×
Ibeere nipa itumo aseju ninu esin, awon onimimo se alaye ohun ti o n je aseju ninu esin won si mu apejuwe re wa pelu awon eri.

    ALAYE ITUMO ASEJU NINU ESIN

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia

    Itumo Si Ede Yoruba: Rafiu Adisa Bello

    Atunyewo: Abdur-rosheed Adeniyi Abdur-rou'f

    2014 - 1435

    بيان معنى الغلو في الدين

    « بلغة اليوربا »

    الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء

    في المملكة العربية السعودية

    ترجمة: رفيع أديسا بلو

    مراجعة: عبد الرشيد أدينيي عبد الرؤوف

    2014 - 1435

    ALAYE ITUMO ASEJU NINU ESIN

    [Lati inu Fatawa Nur ala Darb, Idi Keta Oju ewe 36- 37 Ibeere Kesan].

    IBEERE:

    Kinni paapaa aseju ti Olohun ko fun wa pe ki a ma se ninu esin?

    ------------------------------------------------------------------

    IDAHUN:

    Aseju ni kikoja enu aala ohun ti Olohun se ni ofin ninu esin, gege bi Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ti so wipe: ([Eyin Musulumi] e jinna si sise aseju ninu esin, nitoripe ohun ti o ko iparun ba awon ijo ti won siwaju yin naa ni aseju ninu esin) [1].

    Ojise Olohun tun so ni aaye miran pe: (Awon alaseju iparun ti ba won o) [2], o wi gbolohun yi ni eemeta.

    Itumo aseju ninu esin si ni sise alekun lori ohun ti Olohun ti se ni ofin, apeere aseju ni bii ki eniyan ko ile si ori saaree oku tabi ki o mu ile naa ni mosalaasi, ki o maa ki irun nibe, apejuwe aseju ninu esin niyi, nitoripe o je alekun lori ohun ti Olohun ti se ni ofin. Ohun ti Olohun se ni ofin ni ki Musulumi se abewo omo iya re ti o ti ku, ki o si toro aforiji ati ike Olohun fun un, ki o si mase ko ile si ori saare oku re tabi ki o dara si i.

    Kiko ile si ori saaree oku je okan ninu awon ohun ti o maa n se okunfa ebo sise, eyi ti o je ohun eewo ninu esin Islam. Ojise Olohun ti ko eleyi fun awa Musulumi, o si se ibi le awon Yahudi ati Nasaara ti won maa n se bee. Nitori idi eyi, irun kiki nibi saare oku je okan ninu ojuponna aseju ninu esin ti o si le mu eniyan se ebo si Olohun.

    Beenaani gbogbo alekun lori ohun ti Olohun ba se ni ofin, gege bii ki eniyan maa fo orikerike aluwala ni igba ti o ju eemeta lo, alekun lori ofin Olohun ni eleyi jasi. Bakannaa ni ki eniyan maa se koja ohun ti Olohun pa lase ninu irun kiki, gege bii ki o te ni ori irun [rukuu] ni ona ti o le ko inira ba a tabi ko inira ba awon ti won n ki irun leyin re, tabi ki o fi ori kan ile ninu irun [sujuud] ni ona ti o le ko inira ba a tabi ko inira ba awon ti won n ki irun leyin re.

    Ohun ti o je dandan fun Musulumi ni ki o gbiyanju lati wa ni wontun-wonsi nibi ijosin, ki o ma se ohun ti o koja enu aala Olohun. Ki o ma se ohun ti yoo fi ko iparun ba ara re tabi awon eniyan miran.

    Ki Musulumi ni aniyan wipe oun yoo maa gba aawe lai sinu tabi wipe oun yoo maa fi gbogbo oru ki irun lai sun gbogbo eleyi wa ninu aseju ati ikoja enu aala Olohun ninu esin. Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- si ti so ninu oro re wipe: (Awon alaseju iparun ti ba won o), o wi gbolohun yi ni eemeta. Bakannaa ni Ojise Olohun ko ki Musulumi ni ipinnu pe oun ko ni fe iyawo tabi oun ko ni ni oko leni ti o fi n gbero ijosin fun Olohun; nitoripe gbogbo awon nkan wonyi n se okunfa inira ti o tobi fun eniyan.

    ---------------------------------------

    [1] Ibn Majah: (3029), Silsilatul Ahaadisi Sohiiha: (1283).

    [2] Muslim: (2670).