×
Fatwa yi so fun wa nipa bi o ti je wipe eniyan leto lati to ni iduro bi o tile je wipe ipile ni ki eniyan bere nigbati o ba fe to.

    IDAJO KI ENIYAN TO NI IDURO

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia

    Eni ti o tumo re ni: Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    حكم البول واقفا

    « بلغة اليوربا »

    الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء

    في المملكة العربية السعودية

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    IDAJO KI ENIYAN TO NI IDURO

    (Ibeere alakoko fatwa 2001)

    IBEERE:

    Nje o leto ki eniyan to ni iduro bi?

    --------------------------------------------------------------------------------------------------

    IDAHUN:

    Ope ni fun Olohun, ike ati ola fun Ojise Olohun ati awon ara ile re.

    Kiise eewo ki eniyan to ni iduro, sugbon sunna ni o je ki eniyan bere ti o ba fe to. Iya wa Aisha- ki Olohun yonu si i- so wipe: "Eni ti o ba so fun yin wipe Anabi- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- maa n to ni iduro ki e ma se gba a gbo, Ojise Olohun ki i to ayafi ki o bere" [1], imaam Tirmisi ni o gba oro yi wa o si so wipe: "Eleyi ni oro ti o fi ese rinle julo ni oju ona yi; nitoripe ki eniyan bere ti o ba fe to ni o bo ihooho ara re ju, ohun ni yoo si so ara re ti o fi je wipe ito ko ni ta si i ni ara".

    Sugbon egba oro miran wa lati odo Umar ati Aliy ati Ibn Umar ati Zaed bin Saabit- ki Olohun yonu si gbogbo won- ti o se ede (irorun) lori wipe o leto ki eniyan to ni iduro. Imaam Bukhari ati imaam Muslim gba hadiisi wa lati odo Usaefa- ki Olohun yonu si i- lati odo Anabi- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- pe Anabi de aaye kan ti awon eniyan kan maa n da ile (idoti) si o si to nibe ni iduro [2].

    O ye ki o ye wa wipe kosi iyapa laarin hadiisi yi ati hadiisi iya wa Aisha; nitoripe o seese ki o je wipe Anabi to ni iduro ni aaye ti o ti to ni iduro nigbati ko rorun fun un lati to ni ibere, tabi ki o je wipe Anabi se eleyi ki o le fi ye awon eniyan wipe ki enikan to ni iduro kiise eewo, eleyi ko si yapa si ohun ti iya wa Aisha so wipe Ojise Olohun maa n bere ti o ba fe to ni. Ki Olohun fi wa se konge aanu re.

    [1] Musnad Ahmad: 1/192. Sunan Tirmisi: (hadiisi: 12).

    [2] Sohih Bukhari: (hadiisi: 224). Sohih Muslim: (hadiisi: 273).