×
Akosile yi so nipa bi o ti se je wipe ko ba laakaye mu ki eniyan se nkan ti o dara ti o si tobi lai ni idi kankan, beenaani o se je wipe a ko gbodo lero wipe Olohun da eda eniyan pelu awon idera ti o po ti O se fu un lai ni ojuse ankan fun eniyan naa ni ile aye yii.

    OJUSE ENIYAN NI ILE AYE

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    مسؤولية الإنسان في الحياة

    « بلغة اليوربا »

    رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    OJUSE ENIYAN NI ILE AYE

    Oro Irori:

    Ninu ohun ti ko ba laakaye mu ni ki eniyan se ise kan, ki o se igbiyanju pupo ki o to pari re, sugbon ni ipari ki o je wipe kosi erongba kankan ti o fi se ise naa. Fun apejuwe eniti o se oko ofurufu (baaluu), ti o se wahala pupo lori re ki o to pari, ki o to di ohun ti yoo maa fo ni oju ofurufu, leyinnaa ki awon eniyan wa bii leere wipe: kinni idi ti o fi se oko ofurufu naa? Ki o wa da won lohun wipe: Oun kan se e lasan ni, kosi idi Kankan fun sise re, oun ko ni nkankan ti oun fee fi se. A o ri pe gbogbo onilaakaye olopolo pipe ni oro yii yoo tako laakaye won.

    Olohun Se Eda Eniyan O si se Aponle Pupo Fu un, Nje Eniyan Ni Ojuse Kan Ni Ile Aye Bi?

    Ti Olohun Oba nla ni apejuwe ti o ga julo, Oun ni o da eniyan si ile aye yii, O si daa ni eda ti o dara julo, gege bi O ti so wipe: (Dajudaju A da eniyan ni eya ti o dara julo). [Suuratu Tiin: 4].

    Bi o ti je wipe Olohun ni O da eniyan ti O si da gbogbo awon nkan miran ti o wa ni aye, sugbon O sa awon eniyan ni esa, O si se aponle fun won, O si gbe won ga ju gbogbo awon eda Re yoku lo. Olohun so wipe: (Atipe dajudaju Awa se aponle fun awon omo [Anabi] Aadama, A si gbe won [rin] lori ile ati odo, A si fun won ni ije-imu ninu ohun ti o dara, Awa si da won lola ju opolopo ninu awon eda ti A da lo). [Suuratu Isra': 70].

    Awon ohun ti Olohun fi se aponle fun eda eniyan po pupo, sugbon ninu eyi ti o ga julo ni laakaye ti O fun won lati maa dari awon nkan yoku ninu awon eda Re, bakannaa ni O se idera Re fun won, ti O si se gbogbo ohun ti yoo je ki gbigbe ile aye rorun fun won. Olohun so wipe: (Atipe [Olohun] ro fun yin ohun ti o wa ni sanma ati ohun ti o wa ni ile patapata, lati odo ara Re. Dajudaju awon ami wa ninu eyi fun awon eniyan ti won nronu). [Suuratu Jaasiyah: 13]. O tun so ni aaye miran pe: (Oun [Olohun] naa ni Eniti O da gbogbo ohun ti o nbe lori ile patapata fun yin). [Suuratu Bakorah: 29].

    Omo eda eniyan yato si gbogbo awon eda yoku ti won nrin ni ori ile, o yato si won nibi awon eya ara ti Olohun se fun un, o yato si won nibi laakaye ati irori, o si yato si won nibi awon idera miran repete ti Olohun se fun un.

    Gege bi a ti se so siwaju, ti Olohun Oba nla Allah ni apejuwe ti o ga julo, nje o rorun, tabi o dun lati gbo leti pe Olohun ti O da eniyan bi O ti da a yi ni aworan ti o pe, ti o si rewa julo, ki a so wipe O da eniyan naa lasan laisi idi kankan ti o fi da a? Kosi iye meji wipe gbogbo onilaakaye olopolo ni yoo dahun wipe: ko rorun, kosi ba laakaye mu ki a so wipe Olohun da eniyan lai je wipe nitori idi pataki kan ni O fi da a.

    Eleyi ni ibeere ti Olohun bi gbogbo awa eniyan nigbati O nso wipe: (Se e ro pe A da yin lasan, atipe A ko ni da yin pada si odo Wa ni bi?). [Suuratu Muuminuun: 115].

    Ni otito ati ni ododo, ohun ti o ye ki eniyan bi ara re leere ni ibeere yi wipe: Se Olohun da oun, O si fun oun ni gbogbo awon idera ti O fun oun wonyi, O si gba oun ni aaye bi O ti se gba oun laaye yii, O se gbogbo aponle wonyi fun oun lai si idi kankan bikosepe O fe ki oun maa wa lasan?

    Olohun Allah fe ki eniyan ronu jinle lori oro yii, O tun ran an leti bi O ti se se eda re lati ipele kan si ipele miran nigbati O nso pe: (Se eniyan nro pe A o fi oun sile lasan ni bi # Abi oun ko ti je omi logbologbo lati ibi ato ti o jade # Leyinnaa ni o di eje didi O [Olohun] si da a ni adape # O mu jade lati ara re iru re meji: ako ati abo # Nje Eniti O se eleyi ko wa le ji oku bi?). [Suuratu Kiyaamah: 36- 40].

    Pelu arojinle, omo eniyan yoo mo amodaju wipe gbogbo aponle ti oun ri lati odo Olohun ati awon idera ti O se fun oun gbogbo re kii se lasan bikosepe nitori erongba kan ti o se pataki ni. Kiise nitori ki oun le maa jeun, ki oun maa mu, ki oun si maa dunnu lasan. Bakannaa kiise nitori ki oun le maa se ohun ti o ba ife inu oun mu, o gbodo je wipe gbogbo ohun ti Olohun pese re sile fun oun yii nitori erongba kan ti o ga ti o si tobi ni.

    Lai fa oro gun, kinni erongba ati idi naa ti Olohun fi da eniyan yato si awon eda yoku ti O si se aponle fun un pelu awon nkan lorisirisi?

    Erongba naa ni wipe bi Olohun ti se aponle ati idera ti o ga julo fun eniyan bee naa ni O gbe ojuse ti o tobi julo le e lowo, eleyi ni a npe ni amaana, ti o ntumo si ifokantan (Ohun ti a fi so eniyan pe ki o maa se amojuto re). Ohun ti Olohun gbe fun eniyan gegebi ojuse yii ti o ba se deede lori re, ti o so o bi o ti se ye, esan ti o tobi wa fun un, ti o nduro de e ni odo Olohun Allah. Olohun yoo si pese sile fun un awon nkan ti oju ko ri ri, ti eti ko gbo ri, ti okan eniyan kan kosi ronu nipa re ri. Ni afikun, yoo maa wa ni eni aponle ni gbogbo igba ti o ba wa laye, ti o ba di orun naa yoo maa je eni aponle.

    Olohun so wipe: (Ohun tin be ni odo Olohun ni o dara julo ni o si maa seku). [Suuratu Kosos: 60].

    Olohun se alaye nipa ojuse ti O gbe le eniyan lowo nigbati O so wipe: (Dajudaju Awa ti fi ise ifokantan ni lo sanma ati ile ati awon oke wo, won rori lati gbe e, won si paya re, eniyan si gbe e, dajudaju oun je alabosi alaimokan). [Suuratu Ahsaab: 72].

    Lehinnaa, Olohun tun se alaye ohun ti yoo je erenje fun eniti o ba gbe ojuse tire sile laise ati ohun ti yoo je erenje fu eniti o ba se ojuse tire bi o ti ye ki o se e. (Ki Olohun le ba je awon olojueji [munaafiki] l'okunrin ni iya ati awon olojueji [munaafiki] l'obinrin ati awon osebo l'okunrin ati awon osebo l'obinrin, ati ki Olohun le gba ironupiwada fun awon onigbagbo ododo l'okunrin ati onigbagbo ododo l'obinrin, atipe Olohun si je Alaforiji, Onike). [Suuratu Ahsaab: 73].

    Kinni Paapaa Ojuse Naa?

    Ojuse ti Olohun gbe le eniyan lowo ni ifokantan (amaana), itumo re naa si ni gbogbo ohun ti Olohun se ni oranyan fun awa eniyan ati gbogbo titele ase Olohun eyi ti o je wipe eniti o ba se e yoo gba esan eniti o ba si ra a lare tabi gbe e ju sile yoo je iya. Awon nkan wonyi ni Olohun so nipa re ni soki ninu aayah ti O ti so pe: (Ki e maa josin fun Olohun, ki e si mase wa orogun fun Un, ki e si maa se rere si awon obi yin mejeeji ati awon ibatan ti won sunmo yin ati awon omo-orukan ati awon alaini ati awon aladugbo ti won sunmo yin ati awon aladugbo ti won jinna ati awon ore alabarin ati omo oju ona ati awon ti won wa labe ikapa yin, dajudaju Olohun ko feran onigberaga oniyanran). [Suuratu Nisaai: 36].

    Gbogbo awon iwo ti Olohun so nipa won ninu aayah yi kosi eniti esin Islam se amojukuro tabi iyonda fun pe ki o ma pe awon iwo naa fun eniti o ba ye ki o pe won fun ayafi eniti laakaye tabi opolo re ko pe (were).

    Ni ipari, ikookan ninu awon iwo ti Olohun so nipa won yi ni o ni alaye pupo lori, ti a o maa se alaye naa nigba miran. Ki Olohun fi ododo oro Re ye wa. Amin.