×
Hadiith ogoji ti o je ti Alufa wa Nawawiy

Hadiith ogoji ti o je ti Alufa wa Nawawiy

Pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake orun.

Hadith alakoko.

Dajudaju gbogbo ise nbe pelu aniyan.

Egbawa yi wa lati odo alase awon muumini baba Afsi Umar omo Khattaab – ki Olohun yonu si i – o so pe: mo gbo lenu ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ti o nso pe:Dajudaju gbogbo ise nbe pelu aniyan, atipe dajudaju o nbe fun gbogbo omoniyan ohun ti o ba gbalero, eniti o ba wa se Hijra tie ni titori ti Olohun ati ojise Re, yio gba esan Hijra re ni titori ti Olohun ati ojise Re, eniti o ba wa se Hijra tie ni titori aye to fe ki owo re o te e tabi ni titori obinrin ti o fe fe e, yio gba esan Hijra re lori ohun ti o ba titori re se e.Awon imam awon aladiithi meji ni won gba egbawa yi wa Abu Abdullaah Muhammad omo Ismaahiil omo Ibraahiim omo Almugiirah omo Bardizbah Al-Bukhaariy Al-Juhfiy [Number:1].Ati Abul Usain Muslim omo Al-Ajjaaj omo Muslim Al-Qushairiy Al-Naisaabuuriy [Number:1907] ki Olohun yonu si awon mejeejiNinu sohiihu awon mejeeji ti won ni alaafia ju ni awon tira ti awon alufa se lori Hadiith.

Hadith eleekeji.

Wiwa Jibiriilu lati wa fi mo awon musulumi alamori esin won.

Lati odo Umar – ki Olohun yonu si i – bakanna, o so pe:Laarin igba ti a joko si odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ni ojo kan, ni arakunrin kan ba wole to wa wa, aso re si funfun gbo, irun ori re si dudu kirikiri, ko si apere arinrin-ajo Kankan lara re, enikankan o si mon on ninu wa. Titi ti o fi joko si odo Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o wa fi orunkun re mejeeji ti orunkun Anabi mejeeji, o si gbe owo re mejeeji le ori itan re mejeeji, o wa so pe: Ire Muhammad, fun mi niro nipa Islam. Ojise Olohun – ki ike ati ola Oloun maa ba a – wa so pe: ohun ti nje Islam ni ki o jeri wipe ko si oba Kankan ayafi Allaah ati pe Muhammad ojise Allaah ni, ki o si maa gbe irun duro, ki o si maa yo zakah, ki o si maa lo si ile Olohun ti o ba ni ikapa ipese ti o fi le lo. O so pe: ododo lo so. O wa ya wa lenu fun un, oun ni nbi i leere ibeere, oun lo tun nso fun un wipe ododo lo so! O so pe: fun mi niro nipa Al-Iimaan {Igbagbo}. O so pe: ki o gba Olohun Oba gbo ati awon Malaika Re ati awon tira Re ati awon ojise Re ati ojo ikehin, ki o si ni igbagbo si kadara daada re ni ati aida re. O so pe: ododo lo so. O so pe: fun mi niro nipa Al-I'isaan {Sise daada}. O so pe: ki o maa josin fun Olohun gegebi wipe o nri I, ti oo ba waa ri I dajudaju Oun ri o. O so pe: fun mi niro nipa As-saahah {Igbati aye a pare}. O so pe: eniti a nbi leere nipa re ko ni imo ju eniti o nbeere lo. O sope: fun mi niro nipa awon amin ti aa maa ri ti aye ba ti fe pare. O so pe: ki eru maa bi olowo re, ati ki o maa ri awon arin ma wo bata ati awon arin ihoho ati awon alaini ti won a maa fi ile giga se iyanran. Leyin naa ni o wa lo, ni mo wa ko ara ro die, leyin naa ni o wa so pe: ire Umar, nje o mo eniti o nbeere ibeere? Mo so pe: Olohun ati ojise Re nikan lo mo on, o so pe: dajudaju Jubriil ni o wa bayin lati wa fi esin yin mo yin.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 8].

Hadith eleeketa.

Won mo Islaam lori nkan maarun.

Egbawa yi wa lati odo Abi Abdir Rahmaan Abdullah omo Umar omo Khattoob – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe: mo gbo ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – nso pe:Won mo islaam pa lori nkan maarun: jijeri pe ko si olujosin fun kankan ayafi Allaah atipe dajudaju Muhammad ojise Olohun ni, ati mimaa gbe irun duro, ati mimaa yo zakah, ati mimaa lo si ile Olohun, ati mimaa gba aawe Ramadan.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 8], ati Muslim [Number: 16].

Hadith eleekerin.

Dajudaju enikookan yin won ko eda dida re jo si inu ikun iya re.

Egbawa yi wa lati odo Abi Abdir Rahmaan Abdullah omo Mashood – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – bawa soro – o si je olododo eniti a maa ngba a lododo ti won si maa nso ododo fun -:Dajudaju enikookan yin won ko eda dida re jo si inu ikun iya re fun ogoji ojo ni omi logbologbo, leyin naa ni yio di eje kiki fun iru ojo yen, leyin naa ni yio di baasi eran fun iru ojo yen, leyin naa won yio ran malaika kan si i ti yio si fe emi si i lara, won o si pa a lase pelu gbolohun meerin kan: pelu kiko ijeemu re, ati iye igba ti yio lo laye, ati ise ti yio se, ati pe oloriibu ni yio je ni abi oloriire; mo wa fi Olohun Oba ti ko si olujosin fun mii leyin Re bura, dajudaju enikan ninu yin, yoo ti maa sise omo alujanna bo titi ti ohun ti yio seku laarin re ati alujanna ko ni ju ponna apa kan lo ni akosile o ba gba waju re ni yio ba maa sise omo ina yio si wo ina na. Dajudaju enikan naa ninu yin yio ti maa sise omo ina bo titi ti ohun ti yio seku laarin re ati ina ko ni ju ponna apa kan lo, ni akosile o ba gba waju re, ni yio ba maa sise omo alujanna yio si wo alujanna naa.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 3208], ati Muslim [Numbe2643 16].

Hadith eleekarun.

Eniti o ba da adasile kan si inu alamori wa yi leyiti ko si nibe tele, yio di nkan ti a maa da pada.

Egbawa yi wa lati odo iya awon muumini Umu Abdullah Aisha – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe: eniti o ba da adasile kan si inu alamori wa yi leyiti ko si nibe tele yio di nkan ti a maa da pada.Eniti o ba da adasile kan si inu alamori wa yi leyiti ko si nibe tele, yio di nkan ti a maa da pada.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 2697], ati Muslim [Numbe1718 16].Ninu egbawa ti Muslim:Eniti o ba se ise kan ti ko si ase wa nibe, yio di adapada.

Hadith eleekefa

Dajudaju nkan eto ti fi oju han atipe dajudaju nkan eewo na ti fi oju han.

Egbawa yi wa lati odo Abi Abdullah, An-Nuhmaan omo Basheer – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe: mo gbo ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – nso pe:Dajudaju nkan eto ti fi oju han, atipe dajudaju nkan eewo naa ni ti fi oju han, awon alaamori kan ti o ruju si wa laarin awon mejeeji ti opolopo ninu awon eeyan o de mo won, eniti o ba wa isora kuro nibi awon nkan ti o ruju yi, irufe eni bee ti se afomo fun esin re ati omoluabi re,eniti o ba wa ko si inu awon iruju yi, irufe eni bee ti ko sinu eewo, o da gegebi adaranje ti nda eran je ni etibebe ogba, o sunmo ki o je wo inu ogba naa, e teti gbo o, dajudaju gbogbo oba lo ni ogba tie, e teti gbo o, dajudaju ogba Olohun ni awon nkan ti o se leewo, e teti gbo o, dajudaju baasi eran kan nbe ninu ara, ti o ba ti daa gbogbo ara patapata lo ti daa, ti o ba si ti baje gbogbo ara patapata lo ti baje, e teti gbo o, oun naa ni okan.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 52], ati Muslim [Number:1599].

Hadiith eleekeje.

Esin ikilo ni.

Egbawa yi wa lati odo Abu Ruqoyyah Tamiim omo Aosi Ad-Daariyy – ki Olohun yonu si i – dajudaju Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Esin, ikilo ni. A so pe: fun taani? O so pe: fun Olohun, ati fun tira Re, ati fun ojise Re, ati fun awon asaaju awon musulumi, ati fun apapo won.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 55].

Hadiith eleekejo.

Won pa mi lase ki n maa gbogun ti awon eeyan.

Egbawa yi wa lati odo Ibnu Umar – ki Olohun yonu si awon mejeeji – dajudaju ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Won pa mi lase ki n maa gbogun ti awon eeyan titi ti won o fi jeri wipe ko si olujosin fun Kankan yato si Allaah, ati pe dajudaju Muhammad ojise Olohun ni, ti won o si maa gbe irun duro, ti won o si maa yo zakah; ti won ba ti wa se eleyi, won ti so awon eje won ati awon dukia won kuro lowo mi ayaafi eyiti o ba je iwo Islaam, isiro won si wa lowo Olohun ti ola Re ga.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 25], ati Muslim [Number:22].

Hadiith eleekesan.

Nkan ti mo ba ko fun yin ki e ya jina si i .

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah Abdur Rahmaan omo Sakhr – ki Olohun yonu si i – o so pe: mo gbo ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – nso pe:Nkan ti mo ba ko fun yin, ki e ya jina si i, nkan ti mo ba si pa yin lase re, ki e se eyiti e ba nikapa nibe; tori pe dajudaju ohun ti o ko iparun ba awon ti won saaju yin ni apoju awon ibeere won ati iyapa awon Anabi won.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 7288], ati Muslim [Numbe1337].

Hadiith eleekewa.

Dajudaju Olohun Oba Oba ti o mo ni, ko si ni gba nkankan ayafi nkan ti o mo.

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Dajudaju Olohun Oba Oba ti o mo ni, ko si ni gba nkankan ayafi nkan ti o mo, atipe dajudaju Olohun pa awon muumini lase pelu ohun ti o fi pa awon ojie lase, Oba Aleke-ola so pe: Mo pe eyin ojise, e maa je ninu awon nkan ti o ba mo, ki e si maa se ise rere, Oba Alekeola tun so pe: Mo pe eyin ti e ni igbagbo, e maa je ninu awon nkan ti o mo ti a se ni ijeemu fun yin, leyin naa ni o wa daruko arakunrin ti o ti pe ni irin-ajo, irun ori re ti ri wuruwuru, eruku si ti bo o, o wa te owo re mejeeji si sanmo: Ire Olohun mi! Ire Olohun mi! ounje ti o nje, haraamu ni, nkan ti o nmu, haraamu ni, aso ti o nwo, haraamu ni, won tun to o dagba pelu nkan haraamu, bawo ni adua re se fe gba?.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 1015].

Hadiith eleekokanla.

Gbe ohun ti nse e ni iyemeji sile ki o lo sibi ohun ti ko se e ni iyemeji.

Egbawa yi wa lati odo Abu Muhammad Al-Asan omo Aliy omo Abu Toolib omo omo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ati itutu oju re – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe:Mo ha lati enu ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a –Gbe ohun ti nse e ni iyemeji sile ki o lo sibi ohun ti ko se e ni iyemeji.Tirimidhiy gba egbawa yi wa [Number: 2520], ati Nasaaiy [Number: 5711].Tirmidhiy wa so pe: Hadiith yi dara o si ni alaafia.

Hadiith eleekejila.

Ninu didaa Islaam omoniyan.

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Ninu didaa Islaam omoniyan ni gbigbe nkan ti ko ba kan an ju sile.Hadiith to daa ni.Tirmidhiy gba egbawa yi wa [Number: 2318], ati Ibnu Maajah [Number: 3976].

Hadiith eleeketala.

Enikookan yin o le tii di onigbagbo titi ti yio fi fe fun omo-iya re ohun ti o ba nfe fun emi ara re.

Egbawa yi wa lati odo Abu Amzah Anas omo Maalik – ki Olohun yonu si i – omo odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – lati odo Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Enikookan yin o le tii di onigbagbo titi ti yio fi fe fun omo-iya re ohun ti o ba nfe fun emi ara re.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 13], ati Muslim [Number: 45].

Hadiith eleekerinla.

Eje omoniyan ti o je musulumi o le di eto ayafi pelu okan ninu nkan meta.

Egbawa yi wa lati odo Ibnu Mas'hood – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Eje omoniyan ti o je musulumi [to jeri wipe ko si olujosin fun Kankan ayafi Allaah atipe emi na ojise Olohun ni mi] o le di eto ayafi pelu okan ninu nkan meta: adelebo ti o je oni sina, ati fi fi emi di emi, ati olugbe esin sile; eniti o nyapa Jamaha.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 6878], ati Muslim [Number: 1676].

Hadiith eleekedogun.

Eniti o ba gba Olohun Oba ati ojo ikehin gbo, ki o ya maa so daada.

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah – ki Olohun yonu si i – dajudaju ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Eniti o ba gba Olohun Oba ati ojo ikehin gbo, ki o ya maa so daada tabi ki o dake, eniti o ba de tun gba Olohun Oba ati ojo ikehin gbo, ki o ya maa se aponle aladugbo re, eniti o ba de tun gba Olohun Oba ati ojo ikehin gbo, ki o ya maa se aponle alejo re.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 6018], ati Muslim [Number: 47].

Hadiith eleekerindinlogun.

O o gbodo maa binu.

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah – ki Olohun yonu si i – dajudaju arakunrin kan so fun Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: so asotele fun mi.o so pe: o o gbo maa binu, o tun wa wi i lawitunwi, o so pe: o o gbodo maa binu.Bukhaari lo gba egbawa yi wa [Number: 6116].

Hadiith eleeketadinlogun.

Dajudaju Olohun Oba ko daada lori gbogbo nkan.

Egbawa yi wa lati odo Abu Yahla Shaddaad omo Aosi – ki Olohun yonu si i – lati odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Dajudaju Olohun Oba ko daada lori gbogbo nkan, ti e ba ti wa fe pa nkan ki e yaa pa a daada, ti e ba si fe du nkan ki e yaa du u daada, ki enikookan yin o si pon nkan di o fee fi du u daada, ko si fun nkan ti o fe du ni isinmi.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 1955].

Hadiith eleekejidinlogun.

Beru Olohun ni aaye kaye ti o ba wa.

Egbawa yi wa lati odo Abu Dharri Jundub omo Junaadah ati Abu Abdur Rahmaan Muaadh omo Jabal – ki Olohun yonu si awon mejeeji – lati odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Beru Olohun ni aaye kaye ti o ba wa, maa fi daada tele aburu yio si maa pa abure naa re, maa ba awon eeyan lopo pelu iwa ti o daa.Tirimidhiy lo gba egbawa yi wa [Number: 1987].O wa so pe: hadiith yi daa, ninu akosile mii: hadiith ti o da ti o si ni alaafia ni.

Hadiith eleekokandinlogun.

Maa so iwo Olohun, Olohun o si maa so iwo naa.

Egbawa yi wa lati odo Abdullaah omo Abbaas – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe:Mo wa leyin ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ni ojo kan, o wa so pe:Ire odomode kunrin yi! Emi o fi awon gbolohun kan mo o: maa so iwo Olohun, Olohun o si maa so iwo naa, maa so iwo Olohun oo maa ri I ni iwaju re, ti o ba fe beere nkan maa beere lowo Olohun, ti o ba fe wa iranlowo maa wa a pelu Olohun, lo mo daju pe gbogbo ijo pata, ti won ba kora po lati fi nkankan se o ni anfaani, won o le se o ni anfaani Kankan ayafi pelu nkan ti Olohun Oba ti ko sile fun o, ti gbogbo won ba tun kojo lati fi inira kan o, won o le fi inira Kankan kan o koja eyiti Olohun Oba ti ko sile fun o; won ti gbe gege ikowe soke, takada si ti gbe.Tirimithiy lo gba egbawa yi wa [Number 2516].O wa so pe: hadiith ti o daa to si ni alaaafia ni.Ninu egbawa ti o yato si ti Tirimidhiy.Maa so iwo Olohun, o o si maa ri I ni iwaju re, da Olohun Oba mo nigba ti ara ba de o, Olohun o mo iwo naa nigba ti ilekoko ba ba o, lo mo pe nkan ti o ba fo o ru, ko si ninu nkan ti o ye ki o se o ni, nkan ti o ba waa se o, ko si ninu nkan ti o ye ki o fo e ru ni, wa lo mo wipe iri aranse wa pelu suuru sise, atipe iri ona abayo nbe fun gbogbo ifunpinpin, ati pe idekun nbe pelu gbogbo inira.

Hadiith ogun.

Ti o o ba ti ni ojuti, maa se nkan ti o ba wu o.

Egbawa yi wa lati odo Ibnu Mas'ood Uqbah omo Amri Al-Ansooriy Al-Badriy – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Dajudaju ninu nkan ti awon eeyan lepa ba ninu oro awon anabi ti o saaju: ti o o ba ti lojuti, maa se nkan ti o ba ti wu o.Bukhaari lo gba egbawa yi wa [Number: 3483].

Hadiith eleekokanlelogun.

So pe mo ni igbagbo pelu Olohun leyinnaa ki o wa duro deede.

Egbawa yi wa lati odo baba Amri, awon kan ni: baba Amrah ni nje, Sufyaan omo Abdullaah – ki Olohun yonu si i – o so pe:Mo so pe: mo pe iwo ojise Olohun! So oro kan fun mi ninu Islam ti mi o si ni bi enikankan leere mo yato si o; o so pe: So pe mo ni igbagbo pelu Olohun leyinnaa ki o wa duro deede.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 38].

Hadiith eleekejilelogun.

Oo ri ti mo ba ki awon irun oranyan ti mo si gba aawe Ramadan.

Egbawa yi wa lati odo baba Abdullaah Jaabir omo Abdullaah Al-Ansooriy – ki Olohun yonu si awon mejeeji - :Dajudaju arakunrin kan bi ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – leere, o si so pe: o o wa ri ti mo ba ki awon irun oranyan, ti mo si gba aawe Ramadan, ti mo se nkan eto letoo, ti mo se nkan eewo leewo, ti mi o se alekun Kankan lori ohun ti mo so yen; se maa wo Aljanna? O so pe: beeni.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 15].

Hadiith eleeketalelogun.

Imototo idaji igbagbo ni.

Egbawa yi wa lati odo baba Maalik Al-Aarith omo Aasim Al-Ash'ariy – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Imototo idaji igbagbo ni, gbolohun 'Alhamdulillaah' o ma nkun osunwon ise keke ni, gbolohun 'Subhaanallaah wal-Amdulillaah' mejeeji maa nkun – tabi ka so pe: o maa nkun – deede ohun ti nbe laarin sanmo ati ile ni, irun kiki imo le ni, saara sise atokun eni lo je, suuru sise imole lo je, Qurani je nkan ti yio jeeri gbe o tabi nkan ti yio jeeri tako o, gbogbo omo eniyan ni o maa mojumo, ti o si maa je eniti o ti gbe emi ara re ta, ninu ki o bo emi re kuro ni oko eru, tabi ki o ti emi re sinu iparun.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 223].

Hadiith eleekerinlelogun.

Eyin erusin mi, dajudaju mo se abosi ni eewo fun ara mi.

Egbawa yi wa lati odo baba Dharri Al-Gifaariy – ki Olohun yonu si i – lati odo Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ninu eyi o gba wa lati odo Olohun Oba re, Oba ti o mo ti ola Re si gbonngbon, o ni Olohun Oba so pe:Eyin erunsin mi:dajudaju emi se abosi leewo fun emi ara mi, mo si tun se e ni eewo naa laarin tiyin; e ko gbodo se abosi ara yin. Eyin erusin Mi! gbogbo yin ni eru ti o sonu, ayaafi eniti Emi Olohun ba se ifimona fun, e wa ifimona wa si odo Emi Olohun maa si fi yin mona. Eyin erusin Mi! gbogbo yin ni eru ti ebi npa, ayaafi eni ti Emi Olohun ba fun ni ounje, e wa ijeemu wa si odo Emi Olohun maa si fun yin ni jije. Eyin erusin Mi! gbogbo yin ni eru ti nrin ihoho, ayaafi eniti Emi Olohun ba da aso bo, e wa aso wa si odo Emi Olohun maa si da aso bo yin. eyin erusin Mi! dajudaju eyin nse asise loru ati ni osan, Emi si ni mo ma nse aforigin ese pata yanyan; e wa aforijin wa si odo Mi, maa si fi ori ese jin yin. Eyin erusin Mi! ee le de ogongo ifi inira kan Mi de bi wipe ee wa fi inira kan Emi Olohun, e ko le de ogongo isemi ni anfaani de bi pe ee wa se mi ni anfaani. Eyin erusin Mi! toba se pe awon eni akoko yin ati awon eni ikehin yin, ati awon eeyan inu yin ati awon aljannu inu yin, ti gbogbo yin ba ko ara yin jo si okan arakunrin kan ti o mo ju ninu yin, eleyi o le nkankan kun ola Emi Olohun rara. Eyin erusin Mi! toba se pe awon eni akoko yin ati awon eni ikehin yin, ati awon eeyan inu yin ati awon aljannu inu yin, ti gbogbo yin ba ko ara yin jo si okan arakunrin kan ti o ya pokii julo ninu yin, eleyi o din nkankan ku ninu ola Emi Olohun. Eyin erusin Mi! toba se pe awon eni akoko yin ati awon eni ikehin yin, ati awon eeyan inu yin ati awon aljannu inu yin ti gbogbo yin ba duro lori erupe kan soso, ti won wa nbi Mi leere nkan, ti mo wa nfun enikookan ni ohun ti o nbi Mi leere, eleyi o din nkankan ku ninu ola Emi Olohun, ayaafi odiwon ohun ti abere le mu nigba ti e ba ti i bo inu ibudo. Eyin erusin Mi! dajudaju awon ti e nwo yi ni awon ise yin ti Mo nba yin se amojuto re, leyinna maa wa ko o fun yin ni pipe; eniti o ba ri daada ki o dupe ni odo Olohun, eniti o ba wa ri idakeji ki o ma bu enikankan ayaafi ara re.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 2577].

Hadiith eleekeedogbon.

Awon olola ti ko laada lo tan.Egbawa yi wa lati odo Abu Dharri – ki Olohun yonu si i – bakanna, dajudaju awon kan ninu awon saabe ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – won so fun anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: ire ojise Olohun, awon olola ma ti ko gbogbo esan lo tan; won nki irun gegebi a ti se nki irun, won ngba aawe gegebi awa na ti se ngba aawe, awon nse saara pelu ohun ti o seku ninu owo won. O so pe: se kii se wipe Olohun Oba ti fun eyin naa ni ohun ti ee ma fi se saara ni? Dajudaju gbogbo 'Subhaanalloohu' ti e ba nwi saara ni, gbogbo 'Allaahu Akbar' ti e ba nwi saara ni, gbogbo 'Alhamdulillaah' ti e ba nwi saara ni, gbogbo 'Laa ilaaha illallaahu' ti e ba nwi saara ni, imaa pani lase daada sise saara ni, imaa ko ibaje fun awon eeyan saara ni, ki e maa ba eleto yin lopo saara ni. Won so pe: ire ojise Olohun, nje enikookan wa le maa ba arale re ni ajosepo ti yio si tun maa gba laada nbe bi? O so pe: ee wa mo ni ti o ba lo fi nkan okunrin re sibi haraamu, se kii wa se wipe ese nbe fun ni? Bee na ni ti o ba lo fi i sibi ona eto, yio gba laada le e lori.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 1006].

Hadiith eleekerindinlogbon.

Gbogbo aaye ipadepo eegun lara omoniyan pata ni saara nbe fun.

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Gbogbo aaye ipadepo eegun lara omoniyan pata ni saara nbe fun, gbogbo ojo ti oorun ba ti nyo ti o si nse deede laarin awon eeyan meji, saara ni, ati ki o maa ran omoniyan lowo nibi nkan ogun re; boya o gbe e gun un ni abi o na nkan igbadun re si i lori re, saara ni, ki gbolohun daada maa ti enu eniyan jade saara ni, gbogbo igbese kookan ti o ba ngbe lo si ibiti o ti fee lo kirun saara ni, mimaa mu nkan ti o le se awon eeyan ni suta kuro ni oju ona saara ni.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 2989], ati Muslim [Numbe100999].

Hadiith eleeketadinlogbon.

Mimaa se daada iwa rere lo je.

Egbawa yi wa lati odo An-Nawwaasi omo Sam'aan – ki Olohun yonu si i – lati odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Mimaa se daada iwa rere lo je, nkan ti o wa nje iwa ese, oun ni nkan ti nso kulukulu lemi re ti iwo na o si nife si ki omoniyan ka o mo ibe.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 2553].Egbawa yi wa lati odo Waabiso omo Ma'bad – ki Olohun yonu si i – o so pe: mo wa ba ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o wa so pe:O wa lati wa bere nipa mimaa se daada? Mo so pe: beeni. O wa so pe: Beere re lowo okan re, nkan ti nje iwa rere ni nkan ti emi re bale le lori, ti okan re naa si bale le lori, iwa ese ni nkan ti nso kulukulu lemi to si nlo ti si nbo ninu igbaaya, koda ki awon eeyan so idajo miran fun e, ki won tun so idajo miran fun e.Hadiith to daa ni.A gba egbawa yi wa ninu MUSNAD awon imaamu meji: Ahmad omo Anbal [Number: 4/227], ati Ad-Daarimiy [2/246] pelu afiti ti o daa.

Hadiith eleekejidinlogbon.

Mo nso asoole fun yin pelu iberu Olohun ati iwa rere.

Egbawa yi wa lati odo Abu Najiih Al-Ir'baad omo Saariyah – ki Olohun yon si i – o so pe:Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – se waasi kan fun wa to je wipe awon okan mi titi latara waasi naa, ti awon oju na si nda omije, a wa so pe: ire ojise Olohun! Waasi yi jo waasi eniti ndagbere, so asotele fun wa, o so pe: Mo nso asoole fun yin pelu iberu Olohun, ki e si maa teti gbo, ki esi maa tele, ki baa je eru lo je olori leyin lori, tori dajudaju eniti emi re ba gun daada ninu yin, yio ri iyapa enu ti o po, o wa di owo yin o ki e gba Sunnah emi anabi mu ati Sunnah awon Khaleefah olutonisona awon ti A fi mona, e fi awon eyin ogan yin de e mole, o di owo yin ki e jina si awon adadaale; tori dajudaju gbogbo adadaale pata anu ni.Abu Daaud gba egbawa yi wa [Number: 4607], ati Tirimidhiy [Number: 266].O wa so pe: hadiith ti o daa to si ni alaaafia ni.

Hadiith eleekokandinlogbon.

Maa sin Olohun Oba, o o si gbodo da ebo Kankan po mo On.

Egbawa yi wa lati odo Muaadh omo Jabal – ki Olohun yonu si i – o so pe: mo so pe: ire ojise Olohun! Fun mi niro nipa ise to je pe ti mo ba se e yio gbe mi wo Aljannah ti yio si mu mi ta kete si ina, o so pe:Dajudaju o ti beere nkan ti o tobi, atipe nkan ti o rorun ni fun eniti Olohun Oba ba se e ni irorun fun: maa sin Olohun Oba, oo si gbodo mu orogun mo On rara, ati ki o maa ki irun, atipe ki o maa yo Zakah, ki maa gba aawe Ramadan, ki o lo si Makkah, leyinna ni o wa so pe: se ki n toka re si awon ojuona ire? Aawe gbigba gaga loje kuro nibi ina, mimaa se saara, o maa npa asise eeyan re ni gegebi omi se maa npa ina, irun ti omoniyan ba ki ni aaringungun oru, leyinna o wa ka aaya yi: {Tatajaafa junuubuhum anil madoojihi} titi ti o fi de oro Olohun ti o so pe {Yahmaluun}, leyinna o wa so pe: se ki n fun o niro nkan ti o je ori oro ati opo ti o gbe e dani ati sonso ike re? mo ni: beeni ire ojise Olohun. O so pe: ori oro ni Islam, opo ti o gbe e duro ni irun kiki, nkan ti o wa je sonso ike eyin re ni mimaa jagun si oju ona Olohun, leyinna o wa so pe: se ki n fun o niro nkan ti o fi maa ni ikapa lori gbogbo nkan yen? Mo so pe: beeni ire ojise Olohun! O wa fa ahon re, o wa so pe: maa ko eleyi ni ijanu. Mo so pe: ire anabi Olohun, se won tun le maa fi iya jewa pelu nkan ti a fi nsoro ni? O wa so pe: o se fun e! nje nkankan le mu ki won da oju awon eeyan bole ninu ina – tabi o so pe: igimu won – to tayo ohun ti ahon won ka fun won lo?!Tirimidhiy lo gba egbawa yi wa [Number: 2616].O wa so pe: hadiith ti o daa to si ni alaaafia ni.

Hadiith ogbon.

Dajudaju Olohun Oba ti se awon nkan oranyan ni oranyan, e ko si gbodo ra won lare.

Egbawa yi wa lati odo Abu Thah'labah Al-Khushaniyyi Jur'thuum omo Naashib – ki Olohun yonu si i – lati odo ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Dajudaju Olohun Oba ti se awon nkan oranyan ni oranyan, e ko si gbodo ra won lare, O si pa awon aala, e ko gbodo tayo won, O se awon nkankan leewo, e ko gbodo fa ogba re ya, O si dake lori awon nkan, ike ni O fi se fun yin, kii se ti igbagbe, e ma wadi nipa won.Hadiith to daa ni.Ad-Daarulqut'niyyi gba egbawa yi wa ninu Sunanu re [4/184], ati elomii na.

Hadiith eleekokanlelogbon.

Ri aye sa ki Olohun Oba le nifee re

Egbawa yi wa lati odo baba Abbaas Sah'lu omo Sah'di – ki Olohun yonu si i – o so pe: arakunrin kan wa ba anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o wa so pe: ire ojise Olohun! Juwe mi si ise kan to je pe ti mo ba se e, Olohun a nife m, awon eeyan naa o si nifee mi; o wa so pe:Ri aye sa, Olohun Oba a nifee re, wa ri ohun ti nbe lodo awon eeyan naa sa, awon eeyan a nifee re.Hadiith ti o daa ni.Ibnu maajah gba egbawa yi wa [Number: 4102], ati elomi pelu awon afiti ti o daa.

Hadiith eleekejilelogbon.

Ma se maa ni eeyan lara, ma si maa gba esan inira.

Egbawa yi wa lati odo baba Saiid Sah'd omo Maalik omo Sinaan Al-Khudiriyyi – ki Olohun yonu si i – dajudaju ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Ma se maa ni eeyan lara, ma si maa gba esan inira.Hadiith to daa ni.Ibnu Maajah gba egbawa yi wa [Number: 2341], ati Ad-Daarulqut'niyyi [Number: 4/228], ati awon ti o yato si awon mejeeji ni eniti o se afiti re lati ibiti o ti bere tofi de odo anabi. Maalik naa gba a wa [2/746] ninu Al-Muwattah lati odo Amri omo Yah'ya lati odo baba re lati odo anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – leniti o yo saabe kuro ninu awon ti won gba a wa lati odo anabi, o ja Abu Saiid kuroOna ti o po ni won gba gba hadiith yi wa ti awon apa kan ona naa si nfun awon apa yoku ni agbara.

Hadiith eleeketalelogbon.

Eri je dandan fun eniti o ba pe ejo ibura si je dandan fun eniti o ba ko.

Egbawa yi wa lati odo Ibnu Abbaas – ki Olohun yonu si awon mejeeji – dajudaju ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Ti o ba je wipe won ma nfun awon eeyan ni eto pelu ipe apemora won ni, awon eeyan kan o ba maa pe apemore awon dukia awon eeyan kan ati awon eje won, sugbon eri pon dandan fun eniti o ba pe ejo, ibura si pon dandan fun eniti o ba ko.Hadiith to daa ni.Al-Baihaqiyy gba egbawa yi wa ninu Sunan [10/252], ati awon miran ti o yato si i bayi, atipe apakan re wa ninu Al-Sohiain.

Hadiith elekerinlelogbon.

Enikeni ti o ba ri nkan ti a ko ninu yin, ki o ya fi owo re yi i pada.

Egbawa yi wa lati odo Abu Saiid Al-Khudri – ki Olohun yonu si i – o so pe: mo gbo ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – nso pe:Enikeni ti o ba ri nkan ti a ko ninu yin, ki o yaa yi i pada pelu owo re, ti ko ba wa ni agbara, ki o ya yi i pada pelu ahon re, ti ko ba tun wa ni agbara, ki o ya yi i pada pelu okan re, atipe eleyi ni igbagbo ti o le ju.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 49].

Enikeni ti o ba ri nkan ti a ko ninu yin, ki o yaa yi i pada pelu owo re, ti ko ba wa ni agbara, ki o ya yi i pada pelu ahon re, ti ko ba tun wa ni agbara, ki o ya yi i pada pelu okan re, atipe eleyi ni igbagbo ti o le ju.

Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 49].

Hadiith eleekarundinlogoji.

E ma maa se keeta ara yin, e ma si maa da iye le oja lati so o di owon, e si ma maa korira ara yin.

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:E ma maa se keeta ara yin, e ma si maa se isesi ati maa so oja di owon fun eniti o fe ra a, e si ma maa korira ara yin, e ma si maa ko eyin si ara yin, atipe apa kan ninu yin ko gbodo maa ta oja leri oja ti elomii ba ti ta, atipe e je erusin Olohun Oba ni omoya, muslumi omoya muslumi ni, ko gbodo se abosi re, ko si gbodo ja a kule, ko si gbodo pa iro fun un, ko si gbodo yepere re, iberu Olohun wa ni ibiyi, o si na ika si aya re ni eemeta, o ti to fun omoniyan ni aburu ki o maa yepere omoya re ti o je musulumi, gbogbo musulumi lori musulumi kookan eewo lo je fun un: eje re ati dukia re ati omoluabi re.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 2564].

E ma maa se keeta ara yin, e ma si maa se isesi ati maa so oja di owon fun eniti o fe ra a, e si ma maa korira ara yin, e ma si maa ko eyin si ara yin, atipe apa kan ninu yin ko gbodo maa ta oja leri oja ti elomii ba ti ta, atipe e je erusin Olohun Oba ni omoya, muslumi omoya muslumi ni, ko gbodo se abosi re, ko si gbodo ja a kule, ko si gbodo pa iro fun un, ko si gbodo yepere re, iberu Olohun wa ni ibiyi, o si na ika si aya re ni eemeta, o ti to fun omoniyan ni aburu ki o maa yepere omoya re ti o je musulumi, gbogbo musulumi lori musulumi kookan eewo lo je fun un: eje re ati dukia re ati omoluabi re.

Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 2564].

Hadiith eleekerindinlogoji.

Eniti o ba gbe ifunpinpin kuro fun musulumi.

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah – ki Olohun yonu si i – lati odo Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Enikeni ti o ba si ilekoko kan kuro fun muumini ninu awon ilekoko aye, Olohun yio gbe kuro fun un ilekoko kan ninu awon ilekoko ojo igbende, atipe eniti o se irorun fun eniti ara nni, Olohun yio se irorun fun un ni aye ati ni ojo ikehin, atipe eniti o ba bo musulumi kan ni asiri, Olohun yio bo o ni asiri ni aye ati ni ojo ikehin, atipe Olohun wa nibi iranlowo eru lopin igba ti eru ba wa nibi iranlowo omoya re, atipe eniti o ba gba oju ona kan ti o nwa mimo nibe, Olohun yio fi oju ona yen se oju ona Alujanna ni irorun fun un, atipe awon eeyan kan ko nii ko ara won jo si inu ile kan ninu awon ile Olohun ti won nka tira Olohun, ti won si nko ara won laarin ara won; ayafi ki ifokanbale ko sokale le won lori, ati ki ike ko bo won daru, ati ki Olohun maa ranti won ni odo awon ti won wa ni odo Re, atipe enikeni ti ise re ba mu u lora, ebi re ko lee mu u yara.Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 2699] pelu gbolohun yii.

Enikeni ti o ba si ilekoko kan kuro fun muumini ninu awon ilekoko aye, Olohun yio gbe kuro fun un ilekoko kan ninu awon ilekoko ojo igbende, atipe eniti o se irorun fun eniti ara nni, Olohun yio se irorun fun un ni aye ati ni ojo ikehin, atipe eniti o ba bo musulumi kan ni asiri, Olohun yio bo o ni asiri ni aye ati ni ojo ikehin, atipe Olohun wa nibi iranlowo eru lopin igba ti eru ba wa nibi iranlowo omoya re, atipe eniti o ba gba oju ona kan ti o nwa mimo nibe, Olohun yio fi oju ona yen se oju ona Alujanna ni irorun fun un, atipe awon eeyan kan ko nii ko ara won jo si inu ile kan ninu awon ile Olohun ti won nka tira Olohun, ti won si nko ara won laarin ara won; ayafi ki ifokanbale ko sokale le won lori, ati ki ike ko bo won daru, ati ki Olohun maa ranti won ni odo awon ti won wa ni odo Re, atipe enikeni ti ise re ba mu u lora, ebi re ko lee mu u yara.

Muslim lo gba egbawa yi wa [Number: 2699] pelu gbolohun yii.

Hadiith eleeketadinlogoji.

Dajudaju Olohun ti ko awon daada ati awon aida.

Egbawa yi wa lati odo Ibnu Abbaas – ki Olohun yonu si awon mejeeji – lati odo ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a – nibi nkan ti o gba a wa lati odo Olohun Oba re ti O je Oni ibunkun ti O ga, o so pe:Dajudaju Olohun ti ko awon daada ati awon aida, leyinna o wa salaye iyen, enikeni ti o ba wa gbero lati se daada kan, sugbon ti ko wa se e, Olohun yi ko o sile ni odo Re ni daada kan ti o pe perepere, sugbon ti o ba wa gbero lati se e ti o si se e, Olohun yio ko o si odo Re ni daada mewa titi lo si ilopo ogorun meje titi lo si awon ilopo ilopo ti o po, amo ti o ba gbero lati se aburu kan ti ko wa se e, Olohun yio ko o si odo Re ni daada kan ti o pe, amo ti o ba gbero lati se e ti o si se e, Olohun yio ko o ni aburu eyokan.Bukhari gba egbawa yi wa [Number: 6491], ati Muslim [Number: 131], ninu Sohiih awon mejeeji pelu awon arafi ti a ka yi.

Dajudaju Olohun ti ko awon daada ati awon aida, leyinna o wa salaye iyen, enikeni ti o ba wa gbero lati se daada kan, sugbon ti ko wa se e, Olohun yi ko o sile ni odo Re ni daada kan ti o pe perepere, sugbon ti o ba wa gbero lati se e ti o si se e, Olohun yio ko o si odo Re ni daada mewa titi lo si ilopo ogorun meje titi lo si awon ilopo ilopo ti o po, amo ti o ba gbero lati se aburu kan ti ko wa se e, Olohun yio ko o si odo Re ni daada kan ti o pe, amo ti o ba gbero lati se e ti o si se e, Olohun yio ko o ni aburu eyokan.

Bukhari gba egbawa yi wa [Number: 6491], ati Muslim [Number: 131], ninu Sohiih awon mejeeji pelu awon arafi ti a ka yi.

Hadiith eleekejidinlogoji.

Enikeni ti o ba ba ore mi se ota, mo ti kede ogun fun un.

Egbawa yi wa lati odo Abu Urairah – ki Olohun yonu si i – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe: dajudaju Olohun Oba ti O ga so pe:Enikeni ti o ba ba ore Mi se ota, mo ti kede ogun fun un, atipe eru Mi ko lee fi nkankan sun mo Mi ti yio wa je nkan ti mo nife ju nkan ti mo se ni oranyan le lori lo, atipe eru mi ko nii ye ko nii gbo leniti yio maa sunmo mi pelu awon ise asegbore ti ti maa fi nifee re, ti mo ba wa ti nifee re, maa wa di eti re ti o fi ngbo oro, ati oju re ti o fi nri iran, ati owo re ti o fi ndi nkan mu, ati ese re ti o fi nrin, atipe dajudaju ti o ba beere nkan ni owo Mi, dajudaju Emi o fun un, atipe ti o ba wa iso lodo mi dajudaju Emi o so o.Bukhaari lo gba egbawa yi wa [Number: 6502].

Enikeni ti o ba ba ore Mi se ota, mo ti kede ogun fun un, atipe eru Mi ko lee fi nkankan sun mo Mi ti yio wa je nkan ti mo nife ju nkan ti mo se ni oranyan le lori lo, atipe eru mi ko nii ye ko nii gbo leniti yio maa sunmo mi pelu awon ise asegbore ti ti maa fi nifee re, ti mo ba wa ti nifee re, maa wa di eti re ti o fi ngbo oro, ati oju re ti o fi nri iran, ati owo re ti o fi ndi nkan mu, ati ese re ti o fi nrin, atipe dajudaju ti o ba beere nkan ni owo Mi, dajudaju Emi o fun un, atipe ti o ba wa iso lodo mi dajudaju Emi o so o.

Bukhaari lo gba egbawa yi wa [Number: 6502].

Hadiith eleekokandinlogoji.

Dajudaju Olohun ti bami se amojukuro fun awon ijo mi nibi asise ati igbagbe.

Egbawa yi wa lati odo Ibnu Abbaas – ki Olohun yonu si awon mejeeji – dajudaju ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Dajudaju Olohun ti bami se amojukuro fun awon ijo mi nibi asise ati igbagbe ati ohun ti won ba je won nipa se.Hadiith to daa ni.Ibnu Maajah gba a wa [Number: 2045], ati Al-Baihaqiyy [As-Sunan 7].

Dajudaju Olohun ti bami se amojukuro fun awon ijo mi nibi asise ati igbagbe ati ohun ti won ba je won nipa se.

Hadiith to daa ni.

Ibnu Maajah gba a wa [Number: 2045], ati Al-Baihaqiyy [As-Sunan 7].

Hadiith ogoji.

Maa be ni ile-aye gegebi wipe o je ajoji tabi eniti o fe re ona koja.

Egbawa yi wa lati odo Ibnu Umar – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – fi owo mu mi ni ejika, o si so pe:Maa be ni ile-aye gegebi wipe ajoji ni e tabi eniti o fe fo ona.Atipe Ibnu Umar – ki Olohun yonu si awon mejeeji – je eniti o maa nso pe:Ti o ba di ale, ma maa reti aaro, atipe ti o ba di aaro ma maa reti ale, atipe mu ninu alaafia re fun aisan re, ati ninu isemi re fun iku re.Bukhaari lo gba egbawa yi wa [Number: 6416].

Maa be ni ile-aye gegebi wipe ajoji ni e tabi eniti o fe fo ona.

Atipe Ibnu Umar – ki Olohun yonu si awon mejeeji – je eniti o maa nso pe:

Ti o ba di ale, ma maa reti aaro, atipe ti o ba di aaro ma maa reti ale, atipe mu ninu alaafia re fun aisan re, ati ninu isemi re fun iku re.

Bukhaari lo gba egbawa yi wa [Number: 6416].

Hadiith eleekokanlelogoji.

Enikankan ninu yin ko lee di olugbagbo titi ti ifenu re yio fi tele nkan ti mo mu wa.

Egbawa yi wa lati odo Abu Muhammad Abdullaah omo Amri omo Aas – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe: ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a – so peEnikankan ninu yin ko lee di olugbagbo titi ti ifenu re yio fi tele nkan ti mo mu wa.Hadiith ti o daa ti o si ni alaafia ni..A gba a wa ninu Kitaabul Ujjah pelu afiti ti o ni alaafia.

Enikankan ninu yin ko lee di olugbagbo titi ti ifenu re yio fi tele nkan ti mo mu wa.

Hadiith ti o daa ti o si ni alaafia ni..

A gba a wa ninu Kitaabul Ujjah pelu afiti ti o ni alaafia.

Hadiith eleekejilelogoji.

Iwo omo Aadam, dajudaju ti ire ba pe Mi ti o si rankan mi.

Egbawa yi wa lati odo Anas omo Maalik – ki Olohun yonu si i – o so pe: mo gbo ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba – ti o nso pe: Olohun Oba ti ola Re ga so pe:Ire omo Aadam! Dajudaju lopin igba ti o ba npe Mi ti o si nrankan si odo Mi, maa fi ori jin o lori gbogbo nkan ti o ba wa lati odo re, mi o si ni kunla, ire omo Aadam! Ti awon ese re ba ga de oke sanmo, leyinna ti o wa toro aforijin ni odo Mi, Emi yio fi ori jin o, ire omo Aadam! Dajudaju ti ire ba wa ba mi pelu nkan ti o to ile ni awon asise, leyinna ti o si pade Mi ti o o pa nkankan po pelu Mi, dajudaju Emi naa yio wa ba o pelu nkan ti o sunmo on ni aforijin.Tirimidhiy lo gba egbawa yi wa [Number: 3540]O si so pe: hadiith ti o daa ti o si ni alaafia ni.

Ire omo Aadam! Dajudaju lopin igba ti o ba npe Mi ti o si nrankan si odo Mi, maa fi ori jin o lori gbogbo nkan ti o ba wa lati odo re, mi o si ni kunla, ire omo Aadam! Ti awon ese re ba ga de oke sanmo, leyinna ti o wa toro aforijin ni odo Mi, Emi yio fi ori jin o, ire omo Aadam! Dajudaju ti ire ba wa ba mi pelu nkan ti o to ile ni awon asise, leyinna ti o si pade Mi ti o o pa nkankan po pelu Mi, dajudaju Emi naa yio wa ba o pelu nkan ti o sunmo on ni aforijin.

Tirimidhiy lo gba egbawa yi wa [Number: 3540]

O si so pe: hadiith ti o daa ti o si ni alaafia ni.

Hadiith eleeketalelogoji.

E ko awon ogun oranyan fun awon ti o ni i.

Egbawa yi wa lati odo Ibnu Abbaas – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe: ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:E ko awon ogun oranyan fun awon ti o ni i, eyiti oranyan ba wa seku yio maa je ti eniti o leto si i julo, oun naa ni okunrin.Bukhari gba egbawa yi wa [Number: 6732], ati Muslim [Number: 1615].

E ko awon ogun oranyan fun awon ti o ni i, eyiti oranyan ba wa seku yio maa je ti eniti o leto si i julo, oun naa ni okunrin.

Bukhari gba egbawa yi wa [Number: 6732], ati Muslim [Number: 1615].

Hadiith eleekerinlelogoji.

Ifunniloyan maa nso ohun ti ibi ma nso di eewo di eewo.

Egbawa yi wa lati odo Aaisha – ki Olohun yonu si i – lati odo anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Ifunniloyan maa nso ohun ti ibi ma nso di eewo di eewo.Bukhari gba egbawa yi wa [Number: 2646], ati Muslim [Number: 1444].

Ifunniloyan maa nso ohun ti ibi ma nso di eewo di eewo.

Bukhari gba egbawa yi wa [Number: 2646], ati Muslim [Number: 1444].

Hadiith eleekarundinlaadota.

Dajudaju Olohun ati ojise Re se tita oti ni eewo.

Egbawa yi wa lati odo Jaabir omo Abdullaah – ki Olohun yonu si awon mejeeji – dajudaju oun gbo ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ni odun ti won si Makkah ti o si wa ni Makkah, ti o nso pe:Dajudaju Olohun Oba ati ojise Re so oti tita di eewo, ati oku nbete, ati elede, ati awon ere, won wa so wipe: ire ojise Olohun, o wa ri awon ora oku nbete, won maa nfi i kun oko oju omi, atipe won maa nfi i kun awon awo, atipe awon eeyan fi maa ntan ina? O wa so pe: rara, eewo ni, leyinna ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – wa so nigbayen pe: Olohun yio sebi le awon Yahuudi, dajudaju Olohun se awon ora ni eewo fun won, won wa yo o, leyinna won wa ta a, won si je owo re.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 2236], ati Musli [Number: 1581].

Dajudaju Olohun Oba ati ojise Re so oti tita di eewo, ati oku nbete, ati elede, ati awon ere, won wa so wipe: ire ojise Olohun, o wa ri awon ora oku nbete, won maa nfi i kun oko oju omi, atipe won maa nfi i kun awon awo, atipe awon eeyan fi maa ntan ina? O wa so pe: rara, eewo ni, leyinna ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – wa so nigbayen pe: Olohun yio sebi le awon Yahuudi, dajudaju Olohun se awon ora ni eewo fun won, won wa yo o, leyinna won wa ta a, won si je owo re.

Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 2236], ati Musli [Number: 1581].

Hadiith eleekerindinlaadota.

Gbogbo ohun ti o ba ti le muni hunrira, eewo ni.

Egbawa yi wa lati odo Abu Burdah lati odo baba re lati odo Abu Muusa Al-Ash'ariyy – ki Olohun yonu si i – dajudaju Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – gbe e dide lo si Yaman, o si bi i leere nipa awon ohun mimu ti won nse ni ibe, o wa so pe: kinni awon ohun mimu naa? O wa so pe: oun naa ni Bit'hu ati Miz'ru, won wa so fun Abu Burdah pe: kini a npe ni Bit'hu? O wa so pe: oti ti won se lati ara oyin, atipe nkan ti o nje Miz'ru ni oti ti won se lara yangan, o wa so pe: gbogbo ohun ti o ba ti le mu ni hunrira eewo ni.Bukhaari lo gba egbawa yi wa [Number: 4343]. Bukhaari lo gba egbawa yi wa [Number: 4343].

Hadiith eleeketadinlaadota.

Omo Aadam kan ko kun igba kan to buru ju ikun lo.

Egbawa yi wa lati odo Miq'daam omo Mah'diyak'rib o so pe: mo gbo ti ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – nso pe:Omo Aadam kan ko kun igba kan to buru ju ikun lo, o ti to omo Aadam awon ounje kan ti yio gbe okun inu re duro, amo ti ko ba wa si ibuye, idameta ikun re ki o maa be fun ounje, idameta miran ki o maa be fun mimu re, idameta miran ki o si maa be fun mimi re.Ahmad gba egbawa yi wa [Number: 4/132], ati Tirimidhiy [Number: 2380], ati Ibnu Maajah [Number: 3349],Tirimidhiyy wa so pe: hadiith ti o daa ni.

Omo Aadam kan ko kun igba kan to buru ju ikun lo, o ti to omo Aadam awon ounje kan ti yio gbe okun inu re duro, amo ti ko ba wa si ibuye, idameta ikun re ki o maa be fun ounje, idameta miran ki o maa be fun mimu re, idameta miran ki o si maa be fun mimi re.

Ahmad gba egbawa yi wa [Number: 4/132], ati Tirimidhiy [Number: 2380], ati Ibnu Maajah [Number: 3349],

Tirimidhiyy wa so pe: hadiith ti o daa ni.

Hadiith eleekejidinlaadota.

Awon nkan meerin kan eniti o ba wa lara re yio je munaafiki.

Egbawa yi wa lati odo Abdullaah omo Amri – ki Olohun yonu si awon mejeeji – dajudaju Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe:Awon nkan meerin kan eniti o ba wa lara re yio je munaafiki, atipe ti o ba je pe iroyin kan wa lara re ninu won, iroyin kan ninu iroyin pooki sise ni o wa lara re titi ti yio fi gbe e ju sile: eniti o se wipe ti o ba soro yio paro, atipe ti o ba se adehhun yio yapa, atipe ti o ba ja yio ma so oro ibaje, atipe ti o ba se adehun yio jamba.Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 34], ati Muslim [Number: 58].

Awon nkan meerin kan eniti o ba wa lara re yio je munaafiki, atipe ti o ba je pe iroyin kan wa lara re ninu won, iroyin kan ninu iroyin pooki sise ni o wa lara re titi ti yio fi gbe e ju sile: eniti o se wipe ti o ba soro yio paro, atipe ti o ba se adehhun yio yapa, atipe ti o ba ja yio ma so oro ibaje, atipe ti o ba se adehun yio jamba.

Bukhaari gba egbawa yi wa [Number: 34], ati Muslim [Number: 58].

Hadiith eleekokandinlaadota.

Ti o ba je pe eyin ngbara le Olohun ni paapa igbarale re.

Egbawa yi wa lati odo Umar omo Al-Khattaab – ki Olohun yonu si i – lati odo Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o so pe:Ti o ba je pe eyin ngbara le Olohun ni paapa igbarale re, ko ba se ijeemu fun yin gegebi o se maa nse ijeemu fun eye; yio lo ni aaro ni eniti ebi npa yio si seri pada ni eniti o ti yo.Ahmad gba egbawa yi wa [Number 01 ati 52], ati Tirimidhiy [Number: 2344], ati Nasaaiy ninu Al-Kubrah gegebi o se wa ninu At-Tuh'fah: [Number: 8/79], ati Ibnu Maajah [Number: 4164], Ibnu Ibbaan so pe o ni alaafia (730), ati Haakim 418,Tirimidhiy so pe: hadiith ti o daa ti o si ni alaafia ni.

Ti o ba je pe eyin ngbara le Olohun ni paapa igbarale re, ko ba se ijeemu fun yin gegebi o se maa nse ijeemu fun eye; yio lo ni aaro ni eniti ebi npa yio si seri pada ni eniti o ti yo.

Ahmad gba egbawa yi wa [Number 01 ati 52], ati Tirimidhiy [Number: 2344], ati Nasaaiy ninu Al-Kubrah gegebi o se wa ninu At-Tuh'fah: [Number: 8/79], ati Ibnu Maajah [Number: 4164], Ibnu Ibbaan so pe o ni alaafia (730), ati Haakim 418,

Tirimidhiy so pe: hadiith ti o daa ti o si ni alaafia ni.

Hadiith aadota.

Ahon re ko gbodo ye ko gbodo gbo ni ohun ti yio maa tutu pelu iranti Olohun Oba ti O gbongbon.

Egbawa yi wa lati odo Abdullaah omo Bus'ri o so pe:Okunrin kan wa ba Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o wa so pe: ire ojise Olohun dajudaju awon ofin Islaam ti po fun wa, fun wa ni oju opo kan ti a a diro mo ti o si ko nkan sinu? O wa so pe: Ahon re ko gbodo ye ko gbodo gbo ni ohun ti yio maa tutu pelu iranti Olohun Oba ti O gbongbon.Ahmad lo gba egbawa yi wa [Number: 188 ati 190].

Okunrin kan wa ba Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o wa so pe: ire ojise Olohun dajudaju awon ofin Islaam ti po fun wa, fun wa ni oju opo kan ti a a diro mo ti o si ko nkan sinu? O wa so pe: Ahon re ko gbodo ye ko gbodo gbo ni ohun ti yio maa tutu pelu iranti Olohun Oba ti O gbongbon.

Ahmad lo gba egbawa yi wa [Number: 188 ati 190].