Ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi kosi ninu Ẹsin Islam
Àwọn ìsọ̀rí
Àwọn ipilẹ ti a ti mú nǹkan
Full Description
Ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi kosi ninu Ẹsin Islam
الاحتفال بمولد نبينا محمد- صلى الله عليه وسلم- ليس من الإسلام
< يوربا - Yorùbá >
Dr. Mubarak Zakariya Al-Imam
الدكتور مبارك زكرياء الإمام
Atunyẹwo: Rafiu Adisa Bello
مراجعة: رفيع أديسا بلو
Ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi kosi ninu Ẹsin Islam
Ni deede asiko ti a wa yi (Osu kẹta oju ọrun ti a mọ si Rabiul-awwal) ni ọdọọdun, o ti gbajumo wipe awọn kan ninu Musulumi maa n se ayajọ ọjọ ibi Anabi Muhammad [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a], pẹlu erongba wipe awọn n fi eleyi se ijọsin fun Ọlọhun, ati lati se afihan ifẹ awọn fun Anabi wa Muhammad, ati bẹẹbẹẹ lọ ninu awọn erongba ti o mu wọn maa se ọjọ ibi Anabi.
Njẹ gbogbo awọn nkan wọnyi to fun wa gẹgẹ bii ẹri ti a le gbe ara le lati maa se ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi Muhammad bi?
Idahun si ibẹrẹ yi ni wipe: awọn nkan wọnyi ko to gẹgẹ bii arojare ti a fi le maa se ọjọ ibi Anabi, fun awọn idi Pataki ti a fẹ mu wa yi:
Alakọkọ : Ẹsin Islam jẹ ẹsin ti o wa lati ọdọ Ọlọhun, kii se ẹsin ti awọn ẹniyan kan fi ọgbọn ori ati oye wọn gbe kalẹ, idi niyi ti o fi jẹ wipe ẹsin naa ko ni abuku tabi adinku rara, Ọlọhun naa si ti jẹri bẹẹ wipe odidi ẹsin ti o pe ni Oun fi ran Anabi wa Muhammad [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] si aye, gẹgẹ bi o se wa ninu Alukurani wipe:
{ ﭻ ﭼ ﭽ ﭾ ﭿ ﮀ ﮁ ﮂ ﮃ ﮄ ﮅﮆ } [سورة المائدة:3]
Itumọ: (Ni ọjọ oni yi – ọjọ Arafa- Emi Ọlọhun ti se ẹsin yin ni pipe fun yin, Mo si ti pari idẹra mi fun yin ati wipe Mo yọnu si Islam ni ẹsin fun yin) ]Suuratu maaida: 3[.
Nigbati Aaya Alukurani yi sọ kalẹ, awọn isẹlẹ kan sẹlẹ pẹlu rẹ, ti o yẹ ki a ronu si, Anabi wa Muhammad [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] n fi Ọlọhun se ẹlẹri wipe oun ti jẹ gbgbo isẹ ti Ọlọhun fi ran oun si ara aye, Anabi n sọ ni aaye naa wipe: {Irẹ Ọlọhun jẹ ẹlẹri fun mi}, ti gbogbo awọn ti wọn wa ni aaye naa si n sọ pe : Bẹẹni, o ti jẹ isẹ naa de opin gege bi Ọlọhun se fi ran ọ)).(Saheehul bukhariy).
Oun ti a fẹ ki o ye wa ni wipe gbogbo oun ti Ọlọhun n fẹ ki a fi se ijọsin fun Oun ni O ti se alaye rẹ si inu Alukurani Alapọnle fun Anabi wa muhammad.
Awọn nkan wọnyi naa si ni awọn Musulumi ti wọn ti siwaju fi sin Ọlọhun. Kosi ẹnikan ninu awọn ọmọlẹyin Anabi wa Muhammad ti o se ọjọ ibi Anabi, boya ni oju aye Anabi tabi lẹyin ti o ku tan.
Fun idi eyi, ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi (maolidi) ko si ninu ẹsin Islam. Sugbọn ti a ba gba wipe o wa ninu Islam, itumọ rẹ ni wipe ẹsin awọn ọmọlẹyin Anabi (sahabe) –Abu bakr, Umar, Usman, Aliy- ati gbogbo awọn ti o wa lẹyin wọn, ẹsin wọn ko pe ni, ẹsin ti awa n se ni ode oni ni o pe perepere nitori pe awa n se ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi (maolidi) ti awọn ko se!!!
Ohun ti o daju ni wipe kosi Musulumi ti o le sọ eleyi, ti o ba wa ri bẹẹ, a jẹ wipe awa ni a mu ohun ti ko si ni ara ẹsin wọ inu ẹsin.
Ẹlẹẹkeji: Awọn Yahuudi ilu madinah n sọ fun awọn Musulumi wipe: "Ti o ba jẹ wipe awa yahuudi ni Ọlọhun sọ aaya yi – eyi ti a tọka si siwaju - fun gẹgẹ bi O ti sọ kalẹ fun ẹyin Musulumi, awa yoo ya ọjọ naa si ọtọ ni gẹgẹ bi ọjọ odun". Oun ti o mu wọn sọ bẹẹ ni wipe aaya ti a tọka si naa jẹ ẹri wipe kosi nkan ti Ọlọhun N fẹ ninu ijọsin ni ọdọ Musulumi ti ko si alaye rẹ ninu Alukurani, kii se pe a o maa se wahala lati ronu sii tabi Iati jiroro lori rẹ. Idi niyi ti wọn fi ri wipe o tọ ki awọn mu ọjọ naa ni ọjọ odun. A o si rii wipe awọn Yahudi gan an gba wipe ẹsin Islam ẹsin ti Ọlọhun ti pari alaye lori rẹ ni. Nitorinaa ohunkohun ti ko ba si ninu Alukurani, ti Anabi wa Muhammad ko si mu wa fun wa ninu ọrọ ẹsin, nkan naa kii se ara ẹsin Islam rara, Ọlọhun sọ pe:
{ ﮟ ﮠ ﮡ ﮢ ﮣ ﮤ ﮥ ﮦ ﮧﮨ } [سورة الحشر:7].
Itumọ: (Atipe ohunkohun ti Ojisẹ naa ba mu wa fun yin ki ẹ gba a, ohunkohun ti o ba si kọ fun yin ki ẹ jinna si i) [Suuratul Hashri: 7].
Fun idi eyi, sise ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi (maolidi) kiise ara ẹsin Islam, nitoripe ko si ninu Alukurani, Anabi wa Muhammad ko si sọ nipa rẹ, eyi ni o n jẹ ki a mọ wipe kosi ninu ẹsin Islam rara, ti o ba jẹ ara ẹsin ni Anabi wa yoo ti se alaye rẹ fun wa.
Sugbọn ti a ba gba wipe o wa ninu ẹsin, ti Anabi ko se alaye fun ara aye itumọ rẹ ni wipe Anabi ko jẹ ise ti Ọlọhun ran an de ibi ti o yẹ, ti a ba wa gba wipe ko jẹ ise Ọlọhun de ibi ti o yẹ eleyi tumọ si wipe o se ijamba nibi isẹ naa ti Ọlọhun fi ran an si ara aye. Imam Malik [Ki Ọlọhun kẹ ẹ] sọ ninu ọrọ rẹ wipe: (Ẹniti o ba mu nkan tuntun kan wa si inu Islam, ti o lero wipe nkan naa dara ninu ẹsin, ẹni bẹẹ ti gba wipe Anabi wa muhammad ko jẹ isẹ Ọlọhun bi o se yẹ).
O damiloju wipe kosi Musulumi ti o le sọ eleyi, ti o ba ri bẹẹ; ajẹwipe Anabi wa jẹ isẹ Ọlọhun bi o se tọ ati bi o se yẹ, sugbọn ọrọ maoludi ko lẹto ninu ẹsin, idi niyi ti Anabi ko fi se e, ti ko si sọ fun wa wipe ki a se e.
Fun apẹerẹ: ọrọ asalatu, ọrọ kiki Anabi [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a], mejeeji ni o kan Anabi, ti Ọlọhun si pa asẹ wipe ki awa Musulumi se e, a o rii wipe Anabi se alaye mejeeji yi bi a o se se wọn, sugbọn nitoripe ọrọ maolidi ko si ninu ẹsin idi niyi ti Ọlọhun ati Anabi ko fi pa wa ni ase ki a se e.
Ẹlẹẹkẹta: Ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi (maolidi) kiise ara ẹsin islam; nitoripe ko si akọsilẹ wipe ẹnikankan se ọjọ ibi anabi ninu awọn ti gbogbo Musulumi gba fun gẹgẹ bi asiwaju ati ẹni ti o se ẹsin de ogongo, ti Ọlọhun si ti fun wọn ni iwe ẹri lati ile aye wipe wọn yoo wọ ọgba idẹra (Alujanna), gẹgẹ bii Abubakr, Umar, Usman, Aliy, ati awọn ti o wa ni ẹyin wọn. Bẹẹni awọn asiwaju ẹsin (Imaamu) mẹrin ti a gba fun, gẹgẹ bii Imam Abu Haniifa, Imam Malik, Imam Shafi', Imam Ahmad bin Hanbal. Ti o ba wa ri bayi, o ye ki a mọ wipe ẹsin tuntun ni maolidi jẹ, kii se ẹsin ti Ọlọhun ran Anabi wa Muhammad [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a].
Ẹlẹẹkẹrin: Kii se maoludi Anabi ni ọna ti Anabi n fẹ ki a fi se afihan ifẹ ti awa Musulumi ni si oun, tabi amin wipe ohun se pataki ni ọdọ wa. Ọna ti Anabi la silẹ fun wa lati se afihan ifẹ ti a ni si ohun ni wipe ki a tẹle ilana rẹ, ẹsin rẹ, iwa rẹ ati ohun ti o muwa fun wa ninu Alukurani ati sunna, gẹgẹ bi Ọlọhun se sọ pe:
{ ﭮ ﭯ ﭰ ﭱ ﭲ ﭳ ﭴ ﭵ } [سورة آل عمران:31].
Itumọ: (Irẹ Anabi sọ fun wọn wipe: Ti o ba jẹ wipe ẹyin n fẹran Ọlọhun; ki ẹ maa tẹle emi Anabi, Ọlọhun yoo maa fẹran yin).
Ẹlẹẹkarun: Anabi ti se ikilọ fun wa pupọ ki o to jade laye wipe ohun ti Ọlọhun n fẹ ki a fi se ijọsin fun Oun ti yoo si beere lọwọ wa ni ọrun oun ti se alaye gbogbo rẹ fun wa patapata, ki a sọra ki a si jinna si adadasilẹ. Ohun ti o njẹ adadasilẹ si ni ki a mu ohun ti ko si ninu ẹsin tẹlẹ, ki a mu u wọ inu ẹsin, gẹgẹ bii sise ayẹyẹ ọjọ ibi Anabi (maolidi).
Ojise Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ wipe:
{من أحدث في أمرنا هذا ما ليس منه فهو رد} (متفق عليه).
Itumọ: (Ẹnikẹni ti o ba da nkankan silẹ ninu ẹsin wa yi, ti kosi nibẹ tẹlẹ, Ọlọhun ko ni gba nkan naa ni ọwọ rẹ) [Bukhari ati Muslim].
Nitorina, ẹyin Musulumi, ẹ jẹ ki a tẹlẹ ikilọ Anabi yi nitoripe isẹ asedanu ni fun ẹniti o ba se ohun ti ko ba si ninu ẹsin.
Ẹlẹẹkẹfa: Eyikeyi ijọsin ti ko ba si asẹ Ọlọhun ati Anabi nibẹ ọna anu ni irufẹ ijọsin naa ti yoo si se okunfa ibinu Ọlọhun. Ojise Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ wipe:
{وإياكم ومحدثات الأمور, فإن كل محدثة بدعة وكل بدعة ضلالة} رواه أو داود.
Itumọ: (Ẹ sọra fun mimu awọn nkan ti kosi ninu ẹsin tẹlẹ wọ inu ẹsin, nitoripe irufẹ awọn nkan wọnyi adadasilẹ ni wọn jẹ, gbogbo adadasilẹ naa si jẹ isina) [Abu Dauud].
Fun idi eyi, ẹyin ọmọ iya mi ninu Islam, ẹ jẹ ki a jawọ nibi awọn nkan wọnyi, ki a si duro ti ilana (sunna) Anabi wa Muhammad, ki a ma jẹ alatako fun ẹsin ati ofin ati ilana ti o fi siIẹ fun wa, ki a ma baa di ẹniti Ọlọhun yoo binu si gẹgẹ bi O ti sọ wipe:
{ ﭮ ﭯ ﭰ ﭱ ﭲ ﭳ ﭴ ﭵ ﭶ ﭷ ﭸ ﭹ ﭺ ﭻ ﭼ ﭽ ﭾ ﭿﮀ ﮁ ﮂ ﮃ } [سورة النساء:115].
Itumọ: (Ẹnikẹni ti o ba kọ ẹyin si oju ọna Anabi, lẹyin ti o ti mọ ọna, ti o wa tẹle oju ọna awọn ti wọn kii se onigbagbọ ododo, Awa Ọlọhun yoo yọ ọwọ ninu ọrọ rẹ, A o si fi si inu ina jahanama, eyi ti o buru julọ ni ibudarisi) [Suuratu Nisaai: 115].
Ki Ọlọhun see ni irọrun fun wa lati maa tẹle suna Anabi, ki a si le jinna si awọn ohun ti Anabi ko se ninu ẹsin.