Eni ti o n beru aisan, kinni yoo se?
Eleyi ni idahun fun ibeere lori bi eniyan kan ba n beru aisan.
Àwọn ìsọ̀rí
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan
Full Description
Ibeere Eleekejo Fatwa (7804)
IBEERE:
Mo je eni ti o maa n beru aisan ni awon asiko kan, kinni o ye ki n maa se?
_____________________________________________
IDAHUN:
Ohun ti iwo yoo maa se ni wipe ki o ni agbiyele ninu Olohun Allah, ki o si gbe ara le E ni otito ati ododo. Bakannaa, ki o maa be Olohun wipe ki O se amojukuro fun o, ki O si fun o ni alaafia. Ni afikun, ki o gbiyanju lati maa lekun ni ise rere eyi ti yoo maa je ohun afipamo fun o ni orun, ki o si jinna si awon ohun ti o maa nse okunfa aisan. Bakannaa, ki o ma se iye meji lati se abewo awon onimimo nipa eto ilera ni ile iwosan ti ijoba tabi ti aladani lati se alaye fun won ohun ti o ba se akiyesi re ni ara re. A be Olohun ki o maa ran o lowo.