×
Idahun si ibeere nipa wipe irun ti won n pe ni "solaatur-rogaaibi" ati sise adayanri ojo ketadinlogbon ninu osu Rajab fun awon ijosin kan, se awon nkan wonyi ni ipile ninu esin, idahun si waye wipe adadaale ni gbogbo re je.

    AWỌN ADADAALẸ INU OSU RAJAB

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia

    Itumo Si Ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello

    Atunyewo: Hamid Yusuf

    2014 - 1435

    بدع شهر رجب

    « بلغة اليوربا »

    الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء

    في المملكة العربية السعودية

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    مراجعة: حامد يوسف

    2014 - 1435

    AWỌN ADADAALẸ INU OSU RAJAB

    IBEERE:

    Apakan ninu awọn Musulumi maa n se adayanri osu Rajab pẹlu awọn ijọsin kan gẹgẹ bii irun kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni "Sọlaatu Rọgaaibi", bakannaa ni sisa awọn isẹ ijọsin kan ni ẹsa fun oru ọjọ kẹtadinlọgbọn, se awọn nkan wọnyi ni ipilẹ ninu ẹsin bi? Ki Ọlọhun san yin ni ẹsan rere.

    __________________________________

    IDAHUN:

    Sise adayanri osu Rajab pẹlu irun kan ti wọn n pe ni "Sọlaatur-rọgaaibi" tabi sise ayẹyẹ ni oru ọjọ kẹtadinlọgbọn ninu osu naa, ti wọn n lero pe oru naa ni oru "Israai wal-miiraji", adadaalẹ ni gbogbo awọn nkan wọnyi, ko si ni ipilẹ kankan ninu ẹsin Islam. Awọn ti wọn jẹ onimimọ ti wọn fi ẹsẹ rinlẹ, ti wọn si tun jẹ oluse iwadi nipa ọrọ ẹsin ti pe akiyesi awa Musulumi si eleyi, awa naa si ti kọ akọsilẹ ni ori ọrọ yi ni ọpọlọpọ, a si ti se alaye fun gbogbo Musulumi wipe irun ti wọn n pe ni "Sọlaatur-rọgaaibi" ti awọn eniyan kan maa n ki ni ọjọ Jimọh alakọkọ ninu osu Rajab, adadaalẹ ni ninu ẹsin. Bakannaa ni sise ayẹyẹ ni oru kẹtadinlọgbọn ninu osu Rajab pẹlu adiọkan wipe ohun ni oru ti Ọlọhun mu Ojisẹ Rẹ se irin-ajo "Israai wal-miiraaji", adadaalẹ ni gbogbo eyi jẹ ninu esin.

    Oru "Israai wal-miiraaji" ko si ẹni ti o mọ ọ, ti o ba si jẹ wipe awọn eniyan kan mọ ọ sibẹsibẹ ko lẹtọ ki a mu oru naa ni ohun ti a o maa se ayẹyẹ nibẹ; nitoripe Ojisẹ Ọlọhun – ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a – ko mu oru naa ni oru ti yoo maa se ayẹyẹ ninu rẹ, bẹẹnaani awọn arole rẹ ti wọn jẹ olufinimọna (awọn Saabe rẹ mẹrẹẹrin) ati gbogbo awọn ọmọlẹyin rẹ yoku, ẹnikankan ninu wọn ko mu oru naa ni oru ayẹyẹ, ti o ba si jẹ wipe ilana Ojisẹ Ọlọhun ni eleyi gbogbo wọn ko ba ti maa se e.

    Ohun ti o jẹ oore ni ki a maa tẹle ilana wọn, ki a si maa rin lori ipasẹ wọn gẹgẹ bi Ọlọhun ti sọ wipe: {Ati awọn ti wọn gba iwaju, awọn ẹni akọkọ ninu awọn ti wọn se irin-ajo lati ilu Makkah ati awọn alatilẹyin ti wọn jẹ ara ilu Madina ati awọn ti wọn tẹle wọn pẹlu isẹ rere, Ọlọhun ti yọnu si wọn, awọn naa si yọnu si ohun ti Ọlọhun se fun wọn, O si pese silẹ fun wọn awọn ọgba idẹra ti awọn odo n san ni abẹ wọn, wọn yoo maa bẹ ninu rẹ (ọgba idẹra naa) gbere. Eyi si jẹ erenjẹ ti o tobi} [Suuratu Taoba: 100].

    Bakannaa ni Ojisẹ Ọlọhun – ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a - sọ wipe: (Eniyowu ti o ba da nkankan silẹ ninu ọrọ ẹsin wa yi, ti nkan naa ko si ni ara ẹsin, a o da a pada si i ni) [1].

    Ojisẹ Ọlọhun tun sọ wipe: (Eniyowu ti o ba se isẹ kan ti ko si asẹ awa Ojisẹ Ọlọhun lori rẹ, a o da isẹ naa pada si i ni) [2].

    Itumọ gbolohun: (A o da a pada si i ni) ni wipe: Isẹ naa yoo pada si ọdọ ẹniti o se e, ti ko si ni ni ẹsan kankan lori rẹ.

    Ni afikun, Ojisẹ Ọlọhun – ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a – maa n sọ bayi nibi ibanisọrọ rẹ "Khutba": (Lẹyinnaa, eyi ti o dara julọ ni ọrọ naa ni ọrọ Ọlọhun, eyi ti o si dara julọ ni ilana naa ni ilana Muhammad, eyi ti o si buru julọ ninu awọn nkan ohun naa ni nkan tuntun ti o ba wọ inu ẹsin, gbogbo adadaalẹ anu (isina) ni o jẹ) [3].

    Nitori idi eyi, ohun ti o jẹ dandan fun gbogbo Musulumi ni ki wọn maa tẹle ilana Ojisẹ Ọlọhun ati sunna rẹ, ki wọn gbiyanju lati duro sinsin lori rẹ, ki wọn tun maa sọ asọtẹlẹ rẹ fun awọn ọmọ iya wọn Musulumi yoku, ki wọn si jinna si gbogbo adadaalẹ ninu ẹsin, ki wọn maa sisẹ tọ ọrọ Ọlọhun ti o sọ wipe: {Ẹ ran ara yin lọwọ lori isẹ rere ati ibẹru Ọlọhun, ẹ mase ran ara yin lọwọ lori iwa ẹsẹ ati biba ara ẹni ja} [Suuratu Maaida: 2]. Ati ọrọ Ọlọhun ti o sọ wipe: {Mo fi akoko ('Asri) bura # Dajudaju eniyan n bẹ ninu ofo # Ayafi awọn ti wọn ni igbagbọ si Ọlọhun ni ododo, ti wọn si se isẹ rere, ti wọn si n gba ara wọn niyanju sisọ ododo, ti wọn si n gba ara wọn niyanju lori sise suuru ati ifarada} [Suuratul 'Asri: 1- 3]. Ati ọrọ Ojisẹ Ọlọhun ti o sọ wipe: (Ẹsin isiti (waasi) ni o jẹ). Awọn Saabe beere wipe: fun taani? Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: (Fun Ọlọhun ati fun tira Rẹ (Alkurani) ati fun Ojisẹ Rẹ ati fun awọn asiwaju awọn Musulumi ati fun awọn ọgọọrọ wọn) [4].

    Sugbọn nipa ki Musulumi se 'Umra ninu osu Rajab ko si laifi kankan nibẹ; nitoripe o wa ninu hadiisi ti Abdullahi ọmọ 'Umar gba wa wipe Ojisẹ Ọlọhun - ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a- se 'Umra ninu osu Rajab. Bakannaa, awọn ẹni isaaju ninu ẹsin maa n se 'Umra ninu osu Rajab gẹgẹ bi onimimọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Ibn Rajab- ki Ọlọhun kẹ ẹ- ti sọ ninu tira rẹ ti o n jẹ "Al-latọọif", o ri akọsilẹ naa lati ọdọ 'Umar ati ọmọ rẹ ati iya wa 'Aisha- ki Ọlọhun yọnu si gbogbo wọn.

    Ẹgbawa tun wa lati ọdọ Ibn Siiriin wipe awọn asaaju ninu ẹsin maa n se 'Umra ninu osu Rajab. Ki Ọlọhun fi wa se kongẹ.

    _____________________________

    [1] Bukhari ati Muslim.

    [2] Muslim.

    [3] Muslim.

    [4] Muslim.