo ba ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ojise Olohun wa so fun mi pe: "Gba ohun ti baba re se fun o". Mo wa so wipe: Emi ko fe ohun ti baba mi se fun mi. Ojise Olohun wa so fun mi pe: "Maa lo, ko leto lati fi o fun eniti iwo ko feran, ki o lo fe eniti o ba wu o". Lehinnaa mo wa so wipe: Mo ti gba ohun ti baba mi se, sugbon ohun ti mo fe se ni wipe mo fe ki awon obinrin mo pe awon obi ko ni eto lati je omobinrin won nipa ki o fe eniti ko ni ife si. [Fathul Baari: Oro nipa bi okunrin ba fi omobinrin re l'oko fun eniti ko ni ife si, irufe igbeyawo bee ko ba esin mu].

    Ninu hadiisi miran, ojise Olohun so pe: "A ko gbodo fi abileko l'oko titi ti a o fi gba ase lati odo re, a ko si gbodo fi omoge l'oko titi ti a o fi gba iyonda re". [Bukahri: 5136, Muslim: 1419].

    Nitori esin Islam fe gbogbo ohun ti o je anfaani fun omobinrin Musulumi ni o se gba awon obi re ni imoran wipe ki won se amojuto ohun ti yoo se omo won ni anfaani julo nipa oro eniti o maa je oko fun un. Islam nso nipa awon iroyin ti o dara julo ti o ye ki awon obi omobinrin wa, ki won si woye si ni ara eniti yoo je oko fun omobinrin won, ki won to fi owo si i, ki won si to yonu si i. Ojise Olohun so pe: "Nigbati eniti eyin ba yonu si esin re ati iwa re ba wa bayin lati fe omobinrin yin, ki e fi fun un, ti eyin ko ba se bee adanwo yoo maa sele lori ile ati ibaje ti o tobi". [Tirmisi:1084, Mishkaatul Masoobih: 3090].

    O dara julo ki awon obi mejeeji ko eko ninu ohun ti esin Islam npe awa Musulumi si yi, ki won mase maa je awon omobinrin won nipa lati fe eniti won ko ni ife si, nitoripe lara iwa abosi ati fifi eto eniyan dun un ni eleyi wa.

    Nigbati o wa je wipe awon obi omobinrin ko ni eto lati je omo won nipa lati je aya fun okunrin ti ko ni ife si eyi fi han wa pe elomiran ti o yato si awon obi ko tile l'eto rara lati se bee. Eleyi yoo je ki a mo asise nla gbaa ti awon kan ti won npe ara won ni olori ijo Musulumi maa nse, ti won yoo so ara won di apase waa ti kii laagun lori awon omobinrin Musulumi, ti won ko si je obi tabi alagbato fun won sugbon ti won yoo paa ni dandan fun awon omobinrin bee wipe ki won maa je aya fun awon eniyan ti won ko ni ife si; nitoripe awon omobinrin yi je omo ijo won. Ojuse Musulumi ni ki o maa tele oju ona Olohun ati ilana ojise lori gbogbo nkan. Ojise Olohun so wipe: "Kosi titele fun eda kan nibi ohun ti yoo mu eniyan kan se Olohun Adeda". [Sherhu Ssunna: 2455, Mishkaatil Masoobih: 3696].

    Kinni Ohun Ti O Ye Ki O Je Osunwon Fun Omobinrin Musulumi Nigbati O ba Fe Yan Oko?

    O je oranyan fun omobinrin Musulumi ti o ni agboye esin re ki o ni osunwon ti yoo gbe kale nigbati o ba nwa olubadowopo fun irin-ajo aye re ti o gun gbooro, nigbati o ba fe sa esa eniti yoo je oko re ati olowo ori re.

    Omobinrin Musulumi ko gbodo maa wo didara ni oju, giga ni ipo, pipo ni oro ati awon iroyin miran ti awon omugo ninu awon omobinrin miran maa nwo. Ohun ti o se pataki ki omobinrin Musulumi maa wo ti yoo si maa se akiyesi re lara eniti yoo je aya fun ni esin ati iwa, gege bi o ti se wa ninu oro ojise Olohun ti o so wipe: "Nigbati eniti eyin ba yonu si esin re ati iwa re ba wa bayin lati fe omobinrin yin, ki e fi fun un". Nitoripe esin ti o peye ati iwa ti o dara ni opomulero fun igbesi aye alayo fun toko-taya, awon nkan mejeeji yi si ni o niye lori julo ninu ohun ti o ye ki okunrin Musulumi ni.

    Abajade Titele Ilana Ojise Olohun ati Ilana Esin Islam Ninu Eto Igbeyawo:

    Gbogbo ohun ti o je daradara patapata ni o wa ninu ohun ti ojise Olohun ba pa awa Musulumi lase re, nigbati omobinrin Musulumi ba tele ilana ojise Olohun nibi iroyin ti o ye ki o wa lara eniti yoo je oko fu un, ti Musulumi l'okurin naa si tele ohun ti ojise toka re si nigbati o ba nwa aya, kosi iye meji wipe awon igbese yi je ipilese fun igbesi aye loko-laya ti yoo yege ti yoo si tu oko re de ebute ogo.

    Pelu aanu lati odo Olohun Alagbara lori ohun gbogbo, ife, aanu, ifowosowopo, ifokantan, riran ara eni lowo ati ibagbepo daradara ni yoo maa wa laarin iru awon toko-taya bayi. Adehun Olohun yoo si sele lori awon mejeeji bi O ti se so ninu oro Re pe: (Atipe awon obinrin rere [ni won l'eto si] awon okunrin rere, atipe awon okunrin rere [ni won l'eto si] awon obinrin rere, irufe awon wonyi ni A ti mo won kuro nibi [isokuso] ti won nso si won. Won si ni aforiji ati arisiki ti o ni aponle). [Suuratu Nuur: 26].

    Ni ipari, a nse ni adua wipe ki Olohun se titele ofin esin Islam ati ilana ojise Olohun ni irorun fun gbogbo awon odo Musulumi; ki won le ri aye yi gbe pelu irorun, ki won si le je omo Al-janna ni orun. Amin.