Gbigba Aawe Ninu Gbogbo Awon Ojo Osu Rajab Ati Sha’baan
Àwọn ìsọ̀rí
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan
Full Description
Gbigba aawe ninu gbogbo awon ojo osu Rajab ati Sha'baan
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia
Eni ti o tumo re ni: Rafiu Adisa Bello
2013 - 1434
صيام رجب وشعبان
« بلغة اليوربا »
الرئاسة العامة للبحوث العلمية في المملكة العربية السعودية
ترجمة: رفيع أديسا بلو
2013 - 1434
GBIGBA AAWE NINU GBOGBO AWON OJO OSU RAJAB ATI SHA'BAAN
Ibeere:
Mo ri awon eniyan kan ti won n gba aawe ninu osu Rajab ati Sha'baan ki won to gba awe osu Ramadan, lai je wipe won yoo sinu rara ni gbogbo asiko yii, ejowo nje hadiisi kan wa ti o toka si ohun ti won n se yii, ti o ba si ri bee kinni hadiisi naa?
---------------------------------------------------------------------------------------
Idahun:
Oro kankan ko rinle lati odo ojise Olohun wipe o fi gbogbo ojo osu Rajab ati Sha'baan gba aawe, bakannaa ni eleyi ko waye ri lati odo enikankan ninu awon omoleyin re (Saabe)- ki Olohun yonu si won. Ni afikun, ko sele ri wipe ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- fi gbogbo ojo ninu osu kan gba aawe ayafi osu Ramadan. Iya wa Aisha- ki Olohun yonu si i- so wipe: {Ojise Olohun maa n gba aawe titi ti a o fi so wipe ko ni si'nu, o si maa n si'nu titi ti a o fi so wipe ko ni gba aawe, bee ni emi ko si ri ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ki o fi gbogbo ojo osu kan gba aawe ri ayafi osu Ramadan, bakannaa ni emi ko si ri i ki o fi opolopo ojo ninu osu kan gba aawe ri ayafi osu Sha'baan} [Bukhari ati Muslim].
Ibn Abbaas- ki Olohun yonu si oun ati baba re- naa so wipe: {Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ko fi gbogbo ojo ninu osu kan gba aawe ri ayafi osu Ramadan, o si maa n gba aawe [ninu osu miran yato si Ramadan] titi ti enikan ninu wa yoo fi so wipe: Mo fi Olohun bura, ko ni si'nu, bi o ti se je wipe o maa n si'nu titi ti enikan ninu wa yoo fi so wipe: Mo fi Olohun bura, ko ni gba aawe} [Bukhari ati Muslim].
Fun idi eyi, gbigba aawe asegbore ninu gbogbo awon ojo osu Rajab ati Sha'baan lodi si ilana ati sunna ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- nibi aawe gbigba, o si je adadasile ninu esin. Ojise Olohun si ti so ninu oro re kan wipe: {Eniyowu ti o ba da nkan kan sile ninu esin wa yi ti kosi ninu re tele, a o da a pada si i ni [ise naa ko ni je atewogba]} [Bukhari ati Muslim].
Ki Olohun fi wa se konge. Ike ati ola Olohun ki o maa ba anabi wa Muhammad ati awon ara ile re ati awon omoleyin re.