×
1- Oro lori koko ohun ti Olohun fi ran ojise Re Muhammad, iranse ni o je si gbogbo aye patapata. 2- Pelu bi o ti je wipe awon osebo fi inira kan ojise Olohun ni ilu Makka sibe sibe o tun fi aanu bawon lo ti ko si fi ibi san ibi. 3- Apejuwe lori aanu ti ojise Olohun ni fun awon eranko. Ikilo si waye lori fifi iya je awon eranko. 4- Apejuwe nipa aanu re si awon ewe tabi awon omode. 5- Apejuwe nipa aanu ojise Olohun si awon obinrin, oro si waye lori bi awon eniyan se maa nse abosi si won ni igba aimokan. 6- Awon apejuwe nipa iteriba ati iwapele ojise Olohun. Bi o ti se ni aanu awon omoleyin re ti awon naa si ni ife si i.