×
Itumo ijeri mejeeji ati Pataki won: akosile yi so ni soki itumo ijeri mejeeji ati bi o ti se pataki ki Musulumi mo paapaa re pelu ki o ni adisokan ti o rinle fun itumo re

    Itumo ati Pataki Ijeri Mejeeji

    (LA ILAHA ILLA ALLAH, MUHAMMADU ROSUULU LLAH)

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    معنى الشهادتين وأهميتها

    « بلغة اليوربا »

    رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    Itumo ati Pataki Ijeri Mejeeji: (LA ILAHA ILLA ALLAH, MUHAMMADU ROSUULU LLAH)

    Alakoko: Itumo (LA ILAHA ILLA ALLAH):

    Itumo ijeri yi ni ki eniyan gba pelu okan re pe kosi eni kankan ti o leto si ijosin ni ti ododo ayafi Olohun Allah nikan soso, kosi orogun fun Un ninu awon ijosin ti a nse fun Un, beeni kosi orogun fun Un ninu ola Re.

    Olohun- Mimo fun Un- so wipe: (Atipe Emi ko se eda alijonu ati eniyan lasan ayafi ki won le maa sin Mi) [Q:51, 56].

    Olohun- ti Ola Re ga- tun so wipe: (Atipe Oluwa re pase pe: E ko gbodo sin nkan kan ayafi Oun nikan) [Q: 17,23].

    O je dandan fun Musulumi ki o ni adisokan ti o fi ese rinle fun itumo gbolohun yii gege bi o se je dandan ki o maa wi i pelu enu re.

    Ijeri pe kosi elomiran ti ijosin to si ni ti ododo ayafi Olohun Allah, ohun naa ni a npe ni sise afomo ise ijosin fun Olohun Allah, eyi tii se majemu alakoko ti yoo maa je ki ise Musulumi je atewogba ni odo Olohun Allah.

    Olohun- Mimo fun Un- so wipe: (A ko pa won lase ayafi pe ki wo josin fun Olohun, ki won se afomo esin fun Un) [Q: 98,5].

    Eleekeji: Itumo (MUHAMMADU ROSUULU LLAHI):

    Itumo ijeri yii nipe ki Musulumi maa tele ase ti ojise Olohun anabi Muhammad ba pa a, ki o si maa gba gbogbo ohun ti o ba so ni ododo, ki o si maa jinna si ohun ti o ba ko fun un, ki o si mase josin fun Olohun Allah pelu nkan kan ayafi ohun ti Anabi naa ba se ni ijosin.

    Olohun- ti Ola Re ga- so wipe: (Atipe ohunkohun ti ojise naa ba fun yin e gba a, ohunkohun ti o ba si ko fun yin e jinna si i) [Q: 59,7].

    Olohun- mimo fun Un- tun so wipe: (Wipe: Bi eyin ba je eniti o nferan Olohun, e tele mi, Olohun naa yoo maa feran yin) [Q: 3,31].

    O je dandan fun Musulumi ki o ni adisokan ti o rinle pelu gbolohun yii gege bi o ti se je dandan ki o maa wi i pelu enu re.

    Itumo ijeri pe anobi Muhammad ojise Olohun ni, ohun naa ni o nse okunfa ki ise ijosin wa ni ibamu pelu bi o ti ye ki Musulumi se e, eyi ti o je majemu eleekeji ninu awon majemu ti yoo maa se ijosin ni atewogba ni odo Olohun Allah.

    Eleeketa: Pataki ijeri mejeeji:

    (1) Apapo awon ijeri mejeeji yi ni origun alakoko ninu awon origun esin Islam maraarun, origun yii naa ni o je ipile esin, ti o si se pataki julo.

    (2) Ijeri mejeeji yi maa nse okunfa ki eniyan bo kuro nibi jije eru fun nkan miran ti o yato si Olohun Allah.

    (3) Ise kan tabi ijosin kan ko le je atewogba ni odo Olohun Allah ayafi pelu mimo paapaa itumo awon ijeri mejeeji wonyi.

    (4) Musulumi kan ko le ri ogba idera (Al-Janna) wo tabi ki o la kuro nibi iya ina ayafi pelu ki o mo paapaa itumo ijeri mejeeji wonyi.

    (5) Eni ti o ba ti nwi awon ijeri mejeeji wonyi, eewo ni ki a ta eje re sile tabi ki a ko akoyo si owo re tabi dukia re tabi.

    (6) Awon ijeri mejeeji wonyi naa ni eniyan maa nwi nigbati o ba fe gba esin Islam, awon ni ohun ti a maa npase pe ki eni ti o ba fe gba esin Islam koko wi, toripe ki o wi i ni yoo so o di Musulumi.

    Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- so fun Ma'adh omo Jabal nigbati o ran an nise lo si ilu Yemen lati lo fi esin Islam mo awon ara ibe wipe: "Dajudaju iwo nlo ba awon eniyan kan ninu awon ti a fun ni tira (awon Yahuudi ati Nasaara), ohun ti o je dandan ki o koko pe won si ohun naa ni ijeri pe kosi nkankan ti o leto ki eniyan maa josin fun ni ododo ayafi Olohun Allah, atipe anabi Muhammad ojise Olohun ni" [Hadiisi yi wa ninu tira Bukhari ati Muslim].