×
Ise ijosin eyi ti erusin Olohun yoo maa ni esan lori re naa ni eyi ti o ba je wipe onigbagbo ododo ti o si n tele ilana anabi Muhammad ni o se e, sugbon eyi ti o ba je ti alaigbagbo ofo ati adanu ni yoo je ere re.

    Alaye lori Aayah (23) ninu Suuratu Furkooni

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    تفسير الآية (23) من سورة الفرقان

    « بلغة اليوربا »

    رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    ALAYE LORI AAYAH (23) NINU SUURATU FURKOONI

    Olohun- ti ola Re ga- so wipe: (Dajudaju A o siju wo ohun ti won se ni ise, A o wa so o di eruku ti a ku danu) [Suuratu Furkooni: 23].

    Alaye Lori Aayah Yi:

    Olohun- Oba mimo Oba ti o ga- nso ninu aayah yi nipa awon osebo, awon ti won n da nkan miran po mo Olohun nibi ijosin wipe Oun Olohun yoo mu ise awon osebo naa, awon ise ti won nlero wipe ise daradara ni won, ti won si se wahala lori won, Olohun yoo so ise naa di ohun ti yoo ku danu bii eruku, awon osebo yi yoo wa di eniti won pofo ti won ko si ni esan kankan lori ohun ti won gbe ile aye se.

    Ohun ti yoo se okunfa ki Olohun se ise won bayi ni wipe won ko ni igbagbo si Olohun, won si je eniti won maa npe Olohun ati awon ojise Re ni opuro. Ise ti Olohun yoo maa gba ni odo erusin Re naa ni eyi ti o ba je wipe onigbagbo ododo ni o se e, eniti o gba Olohun ati awon ojise Re ni ododo, ti o ntele won, ti o si nse afomo ise naa fun Olohun Allah nikan.

    Ohun ti Olohun so ninu aayah yi yoo sele ni ojo ajinde nigbati Olohun ba nse isiro ise awon eda Re ti won se ni ile aye, eyi ti o dara ninu awon ise naa ati eyi ti o je aburu. Olohun nso fun awa eru Re ninu aayah yi wipe awon ise ti awon osebo lero wipe awon se ni ile aye ti won si ni agbiyele wipe won yoo gba esan lori won, ti yoo si je ohun ti yoo se okunfa lila kuro ninu iya Olohun fun won, won ko ni ri nkan kan ninu ohun ti won ni agbiyele re, ohun ti o si se okunfa eleyi ni wipe ise won naa ti padanu awon majemu ti o ye ki o wa nibi ise erusin Olohun, awon majemu naa ni ki erusin se afomo ise fun Olohun nikan, ki o fi wa oju rere Re nikan, bakannaa ki ise naa wa ni ibamu bi ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ti se e. Fun idi eyi, gbogbo ise ti ko ba ti ni majemu mejeeji yi ninu ise naa ti baje, ko si si iye meji nibi wipe ise awon osebo ti padanu awon majemu mejeeji, ninu ki o je wipe won ko se e nitori Olohun ati lati fi wa oju rere Re tabi ki o je wipe won ko je ki o wa ni ibamu pelu bi ojise Olohun ti se e tabi ki mejeeji papo si inu ise naa.

    A o se akiyesi pe ninu aayah yi Olohun nfi ise awon osebo we nkan ti o le, ti o si yepere, ti o je wipe ti o ba tuka eniti o ni nkan naa ko ni agbara kan lati ko o jo ti yoo fi se anfaani lati ara re.

    Apejuwe aayah yi ni aayah miran ti Olohun- ti ola Re ga- ti so wipe: (Apeere awon ti won se aigbagbo si Oluwa won {ni pe}: Awon ise won yoo da bii eeru ti ategun lile fe danu ni ojo iji. Won ko ni ni agbara kankan lori ohun ti won se ni ise. Eyi ni isina ti o jinna) [Suuratu Ibraahiima: 18].

    Bakannaa ni oro Olohun ti o so wipe: (Ati awon ti won se aigbagbo, awon ise won da gege bii ahunpeena, ti o wa ni aaye kan ti o teju, ti eniti ohungbe ngbe wa nro pe omi ni titi igbati o de ibe ko wa ba nkankan nibe, {bayi ni ise alaigbagbo yoo se ri, ti o fi je wipe nigbati o ku} o ba Olohun nibe, O si se isiro ise re ni asepe. Olohun yara ni isiro) [Suuratu Nuur: 39].

    Ninu awon anfaani ti a ri ninu aayah yi:

    (1) Ki ise erusin Olohun po pupo ko ni o se pataki, ohun ti o se pataki ni ki ise naa wa ni ibamu pelu sunna ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ki o si je nitori Olohun nikan.

    (2) Gbogbo ise ti alaigbagbo ba se ni ile aye kosi esan kankan lori re nitoripe o ti padanu awon majemu ti o maa nje ki ise di atewogba ni odo Olohun.