×
Idajo esin lori yiyan nafila ni ojo alaruba ti o kehin ninu osu Safar ati idajo esin lori wipe irufe nafila bee adadasile ninu esin ni.

    Idajọ Nafila ni Ọjọ Alaruba ti o kẹhin

    ninu Osu Safar

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Igbimọ iwadi ijinlẹ lori imọ ẹsin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu ẹsin ni ilu Saudi Arabia

    Ẹni ti o tumo rẹ ni: Rafiu Adisa Bello

    Atunyẹwo : Hamid Yusuf

    2014 - 1436

    حكم نافلة يوم الأربعاء

    من آخر شهر صفر

    « بلغة اليوربا »

    الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء

    في المملكة العربية السعودية

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    مراجعة: حامد يوسف

    2014 - 1436

    Idajọ Nafila ni Ọjọ Alaruba ti o kẹhin ninu Osu Safar

    Fatwa: [1619] 2/497

    IBEERE:

    Apakan ninu awọn onimimọ ni ilu wa maa nsọ wipe: Nafila kan wa ninu ẹsin Islam ti Musulumi yoo yan ni ọjọ alaruba ti o kẹhin ninu osu Safar. Yoo ki i ni asiko iyalẹta (dhuha) ni raka mẹrin pẹlu salama kan, yoo maa ka ninu rakaa kọọkan awọn suura wọnyi:

    Suuratul Fatiha 1

    Suuratul Kaosar 17

    Suuratul Ikhlaas 50

    Suuratul Falaki 1

    Suuratun Naasi 1

    Wọn sọ wipe yoo ka awọn suura wọnyi ninu rakaa kọọkan, lẹhinnaa yoo wa salama. Nigbati o ba salama tan, yoo wa ka aaya yi: (والله غالب على أمره ولكن أكثر الناس لا يعلمون) [Suuratu Yuusuf: 21] ni igba “360”. Yoo tun ka gbolohun kan ti wọn npe ni “Jaoharatul kamal” ni ẹẹmẹta. Yoo si pari rẹ pẹlu “سبحان ربك رب العزة عما يصفون والسلام على المرسلين والحمد لله رب العالمين”. Nigbayi yoo wa se itọrẹ aanu pẹlu burẹdi fun awọn alaini.

    Wọn maa nsọ wipe anfaani kika aaya yi ni lati le adanwo ti o maa nsọkalẹ ni ọjọ alaruba ti o kẹhin ninu osu Safar jinna. Wọn tun maa nsọ wipe onka adanwo ati aburu ti o maa nsọ kalẹ ni ọdun kan jẹ “320,000”, ninu ọjọ alaruba ti o kẹhin ninu osu Safar si ni gbogbo rẹ maa nsọ kalẹ, eyi ti o mu ọjọ naa jẹ ọjọ ti o buru julọ ninu ọdun; nitorinaa ẹniti o ba ki nafila yi bi wọn ti se alaye rẹ, Ọlọhun Allah yoo fi isọ Rẹ sọ ọ kuro nibi gbogbo aburu ti yoo sọ kalẹ ni ọjọ naa. Se ododo ni irufẹ nafila yi wa bi?

    ---------------------------------------------------------------------

    IDAHUN:

    Kosi ipilẹ kankan fun iru nafila ti o se iroyin rẹ yi, kosi ẹri fun lati inu Alukurani tabi hadiisi, bẹẹni ko rinlẹ rara wipe ẹnikan ninu awọn asiwaju ninu ẹsin ati awọn ẹni-rere ninu awọn ti o gbẹyin se iru nafila bayi. Nitorinaa, adadasilẹ ti o buru ni nafila bẹẹ.

    Ninu hadiisi ti o fi ẹsẹ rinlẹ, ti o si ni alaafia, ojisẹ Ọlọhun sọ wipe: “Ẹniyowu ti o ba se isẹ kan, ti kosi asẹ wa nibẹ, ti awa kosi se e, a o da isẹ naa pada fun un, ti ko ni jẹ atẹwọgba ni ọwọ rẹ” [1]. O si tun sọ wipe: “Ẹniyowu ti o ba da nkankan silẹ ninu ilana wa yi, ohun ti kosi nibẹ tẹlẹ, a o da a pada fun un, ti a ko ni gba a lọwọ rẹ” [2].

    Gbogbo ẹniti o ba wa sọ wipe lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun [ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] ni oun ti ri iru nafila yi tabi lati ọdọ ẹnikan ninu awọn ọmọlẹyin ojisẹ Ọlọhun (Saabe) ni oun ti ri nafila yi, iru ẹni bẹẹ ti pa irọ nla mọ wọn, ki o si maa reti iya nla ti o lẹtọ si lati ọdọ Ọlọhun Allah.

    [1] Muslim: (1718).

    [2] Bukhari: (2697), Muslim: (1718).