Ninu Awon Eko Irinajo fun Ise Haj Tabi Umrah
Àwọn ìsọ̀rí
Full Description
Ninu Awon Eko Irinajo Fun Ise Haj Tabi Umrah
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Rafiu Adisa Bello
2013 - 1434
من آداب السفر للحج أو العمرة
« بلغة اليوربا »
رفيع أديسا بلو
2013 - 1434
Ninu Awon Eko Irinajo Fun Ise Haj Tabi Umrah
Gbogbo ohun ti esin Islam pa awa Musulumi ni ase re ni o ni ilana, eto ati eko ti o ti gbe kale fun awon nkan naa.
Irinajo lo si ilu Makkah fun ise Haj je origun kan ti o se pataki ninu awon origun esin Islam. Haj ni origun eleekarun eyi ti o gbeyin ninu gbogbo awon origun esin awa Musulumi.
Ninu awon eko ti Islam ko wa ti a ba fe se irinajo lati lo se ise Haj tabi irinajo miran ni yi:
Alakoko: O je dandan fun eni ti o ba ngbero lati se Haj tabi Umrah ki o fi ise Haj ati Umrah re wa ojurere Olohun, ki o si fi wa asunmo si odo Olohun naa, ki o si sora fun sise iru ise yii nitori oro aye, tabi lati maa se iyanran, tabi nitori sekarimi, tabi nitori ki awon eniyan le maa pe e ni Alhaji.
Eleekeji: Esin Islam gba eni ti o fe se irinajo ni iyanju ki o ko asotele re sile (wasiyya): owo re ti o ni ati awon gbese ti o wa lorun re, bakannaa ki o da awon nkan ti won ba fi si lodo pada fun awon ti won ni nkan naa tabi ki o gba iyonda lowo won pe ki nkan naa si tun seku si odo ohun; nitoripe Olohun nikan ni o mo asiko ti iku yoo de.
Eleeketa: Ki eni ti o fe se irinajo ronu piwada losi odo Olohun lori awon ese ti o da, ki o banuje lori awon asise ti o ti koja lo, ki o si ni ipinnu lati ma pada sibi awon ese naa mo.
Eleekerin: Awon nkan ti o gba lowo awon eniyan ni ona ti ko to, gege bii owo tabi dukia miran, ki o da won pada fun awon ti won ni nkan naa, tabi ki o toro amojukuro ni odo won.
Eleekarun: Owo ti yoo fi se Haj tabi Umrah gbodo je owo ti o ri ni ona ti o to (halaal ); nitoripe Olohun Oba wa Oba ti O mo ni, kosi ni gba nkan kan ayafi ohun ti o ba mo.
Eleekefa: Ki o jinna si gbogbo ese; ki o ma se maa fi ininra kan enikankan pelu ahon re tabi owo re, ki o ma se maa ba awon eniyan dimu fun aaye kan ni ona ti o le ko ininra ba won. Bakannaa ki o ma se maa se ofofo, ki o si ma se maa so oro eyin, ki o si ma se maa ba awon eniyan ja iyan. Ni afikun ko gbodo maa pa iro, ko si gbodo maa so ohun ti ko ni imo re nipa Olohun- Oba ti O ga julo.
Eleekeje: Ojuse ni fun Musulumi ti o ba fe se Haj tabi Umrah ki o ni agboye ohun ti o fe se.
Eleekejo: Eni ti o nse irinajo yi gbodo so awon nkan ti Olohun se ni ofin, eyi ti o ga julo ninu re si ni kiki awon irun oranyan ni asiko won, ki o si maa ki won pelu janmoo Musulumi. Ninu awon ojuse re naa ni ki o maa lekun nibi ise oloore gege bii kika Al- Qur'an ati awon iranti Olohun miran, ki o maa se adua ni opolopo, ki o si maa se daradara si awon eniyan nibi oro enu ati ise sise, bakannaa ki o maa se iranlowo fun awon alaini, ki o maa se pelepele pelu awon omo iya re Musulumi, ki o maa se itore aanu fun awon talaka, ki o maa pa awon eniyan lase lati se ise rere, ki o si maa ko fun won nibi ohun ti ko dara.
Eleekesan: Esin Islam fe ki Musulumi se igbiyanju lori bi yoo se ni alabarin rere nibi irinajo re.
Eleekewa: Ki arinrinajo maa hu iwa ti o dara, ki o si maa ba awon eniyan lo pelu iwa ti o dara; awon iwa bii sise suuru, nini amojukuro, sise pele, nini atemora, iteriba, yiyawo tabi jije olore, sise deede, nini aanu, jije eni ifokantan, jije alasaje, jije eni ti o npe adehun, nini itiju, jije olododo, jije oluse daradara. Bakannaa ki o ma je eniti yoo maa kanju lati se idajo tabi lati so oro kan nipa awon eniyan.
Eleekokanla: Esin Islam fe ki eniti o nse irinajo so asotele iberu Olohun fun awon ara ile re; nitoripe oro nipa iberu Olohun ni asotele Olohun fun awon eni isiwaju ati awon eni ikeyin.
Eleekejila: Ninu ojuse onirinajo ni ki o maa so awon adua ati iranti Olohun eyi ti o fi ese rinle lati odo Anabi- ki ike ati ola Olohun ki o maa ba a- ninu re si ni adua irinajo ati adua ti eniyan maa nse nigbati o ba ti wa ni ori nkan igun re.
A nbe Olohun ninu aanu Re ki O se ise Haj ni irorun fun enikookan wa, ki O si se e ni atewogba ni odo Re. Amin.