×
Idajo gbigba aawe ninu osu Rajab bi apa kan ninu awon eniyan se maa n se pelu ero wipe osu naa da yato, awon onimimo si ti se alaye wipe adadaale ni gbogbo awon nkan wonyi.

    IDAJỌ GBIGBA AAWẸ OSU RAJAB

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia

    Itumo Si Ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello

    Atunyewo: Hamid Yusuf

    2014 - 1435

    حكم صيام شهر رجب

    « بلغة اليوربا »

    الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء

    في المملكة العربية السعودية

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    مراجعة: حامد يوسف

    2014 - 1435

    IDAJỌ GBIGBA AAWẸ OSU RAJAB

    IBEERE:

    Njẹ o lẹtọ fun Musulumi ki o fi gbogbo ọjọ osu Rajab gba aawẹ? Nitoripe apa kan ninu awọn onimimọ n sọ pe: Eniti o ba fi gbogbo ọjọ osu Rajab gba aawẹ, Ọlọhun yoo se aforijin ẹsẹ rẹ fun un, koda ki o pọ bii idọti ti o maa n ho bi ọsẹ ni ori odo nla. Bakannaa ni awọn miran ninu awọn onimimọ si n kọ pe ki Musulumi fi gbogbo awọn ọjọ osu Rajab yii gba aawẹ ti wọn n sọ wipe: Osu Rajab jẹ osu kan gẹgẹ bii awọn osu yoku ni, ko lẹtọ ki Musulumi fi gbogbo ọjọ rẹ gba aawẹ. Ki Ọlọhun san yin ni ẹsan rere.

    ____________________________

    IDAHUN:

    Ohun ti o jẹ ododo ni wipe ko lẹtọ ki Musulumi fi gbogbo ọjọ osu Rajab gba aawẹ; nitoripe ko si ẹri kankan fun eleyi. Ohun ti o jẹ ilana ẹsin ni gbigba aawẹ ninu osu Shaaban. Ojisẹ Ọlọhun- ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a - maa n gba aawẹ ninu osu Shaaban, o maa n gba aawẹ ninu rẹ ti yoo si fi ọjọ diẹ silẹ. Sugbọn Osu Rajab, ẹsin kọ fun wa ki a fi gbogbo ọjọ rẹ gba aawẹ; nitoripe ninu isesi awọn alaimọkan ni eyi wa, gbigba aawẹ ninu rẹ ko si ni ẹri kankan.

    Ni afikun, hadiisi ti wọn fi n se ẹri lori wipe fifi gbogbo ọjọ Osu Rajab gba aawẹ jẹ okunfa idarijin ẹsẹ lati ọdọ Ọlọhun, hadiisi naa ko fi ẹsẹ rinlẹ rara, ko si ni alaafia. Nitori idi eyi, ohun ti o jẹ ojuse fun Musulumi ni ki o maa jẹun ni ọsan ninu Osu Rajab, ki o si mase gba aawẹ nibẹ ayafi ni awọn ọjọ ti Ọlọhun ti se gbigba aawẹ nibẹ ni ẹtọ gẹgẹ bii Ọjọ Aje (Monday) ati Ọjọbọ (Thursday), bakannaa ni awọn ọjọ mẹta ni aarin osu oju ọrun: Ọjọ Kẹtala, Ọjọ Kẹrinla ati Ọjọ Kẹẹdogun, awọn eleyi ni o lẹtọ, sugbọn, fifi gbogbo ọjọ inu osu Rajab gba aawẹ, eleyi ko ba ilana ti ẹsin gbe kalẹ mu.