×
Akọsilẹ ti o sọ diẹ ninu awọn nkan ti apa kan ninu awọn alaimọkan Musulumi fi maa n se ibura ti o si lodi si ilana ẹsin Islam.

    Awọn Nkan ti Apa kan Ninu Awọn Musulumi fi maa n bura Yatọ si Ọlọhun

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Lati ọwọ:

    Rafiu Adisa Bello

    Atunyewo:

    Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    أنواع المحلوف به غير الله

    لدى بعض المسلمين

    « بلغة اليوربا »

    كتبها:

    رفيع أديسا بلو

    مراجعة:

    حامد يوسف

    2015 - 1436

    Awọn Nkan ti Apa kan Ninu Awọn Musulumi fi maa n bura Yatọ si Ọlọhun

    Awọn nkan ti apa kan ninu awọn Musulumi fi maa n se ibura yatọ si Ọlọhun pin si ọna mẹta:

    Ipin Alakọkọ : Awọn nkan ti wọn fi maa n bura nitori ipo nkan naa ni ọkan wọn, nitori apọnle ti wọn maa n se fun awọn nkan wọnyi ati bi wọn se mọ iwọ wọn fun wọn, eyi ni o maa n ti wọn lọ sibi ki wọn maa se ibura pẹlu orukọ wọn. Awọn nkan wọnyi naa pin si meji:

    (1) Ibura pẹlu ojisẹ Ọlọhun anabi Muhammad: Apakan ninu awọn Musulumi maa n fi ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] bura ki ẹniti wọn n ba sọrọ le ni igbagbọ si wọn, ki o si le gba wipe ododo ni ọrọ ti wọn nsọ. Eleyi wa ninu awọn ọna ibura ti o wọpọ ni awujọ.

    (2) Ibura pẹlu saare ojisẹ Ọlọhun: Ninu awọn nkan ti apa kan ninu awọn Musulumi maa n fi bura ni saare ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a], ohun ti o si se okunfa eleyi ni apọnle ati ibọwọ ti wọn ni si aaye itẹ ojisẹ Ọlọhun naa.

    Ipin Elẹẹkeji : Awọn nkan ti wọn fi maa n bura pẹlu ero wipe awọn nkan naa ni agbara ti wọn le fi aburu se ẹniti o ba fi wọn bura, ti o ba jẹ wipe irọ ni o n pa, eleyi si pin si ọna mẹta:

    (1) Ibura pẹlu awọn orisa awọn ẹlẹbọ, gẹgẹ bii fifi irin bura eyiti o jẹ apẹẹrẹ fun ogun, orisa awọn ọdẹ ati awọn miran. Ninu rẹ naa ni fifi ọkọ bura tabi ibọn. Bakannaa ni fifi sango bura, eyi tii se ọkan ninu awọn orisa ni ilẹ Yoruba.

    (2) Ibura pẹlu awọn oku ti wọn ti ku tabi yeepẹ inu saare tabi omi ti wọn fi wẹ oku: Bakannaa ni awọn Musulumi miran maa n bura pẹlu ilẹ, ti wọn yoo maa sọ wipe: ‘Mo fi ilẹ ti emi yoo wọ sun bura …’, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

    (3) Ibura pẹlu owo beba (paper currency) tabi owo ẹyọ (coin), nitoripe wọn ni igbagbọ wipe apẹẹrẹ aje ni o jẹ, wọn si gba wipe ẹniti o ba fi owo bura, ti o si jẹ wipe irọ ni o n pa, ajẹ yoo fi ara rẹ dun un, yoo jinna si i, ti ko ni ni owo, ti o ba si n ta ọja ko nii ta.

    Ipin Elẹẹkẹta : Awọn nkan ti wọn fi maa n bura sugbọn ti ko si adisọkan wipe aburu kan le sẹlẹ si awọn ti wọn ba pa irọ nibi ibura naa. Apẹẹrẹ eleyi ni ki wọn maa fi igbesi aye wọn bura.

    Idajọ Awọn orisirisi ibura wọnyi

    Ko lẹtọ fun Musulumi lati maa fi nkan miran bura yatọ si Ọlọhun Allah, eleyi ni ohun ti awọn hadiisi ojisẹ Ọlọhun tọka si; nitoripe itumọ ibura ni wipe ẹniti o nbura pẹlu nkankan ni adisọkan wipe nkan naa tobi ni ọkan oun. Ohun ti ẹsin Islam si pasẹ rẹ fun Musulumi ni wipe ẹlomiran ko gbọdọ tobi ninu ọkan rẹ gẹgẹ bi Ọlọhun se tobi, eleyi si ni itumọ ‘LA ILAHA ILLA ALLAH, MUHAMMAD ROSUULU LLAHI’“Ko si nkankan ti ijọsin tọ si ayafi Ọlọhun Allah ati wipe Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni”.

    Alfa agba Ibn Abdul-barri [Ki Ọlọhun kẹ ẹ] sọ wipe: ‘Ko lẹtọ lati bura pẹlu nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Allah lori eyikeyi nkan, ati ni aaye-kaaye, eleyi ni awọn onimimọ fi ẹnu ko le lori’ [1].

    [1] At-tẹmhiidi, Ibnu Abdul-barri: 14/366.