معنى معرفة الإسلام بالأدلة
أعرض المحتوى باللغة الأصلية
فتوى مترجمة إلى لغة اليوربا عبارة عن سؤال عن معنى قول المؤلف "يجب معرفة الإسلام بالأدلة" في كتاب حاشية الأصول الثلاثة, ومعنى قوله: "أرسل الله إلينا رسولا فمن أطاعه دخل الجنة ومن عصاه دخل النار" في نفس الكتاب.
ITUMO KI A NI AGBOYE ESIN ISLAM PELU AWON ERI
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia
Eni ti o tumo re ni: Rafiu Adisa Bello
2014 - 1435
معنى معرفة الإسلام بالأدلة
« بلغة اليوربا »
الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء
في المملكة العربية السعودية
ترجمة: رفيع أديسا بلو
2014 - 1435
ITUMO KI A NI AGBOYE ESIN ISLAM
PELU AWON ERI
IBEERE:
Kinni itumo gbolohun eni ti o ko tira ti oruko re n je (Haashiyatul Usuul As-salaasa) nigbati o so wipe: "O je dandan ki a mo esin Islam pelu awon eri"? O si tun so ni aaye miran wipe: "Olohun ran ojise kan si wa, eni ti o ba tele e yoo wo ogba idera (Al-janna), eni ti o ba si yapa ase re yoo wo ina". Se ohun ti eleyi tumo si ni titele ojise Olohun abi sise Olohun ni okan soso nibi awon iroyin re?
---------------------------------------------------------------------
IDAHUN:
Itumo oro eni ti o se tira ti a daruko yi nigbati o so wipe "O je dandan ki a mo esin Islam pelu awon eri" ni wipe: O je dandan fun eni ti a ti la iwo bo l'orun (eni ti o ti balaga) pe ki o ko eko nipa awon origun esin Islam lati ibi ti o je orisun ti o ti ye ki a ko oro esin, awon nkan naa ni tira Olohun Al-kurani Alaponle ati sunna ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a. Ki o ko eko nipa mimo Olohun ni okan soso (Taoheed) ati ohun ti o maa n ko aaye ba a ati ohun ti o maa n ba a je patapata. Ki o ko eko nipa irun kiki ati awon majemu re ati awon origun re ati awon sunna re, ki o ko awon nkan wonyi ninu Al-kurani Alaponle ati lati ibi awon oro ojise Olohun ti o wa ni akosile ati awon ise re ati awon nkan ti apakan ninu awon omoleyin ojise se ni oju re ti ko si ko fun won. Bayi ni o ye ki Musulumi maa ko nipa awon origun esin Islam ti o ku ati awon ofin esin naa.
Bakannaa gbolohun re ti o so pe "Olohun ran ojise kan si wa, eni ti o ba tele e yoo wo ogba idera (Al-janna), eni ti o ba si yapa ase re yoo wo ina" itumo re ni wipe: Olohun- Oba ti O ga julo- gbe Anabi wa Muhammad dide ni ojise pelu mimo Olohun ni okan soso (Taoheed) ati awon ofin esin yoku, eni ti o ba je ipepe re ti o gba esin Olohun, ti o si tele awon ofin Olohun naa, ti o si jinna si awon ohun ti Olohun se ni eewo fun un irufe eni bee yoo wo ogba idera. Sugbon eni ti o ba ko, ti ko gba esin Olohun, ti o tun tapa si ofin ojise Olohun ati ilana re irufe eni bee yoo wo ina. Idi niyi ti Olohun- mimo fun Un- fi so ninu Al-kurani wipe: {Enikeni ti o ba tele ojise naa, lotito o ti tele Olohun, enikeni ti o ba si peyinda (ti ko tele e), Awa ko ran o (ire Anabi) pe ki o je oluso le won lori} [Suuratu Nisaai: 80].
Ni afikun, o tun wa ninu hadiisi ti ojise Olohun so wipe: "Gbogbo ijo mi ni yoo wo ogba idera (Al-janna) ayafi eni ti o ba ko", awon omoleyin re si beere wipe: Tani yoo ko ire ojise Olohun? Ojise Olohun wa so bayi pe: "Eni ti o ba tele ase mi yoo wo ogba idera (Al-janna), eni ti o ba si yapa ase mi irufe eni bee ti ko lati wo ogba idera (Al-janna)" [Bukhari: 7280].