×
Image

Awon Asa ti o tako Sunna - (Èdè Yorùbá)

Olubanisọrọ se alaye awọn idajọ ẹsin ti o rọ mọ mima jẹ orukọ ẹlomiran ti o yatọ si baba ẹni, ati pipe apemọra nkan ti kii se ti ẹni (gẹgẹ bii imọ, dukia ati bẹẹ bẹẹ lọ). O si tun sọ nipa ewu ti o nbẹ nibi pipe musulumi kan....

Image

Ẹtọ Adari ati Awọn ti wọn n dari - (Èdè Yorùbá)

Alaye lori awọn ojuse ati iwọ olori si awọn ti wọn ndari, bakannaa ojuse awọn ti wọn nse ijọba le lori si awọn adari

Image

Awọn Asa ti o ba Islam mu ati eyi ti o tako Islam - (Èdè Yorùbá)

Waasi oniyebiye ti o sọ nipa awọn asa ti o dara ti ẹsin Islam kin lẹyin, bakannaa awọn asa ti ko dara ti Islam kọ fun awa Musulumi.

Image

Asa ati Ẹsin - (Èdè Yorùbá)

Idanilẹkọ ti o n se alaye awọn nkan ti o n ba ẹsin jẹ mọ Musulumi lọwọ ti apa kan ninu awọn eniyan si n pe ni asa.

Image

Ojuse Odo Lori Atunse Awujo - 2 - (Èdè Yorùbá)

Oniwaasi se afihan re wipe iyipada ko le waye laisi awon nkan wonyi: Alakoko: Agboye imo ijinle nipa esin Islam. Eleekeji: Wiwa awon imo ijinle ti awujo ni bukaata si. Eleeketa: Sise igbiyanju lati fi imo naa kede esin Islam.

Image

Ojuse Odo Lori Atunse Awujo - 1 - (Èdè Yorùbá)

Olubanisoro se alaye wipe imo nipa Olohun Allah ni eniyan maa fi n mo iyato laarin ohun ti o dara ati eyi ti ko dara, o si so wipe eniti o ba mo ohun ti o dara yato si eyi ti ko dara ni yoo le gbero ayipada ni awujo.

Image

Awon Ese Nla - (Èdè Yorùbá)

Waasi yi da lori oro nipa awon ese nla. Olubanisoro si se alaye iyato ti o wa laarin awon ese nla ati kekere. O tun so nipa bi o ti se je ojuse Musulumi ki o mo wipe oranyan ni ki oun jinna si awon ese kekere ati nla.

Image

Awọn Okunfa Igbesi Aye Idunnu fun Lọkọ-laya-2 - (Èdè Yorùbá)

Abala yii jẹ alekun alaye lori awọn ohun ti o maa nmu igbesi aye lọkọ-laya ni itumọ ati idahun si awọn ibeere ti o waye.

Image

Awọn Okunfa Igbesi Aye Idunnu fun Lọkọ-laya-1 - (Èdè Yorùbá)

Idanilẹkọ yii da lori itumọ lọkọ-laya ati alaye awọn ohun ti o maa njẹ ki igbesi aye lọkọ-laye ni itumọ gẹgẹ bii: Ibẹru Ọlọhun Allah, Sise akiyesi adehun ti ọkunrin maa nse fun obirin nigba ti wọn ko tii gbe ara wọn wọ ile.

Image

Idajọ Tẹtẹ Tita Ninu Islam - 3 - (Èdè Yorùbá)

Abala yi so nipa awon idahun si ibeere lorisirisi ti o wa lori akole ibanisoro yi.

Image

Idajọ Tẹtẹ Tita Ninu Islam - 2 - (Èdè Yorùbá)

Itẹsiwaju ẹkunrẹrẹ alaye lori orisirisi awọn ọna ti tẹtẹ pin si, ti olubanisọrọ si jẹ ki a mọ awọn isesi ti tẹtẹ wọ ati eyi ti tẹtẹ ko wọ, pelu diẹ ninu abala ibeere ati idahun.

Image

Idajọ Tẹtẹ Tita Ninu Islam - 1 - (Èdè Yorùbá)

Ibanisọrọ ni abala yii da lori awọn koko wọnyii: (i) Kinni Itumọ Tẹtẹ tita, (ii) Awọn ẹri ti o se Tẹtẹ Tita ni eewọ lati inu Alukuraani mimọ ati awọn Haadisi pẹlu apanupọ ọrọ awọn onimimọ, (iii) Awọn ewu ti nbẹ nibi tẹtẹ tita.