×
Alaye ranpe nipa gbolohun (as-salaf) pelu die ninu oro awon onimimo.

    ITUMO GBOLOHUN

    "AS-SALAF"

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    معنى كلمة السلف

    « بلغة اليوربا »

    رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    ITUMO GBOLOHUN " AS-SALAF"

    Itumo gbolohun "as-salaf" ninu ede ni eni ti o ba je asiwaju fun eniyan ti o julo pelu ojo ori ati ipo.

    Idi niyi ti o fi je wipe gbogbo itumo ti awon onimimo esin maa n fun gbolohun "as-salaf" ko ye kuro lori awon nkan meta wonyi:

    Alakoko: Awon omoleyin Ojise Olohun (Saabe).

    Eleekeji: Awon omoleyin Ojise Olohun (Saabe) ati awon ti won tele won (Taabiuun).

    Eleeketa: Awon omoleyin Ojise Olohun (Saabe) ati awon ti won tele won (Taabiuun) ati awon ti won tele awon naa, ninu awon asiwaju ninu esin, awon ti o je wipe gbogbo apapo Musulumi ni o gba won gege bii asiwaju, ti won si je awon ti won n tele tira Olohun Al-qur'an ati sunnah Anabi- ki ike ati ola Olohun ki o maa ba a.

    Fun idi eyi, itumo ti awon onimimo fun gbolohun "as-salaf" ni gbogbo awon asiwaju ti won ti re koja lo ninu awon ti won semi ni aarin ogorun odun meteeta akoko leyin iku ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun ki o maa ba a- awon eniyan naa si ni awon omoleyin Ojise Olohun (Saabe) ati awon ti won tele won (Taabiuun), lehinnaa awon ti won tele awon taabiuun. Awon wonyi naa si ni awon ti ojise Olohun so nipa won ninu oro re ti o ti so wipe: "Awon eniyan ti won loore julo ni awon ti won bami lo igba ti o fi de ipari ogorun odun akoko, lehinnaa ni awon ti won tele won, lehinnaa ni awon ti won tun tele won" [1].

    Ninu oro awon onimimo lori itumo "as-salaf":

    (1) Sheikh Ibn Hajar Al-qatary- ki Olohun ke e- so wipe: "Ohun ti a gba lero pelu oju ona awon salaf ni ohun ti awon omoleyin Ojise Olohun (Saabe) wa lori re- ki Olohun ba wa yonu si won, ati awon ti won tele won ni ti ododo titi di ojo ajinde (Taabiuun), ati awon ti won tele awon naa. Bakannaa gbogbo awon asiwaju ninu esin ninu awon ti gbogbo ijo Musulumi jeri si jije asiwaju won gege bii awon imaamu mereerin: Imaam Abu Haniifah, Imaam Maalik, Imaam Shaafihi ati Imaam Ahmad. Ninu won naa ni Sufyaan At-thaoriy ati Laith ibn Saad ati Ibn Mubaarak ati An-nakhakhi ati Bukhari ati Muslim ati beebeelo ninu awon ti won n tele sunna Ojise Olohun. Awon wonyi yato si awon oni adadasile ninu esin ati awon ti won ni alaje ti ko dara gege bii: Khawaarij ati Rawaafidh ati Murji'ah ati Jabriyyah ati Jaamiyyah ati Muutazila" [2].

    (2) Sheikh Mahmoud Khafaaji- ki Olohun ke e- so wipe: "Ki a fi asiko ati igba nikan se amin awon ti a mo si salaf ko to rara, bikosepe leyin ki won je asiwaju ninu igba ati asiko, agbodo se afikun wipe eniti yoo wa ninu awon salaf gbodo je eniti irori re ati isesi re wa ni ibamu pelu ohun ti o wa ninu Al-qur'an ati sunna. Sugbon eni ti irori ati isesi re ba yapa si ohun ti o wa ninu Al-qur'an ati sunna iru eni bee ko si ninu awon salaf, koda ki o gbe laarin awon saabe Ojise Olohun ati awon taabiuun ati awon ti won tele won" [3].

    (3) Al-baajuuri- ki Olohun ke e- so wipe: "Ohun ti a gba lero pelu salaf ni awon eniti won ti siwaju ninu awon Ojise Olohun ati awon omoleyin Anabi (Saabe) ati awon ti won tele won (Taabiuun) ati awon ti won tele awon taabiuun, papaa julo awon Imaam mereerin ti won je olugbiyanju ninu agboye esin Islam: Imaam Abu Haniifah ati Imaam Maalik ati Imaam Shaafihi ati Imaam Ahmad" [4].

    Awon Tira Ti A Se Anfaani Ninu Won:

    [1] Sohih-l-bukhari.

    [2] Al-aqaaidus-salafiyya.

    [3] Al- aqeedatul Islaamiyya baena as-salafiyya wal- muutazila.

    [4] sharhul-jaohara.