Tani o da agbaye? Taa si ni o da mi? Ati pe ki ni idi ti o fi da mi?
Àwọn ìtumọ̀ iṣẹ́ sí èdè mìíràn
- Tiếng Việt - Vietnamese
- ไทย - Thai
- ગુજરાતી - Unnamed
- العربية - Arabic
- অসমীয়া - Assamese
- فارسی دری - Unnamed
- Wikang Tagalog - Tagalog
- English - English
- සිංහල - Sinhala
- Kinyarwanda - Kinyarwanda
- 中文 - Chinese
- Кыргызча - Кyrgyz
- español - Spanish
- Русский - Russian
- azərbaycanca - Azerbaijani
- Shqip - Albanian
- Bahasa Indonesia - Indonesian
- Deutsch - German
- čeština - Czech
- български - Bulgarian
- svenska - Swedish
- हिन्दी - Hindi
- magyar - Hungarian
- বাংলা - Bengali
- فارسی - Persian
- Kurdî - Kurdish
- bosanski - Bosnian
- తెలుగు - Telugu
- اردو - Urdu
- پښتو - Pashto
- Nederlands - Dutch
- português - Portuguese
- Türkçe - Turkish
- Akan - Akan
- ქართული - Georgian
- ພາສາລາວ - Unnamed
- Ўзбек - Uzbek
- മലയാളം - Malayalam
- polski - Polish
- Српски - Serbian
- አማርኛ - Amharic
- Lingala - Unnamed
- தமிழ் - Tamil
Àwọn ìsọ̀rí
Full Description
Tani o da agbaye? Taa si ni o da mi? Ati pe ki ni idi ti o fi da mi?
Njẹ mo wa lori oju ọna ti o tọ̀nà?
Tani o da awọn sanmọ ati ilẹ ati awọn nkan ti o wa nínú mejeeji ninu awọn ẹda ti o tobi ti ìmọ̀ wa o lee gbe gbogbo rẹ tan?
Tani o ṣe eto ti o munadoko yii sinu sanmọ ati ilẹ?
Tani o da ọmọniyan ti o si tun fun un ni ìgbọràn ati irina ati làákàyè ti o si tun ṣe e ni ẹni ti o ni ikapa lati wa awọn imọ ati mímọ awọn ododo?
Tani o ṣe iṣẹ ti o péye dáadáa yii sinu oríkèé ara rẹ, ti o si tun ya aworan rẹ ni aworan ti o daa?
Woye si iṣẹda awọn nkan abẹmi ti o n bẹ ni oríṣiríṣi, taa ni o ṣẹda wọn pẹlu awọn aworan (irisi) ti ko ni aala?
Bawo ni agbaye nla yii ṣe tò ti o si tun fidi mulẹ pẹlu awọn òfin ti o n de e ni dide to péye lati odún gbọọrọ (bi ọdun ṣe n gori ọdun)?
Taa ni o ṣe agbekalẹ awọn eto ti ndari agbaye yii (Iṣẹmi ati ikú, ibisi ati irẹsi awọn alààyè, oru ati ọsan, iyipada awọn igba, ati bẹẹ bẹẹ lọ)?
Njẹ aye yii da ara rẹ bii? Abi o wa lati ibi aisi (Asẹ̀dá)? Abi o kan ṣèèṣì maa bẹ ni? Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:﴿أَمْ خُلِقُوا مِنْ غَيْرِ شَيْءٍ أَمْ هُمُ الْخَالِقُونَ (٣٥) Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni? (35)أَمْ خَلَقُوا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بَلْ لَا يُوقِنُونَ﴾ Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni[At-Tūr: 35-36].
Ti o ba wa jẹ pe awa ko da ara wa ti o si soro ki a wa lati ibi aisi tabi eesi, a jẹ wipe ododo ti ko si iyemeji nibẹ ni pe: Dajudaju agbaye yii ko gbọdọ ma ni Oluda ti O tobi ti O ni ikapa, tori pé o soro ki ayé yii o da ara rẹ! Tabi ki o wa lati ibi aisi! Tabi ki o ṣèèṣì wa!
Nitori ki ni ọmọniyan yio ṣe gbagbọ ninu bibẹ awọn nnkan ti ko ri? Gẹgẹ bii: (Mimọ nnkan, ati laakaye ati ẹmi ati awọn ìmọ̀lára ati ifẹ) ṣe ko ki n ṣe nitori pe o ri àwọn oripa wọn ni? Bawo ni ọmọniyan ṣe maa tako bibẹ Ẹni tí Ó dá ile aye ti o tobi yii, ti o si n ri awọn oripa awọn ẹda Rẹ ati iṣẹ Rẹ ati ikẹ Rẹ?!
Ẹni kan ti o ni laakaye ko lee gba wọle layelaye ki wọn sọ fun un pé: Ile yii ti wa lai ṣe pe ẹnikan ni o mọ ọn! Tabi ki wọn sọ fun un pé: Dajudaju aisi oun ni o mu ile yii maa bẹ! Bawo ni awọn eniyan kan ṣe lee gba pe olododo ni ẹni ti o ba n sọ bayii pe: Dajudaju agbaye ti o tobi yii wa laisi Adẹdaa kan? Bawo ni onilaakaye kan ṣe lee gba ki wọn sọ fun oun pé: Dajudaju wiwa ti agbaye wa pẹlu eto ti o munadoko yii ṣèèṣì ni?
Gbogbo eyi maa mu wa ja si esi kan, oun ni pe, dajudaju Oluwa kan ti O tobi ti O jẹ Olukapa ti O jẹ Oluṣeto kan n bẹ fun agbaye yìí, ati pe Oun nikan ṣoṣo ni Ẹni ti O ni ẹtọ si ijọsin, ati pe dajudaju gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yàtọ̀ si I, ijọsin rẹ jẹ ibajẹ, ko lẹtọọ si ki wọn maa jọsin fun un.
Oluwa Adẹdaa Ọba ti O tobi
Oluwa Adẹdaa Ọkan ṣoṣo kan n bẹ, Oun ni Olukapa Oludari Olupese ti O maa n sọ eniyan di alààyè ti O si maa n sọ eniyan di oku, Oun ni O ṣẹda ilẹ̀ ti O si tẹri rẹ ba, ti O ṣe e ni nnkan ti o daa fun awọn ẹda Rẹ, Oun ni O ṣẹda sanmọ ati nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu awọn ẹda ti wọn tobi, ti O ṣe eto ti o péye yii fun oorun ati òṣùpá ati oru ati ọsan, eyi ti o n tọka si titobi Rẹ.
Oun ni O rọ atẹgun fun wa ti ko si iṣẹmi kan fun wa lai si i, Oun ni O n rọ ojo le wa lori ti O ṣe awọn okun ati awọn odo ni rírọ̀ fun wa, Oun ni O n fun wa ni oúnjẹ ti O si n ṣọ wa nigba ti a si wa ni ọlẹ̀ ninu ikun awọn iya wa laisi agbara kan ti o n bẹ fun wa, Oun ni O n mu ẹjẹ ṣan ninu awọn iṣan wa lati igba ti wọn ti bi wa titi a o fi kú.
Oluwa Adẹdaa Olupese yii ni Allahu- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga-
Allahu - ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿إِنَّ رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَى عَلَى الْعَرْشِ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ يَطْلُبُهُ حَثِيثًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ وَالنُّجُومَ مُسَخَّرَاتٍ بِأَمْرِهِ أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ﴾ {Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá. Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.}[Al-A'raf : 54].
Allahu ni Oluwa Oluda gbogbo nnkan ti o wa ninu agbaye yii ninu nnkan ti a n ri ati ninu nnkan ti a kò ri, ati pe gbogbo nnkan ti o yàtọ̀ si I jẹ ẹda ninu awọn ẹda Rẹ, Oun ni O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo, ati pe a ko gbọdọ jọsin fun nnkan ti o yàtọ̀ si I pẹlu Rẹ, ko si orogun fun Un nibi ijọba Rẹ tabi ṣiṣẹda Rẹ tabi ṣíṣe ètò Rẹ ati ijọsin Rẹ.
Tí a ba gbà pé awọn ọlọhun miiran n bẹ pẹlu Oluwa nínú ẹ, ile aye o ba bajẹ; nitori pe ko lee daa ki ọlọhun meji maa dari àlámọ̀rí ile aye ni asiko kan náà, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:{لَوْ كَانَ فِيهِمَا آلِهَةٌ إِلَّا اللَّهُ لَفَسَدَتَا} (Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ lẹ́yìn Allāhu, sánmọ̀ àti ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́)Al-Anbiya' : 22.
Awọn iroyin Oluwa Adẹdaa
Awọn orukọ ti wọn rẹwa n bẹ fun Oluwa- mimọ ni fun Un- eyi ti ko ṣee ka, awọn iroyin ti wọn ga ti wọn pọ ti wọn tobi n bẹ fun Un eyi ti wọn n da lori pipe Rẹ, ninu awọn orukọ Rẹ ni: Adẹdaa, "Allahu" ìtumọ̀ rẹ ni: Ẹni ti a n sìn ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un. Ọba Alaaye, Alámòjúútó-ẹ̀dá, Aṣakẹ-ọrun, Olupese ati Ọlọrẹ,
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ninu Al-Kuraani Alapọn-ọnle pé:﴿اللَّهُ لا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلا نَوْمٌ لَهُ مَا فِي السَّمَوَاتِ وَمَا فِي الأَرْضِ مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَوَاتِ وَالأَرْضَ وَلا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ﴾ (Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t'ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t'ó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi)[Al-Baqarah : 255].
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- tun sọ pe:﴿قُلْ هُوَ اللَّهُ أَحَدٌ (١) (Sọ pé: "Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo (1)اللَّهُ الصَّمَدُ (٢) Allāhu ni Aṣíwájú (tí ẹ̀dá ní bùkátà sí, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn (2)لَمْ يَلِدْ وَلَمْ يُولَدْ (٣) Kò bímọ. Wọn kò sì bí I (3)وَلَمْ يَكُنْ لَهُ كُفُوًا أَحَدٌ﴾ Kò sì sí ẹnì kan tí ó jọ Ọ́."[Al-Ikhlass 1-4].
Oluwa Ọba ti a n jọsin fun jẹ́ Ẹniti O ni awọn iroyin pipe
Ninu awọn iroyin Rẹ ni pe Oun ni Ẹni ti a n jọsin fun, ati pe nnkan ti o yàtọ̀ si I jẹ nnkan ti a da, ti a la iwọ bọ lọrun, ti a n pa láṣẹ, ti a borí.
Ninu awọn iroyin Rẹ ni pe, dajudaju Ọba Alaaye, Alámòjúútó-ẹ̀dá ni, ati pe gbogbo alaaye ti n bẹ, Allahu ni Ẹni ti O ye wọn ti O si mu wọn bẹ latara aisi, Oun ni O moju to wọn pẹlu bibẹ Rẹ ati ipese Rẹ ati tito Rẹ. Ati pe Oluwa naa jẹ alaaye ti ko nii ku, ti titan si jẹ kò ṣeé ṣe fun Un, Alamojuuto ti ko ki n sun, koda oogbe tabi oorun kan ko lee gba A mu.
Ninu awọn iroyin Rẹ ni pe Oun ni Ọba Onimimọ ti nnkankan ko pamọ fun Un lori ilẹ tabi ninu sanmọ,
Ninu awọn iroyin Rẹ ni pe Oun ni Ọba Olugbọrọ, Oluriran ti O maa n gbọ́ gbogbo nnkan, ti O si maa n ri gbogbo ẹda, O ni imọ nipa gbogbo nnkan ti ẹmi n ṣe royiroyi nipa rẹ ati nnkan ti awọn igbaaya n gbe pamọ, nnkan kan ko pamọ fun Un- mimọ ni fun Un- lori ilẹ tabi ninu sanmọ.
Ninu awọn iroyin Rẹ ni pe Oun ni Olukapa ti nnkan kan ko lee ko agara ba A, ti ẹni kankan ko lee da erongba Rẹ pada, O maa n ṣe nnkan ti o ba wu U ti O si maa n kọdi nnkan ti O ba wu U, O maa n ti siwaju O si maa n ti sẹ́yìn, ati pe ọgbọ́n ti o pe n bẹ fun Un.
Ninu awọn iroyin Rẹ ni pe Oun ni Adẹdaa, Olupese, Oluṣeto ti O da ẹda ti O si ṣètò rẹ, ati pe ẹda n bẹ ninu arọwọto Rẹ ati labẹ ikapa Rẹ.
Ninu awọn iroyin Rẹ ni pe O maa n da ẹni ti ara n ni lohun, O maa n ran ẹni ti wọn bò sí lọwọ, O maa n ṣi ibanujẹ lọ, ati pe ti gbogbo ẹda ba ko sinu ibanujẹ kan tabi ifunpinpin kan wọ́n maa sádi I ni dandan.
Ijọsin ko gbọdọ jẹ ti ẹnikẹni afi ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- Oun ni Ẹni ti O pe ti O lẹtọọ si i ni Òun nìkan ṣoṣo yàtọ̀ si ẹlomiran, ati pe gbogbo nnkan ti wọn bá jọsin fun yàtọ̀ si I jẹ nnkan ti wọn n jọsin fun pẹlu ibajẹ ti o jẹ nkan to dinku ti iku ati titan le ṣẹlẹ̀ si i.
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pese awọn laakaye fun wa ti o le gbọ́ nnkan ye latara titobi Rẹ, O fi adamọ kan ti o nífẹ̀ẹ́ daadaa rinlẹ si wa lara, ti o si korira aburu, ti o si maa n fi ọkan balẹ ti o ba sadi Oluwa gbogbo ẹda, ati pe adamọ yii n tọka lori pipe Rẹ ati pe ko rọrun lati royin Rẹ- mimọ ni fun Un- pẹlu adinku.
Ko tọ fun ẹni ti o ni laakaye lati jọsin fun nnkan kan afi Ẹni ti O pe, bawo ni o ṣe maa jọsin fun ẹda ti kò pe bii rẹ tabi ti o kere si i!
Ẹni ti a maa jọsin fun ko rọrun ki o jẹ abara tabi òrìṣà tabi igi tabi ẹranko!
Oluwa wà loke awọn sanmọ Rẹ, O gunwa sori aga ọla Rẹ, O takete si ẹda Rẹ, ko si nkan kan ninu awọn ẹda Rẹ nínú paapaa Rẹ, ko si si nkan kan ninu paapaa Rẹ lara awọn ẹda Rẹ, ko ki n sọkalẹ, ko si ki n gbe awọ nkan kan wọ ninu awọn ẹda Rẹ.
Oluwa, ko si nnkan kan ti o da bii Rẹ, Oun ni Ọba Olugbọ Oluriran, ko si ẹni kan ti o jọ Ọ, O rọrọ kuro lọdọ ẹda Rẹ, ko ki n sun ko si ki n jẹ oúnjẹ, O tobi ko si rọrun ki iyawo tabi ọmọ wa fun Un; ati pe Ọba Adẹdaa awọn iroyin titobi n bẹ fun Un, ko si rọrun láéláé ki wọn royin Rẹ pẹlu ini bukaata tabi adinku.
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿يَا أَيُّهَا النَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٌ فَاسْتَمِعُوا لَهُ إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ لَنْ يَخْلُقُوا ذُبَابًا وَلَوِ اجْتَمَعُوا لَهُ وَإِنْ يَسْلُبْهُمُ الذُّبَابُ شَيْئًا لَا يَسْتَنْقِذُوهُ مِنْهُ ضَعُفَ الطَّالِبُ وَالْمَطْلُوبُ (٧٣) {Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi àkàwé kan lélẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ́tí sí i. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, wọn kò lè dá eṣinṣin kan, wọn ìbàá para pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tí eṣinṣin bá sì gba kiní kan mọ́ wọn lọ́wọ́, wọn kò lè gbà á padà lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀lẹ ni ẹni tí ń wá n̄ǹkan (lọ́dọ̀ òrìṣà) àti (òrìṣà) tí wọ́n ń wá n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀} (73)مَا قَدَرُوا اللَّهَ حَقَّ قَدْرِهِ إِنَّ اللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ﴾ {Wọn kò bu ọ̀wọ̀ fún Allāhu ní ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí I. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí}[Al-Hajj: 73-74].
Nitori ki ni Adẹdaa ti O tobi yii ṣẹ dá wa? Ati pe ki ni nnkan ti O n fẹ lati ọdọ wa?
Njẹ o ba laakaye mu pe dajudaju Ọlọhun ṣẹda gbogbo awọn ẹda wọnyii laini afojusun, njẹ O ṣẹda wa lásán, Oun si ni Ọba Ọjọgbọn Onimimọ?
Njẹ o ba laakaye mu pe dajudaju Ẹni ti O ṣẹda wa pẹlu eto yii ati idamuṣemuṣe, ti O ṣe nnkan ti o wa ninu sanmọ ati ilẹ ni irọrun fun wa, pé O ṣẹda wa laini afojusun tabi ki O fi wa silẹ laisi idahun si eyi ti o pataki julọ ninu awọn ibeere ti wọn ko airoju ba wa, gẹgẹ bii: Nitori ki ni a ṣe wa nibi? Ati pe ki ni o wa lẹyin iku? Ati pe ki ni afojusun latara ṣiṣẹda wa?
Njẹ o ba laakaye mu ki o ma si ijiya kan fun alabosi, ki o si ma si ẹsan fun oluṣe daadaa?
Ọlọhun- mimọ ni fun Un- sọ pe:﴿أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لَا تُرْجَعُونَ﴾ (Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?)[Al-Mu'minuun: 115].
Bi ko ṣe pe Ọlọhun ran awọn ojiṣẹ ki a le mọ ìdí bibẹ wa, O si tọ wa sọ́nà nipa bi a ṣe ma maa jọsin fun Un ti a si ma maa sunmọ Ọn, ati pe ki ni nnkan ti O fẹ lati ọdọ wa! Bawo ni a ṣe maa ri iyọnu Rẹ, O si sọ fun wa nipa ibupadasi wa lẹyin iku?
Ọlọhun ran awọn ojiṣẹ lati le sọ fun wa pe Oun nikan ṣoṣo ni O lẹtọọ si ijọsin, ki a si le mọ bi a ṣe maa jọsin fun Un, ati ki wọn le mu awọn àṣẹ Rẹ ati awọn ẹkọ Rẹ de etiigbọ wa, ki wọn si le kọ wa ni awọn iwa ọlọla ti o ṣe pe ti a ba gba wọn mu isẹmi aye wa máa daa, yoo si kun fun awọn oore ati alubarika.
Ati pe Ọlọhun ti ran awọn ojiṣẹ ti wọn pọ gẹgẹ bii: (Nuh, Ibrahim, Musa, ati Isa) ti Ọlọhun kun wọn lọwọ pẹlu awọn ami ati awọn iṣẹ iyanu ti wọn tọka lori ododo sisọ wọn ati pe wọn jẹ ìránṣẹ́ lati ọdọ Rẹ- mimọ ni fun Un-, ti ikẹyin wọn jẹ Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.
Awọn ojiṣẹ si ti sọ fun wa ni gbogbo ọna to han dáadáa pe dajudaju isẹmi aye yii jẹ idanwo ati pe dajudaju isẹmi aye tòótọ́ maa waye lẹyin iku
ati pe alujanna n bẹ fun awọn olugbagbọ ti wọn jọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un ti wọn si ni igbagbọ ninu gbogbo awọn ojiṣẹ, ati pe ina kan si n bẹ ti Ọlọhun pese rẹ kalẹ fun awọn alaigbagbọ ti wọn jọsin fun awọn ọlọhun miiran pẹlu Ọlọhun tabi ti wọn ṣaigbagbọ ninu eyikeyii ojiṣẹ kan ninu awọn ojiṣẹ Ọlọhun.
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿يَا بَنِي آدَمَ إِمَّا يَأْتِيَنَّكُمْ رُسُلٌ مِنْكُمْ يَقُصُّونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِي فَمَنِ اتَّقَى وَأَصْلَحَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ (٣٥) (Ọmọ (Ànábì) Ādam, nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ nínú yín bá wá ba yín, tí wọn yóò máa ka àwọn āyah Mi fun yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Mi), tí ó sì ṣàtúnṣe, kò níí sí ìbẹ̀rù kan fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́ (35)وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَاسْتَكْبَرُوا عَنْهَا أُولَئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ﴾ Àwọn t'ó bá sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, tí wọ́n sì ṣègbéraga sí i, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀)[Al-A'raaf 35-36].
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿يَا أَيُّهَا النَّاسُ اعْبُدُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ (٢١) (Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t'ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná)) (21)الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ فِرَاشًا وَالسَّمَاءَ بِنَاءً وَأَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجَ بِهِ مِنَ الثَّمَرَاتِ رِزْقًا لَكُمْ فَلَا تَجْعَلُوا لِلَّهِ أَنْدَادًا وَأَنْتُمْ تَعْلَمُونَ (٢٢) ((Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà, Ó sọ omi òjò kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fun yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́)) (22)وَإِنْ كُنْتُمْ فِي رَيْبٍ مِمَّا نَزَّلْنَا عَلَى عَبْدِنَا فَأْتُوا بِسُورَةٍ مِنْ مِثْلِهِ وَادْعُوا شُهَدَاءَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ (٢٣) (Tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa, nítorí náà, ẹ mú sūrah kan wá bí irú rẹ̀, kí ẹ sì pe àwọn ẹlẹ́rìí yín, yàtọ̀ sí Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo) (23)فَإِنْ لَمْ تَفْعَلُوا وَلَنْ تَفْعَلُوا فَاتَّقُوا النَّارَ الَّتِي وَقُودُهَا النَّاسُ وَالْحِجَارَةُ أُعِدَّتْ لِلْكَافِرِينَ (٢٤) (Tí ẹ ò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ò wulẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà ẹ ṣọ́ra fún Iná, èyí tí ìkoná rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn àti òkúta tí Wọ́n pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́) (24)وَبَشِّرِ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أَنَّ لَهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ كُلَّمَا رُزِقُوا مِنْهَا مِنْ ثَمَرَةٍ رِزْقًا قَالُوا هَذَا الَّذِي رُزِقْنَا مِنْ قَبْلُ وَأُتُوا بِهِ مُتَشَابِهًا وَلَهُمْ فِيهَا أَزْوَاجٌ مُطَهَّرَةٌ وَهُمْ فِيهَا خَالِدُونَ﴾ (Fún àwọn t'ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé, dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan ń bẹ fún wọn, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Nígbàkígbà tí A bá p'èsè jíjẹ-mímu kan fún wọn nínú èso rẹ̀, wọn yóò sọ pé: "Èyí ni wọ́n ti pèsè fún wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." – Wọ́n mú un wá fún wọn ní ìrísí kan náà ni (àmọ́ pẹ̀lú adùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). – Àwọn ìyàwó mímọ́ sì ń bẹ fún wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀)(Al-Baqarah: 21-25).
Nitori ki ni awọn ojiṣẹ ṣe pọ?
Dajudaju Ọlọhun ran awọn ojiṣẹ Rẹ si awọn ijọ, ko si ninu ìjọ kan afi ki Ọlọhun ran ojiṣẹ kan si wọn, lati pe wọn lọ sibi ijọsin fun Oluwa wọn, ki o si mu awọn àṣẹ Rẹ ati awọn ẹkọ Rẹ de etiigbọ wọn, ati pe afojusun ipepe gbogbo wọn patapata jẹ: Ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo- Alagbara ti O gbọnngbọn, Gbogbo igba ti ìjọ kan ba ti bẹ̀rẹ̀ si nii gbe nnkan ti ojiṣẹ rẹ mu wa jusilẹ tabi da a rú, ninu àṣẹ mimu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo, Ọlọhun maa gbe iṣẹ naa fun ojiṣẹ miiran lati tun oju ọna naa ṣe, ti o si maa mu awọn eniyan pada si adamọ ti o ni àlàáfíà pẹlu imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo ati itẹle Rẹ,
Titi ti Ọlọhun fi pari awọn ojiṣẹ pẹlu Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a-, ẹniti o mu ẹsin ti o pe wa ati ofin gbere ti o kari gbogbo ẹda titi di ọjọ igbende, eyi ti o wa pari, ti o si jẹ nnkan ti o wa pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ̀ rẹ́ ninu awọn ofin, ati pe Olúwa si fi ọwọ sọya fun ẹsin yii lati maa ṣẹku titi di Ọjọ́ Àjíǹde.
Eniyan ko lee di olugbagbọ titi yoo fi ní igbagbọ ninu gbogbo awọn ojiṣẹ
Ọlọhun ni O ran awọn ojiṣẹ, ti O si pa gbogbo ẹda Rẹ láṣẹ pẹlu itẹle wọn, ẹni ti o ba ṣe aigbagbọ ninu ìránṣẹ́ ọkan ninu wọn dajudaju o ti ṣe aigbagbọ ninu gbogbo wọn, ati pe ko si ẹṣẹ kan ti o tobi ju ki ọmọniyan da imisi Ọlọhun pada sọ́dọ̀ Rẹ, ko si ibuyẹ fun wiwọ alujanna laisi nini igbagbọ ninu gbogbo awọn ojiṣẹ.
Nitori naa nkan ti o jẹ dandan lori ẹnikọọkan ni asiko yii ni ki o ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun ati gbogbo awọn ojiṣẹ Rẹ, ki o si tun gba ọjọ ikẹhin gbọ, ìyẹn o wàá níí ṣẹlẹ ayaafi pẹlu ki o gbagbọ ki o si tẹle igbẹyin wọn (awọn ojiṣẹ) ati opin wọn tii ṣe Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ẹni ti a kun lọwọ pẹlu ami ìyanu láéláé, oun naa ni Kuraani Alapọn-ọnle, èyí ti Ọlọhun nṣọ ọ titi di ìgbà tí yoo jogun ilẹ ati gbogbo nkan ti o wa l'ori rẹ.
Ọlọhun sọ ninu Kuraani Alapọn-ọnle pe dajudaju ẹni ti o ba kọ nini igbagbọ sí ojiṣẹ kan ninu awọn ojiṣẹ Rẹ, o ti ṣe keferi si Ọlọhun o si ti pe imisi Rẹ ni irọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:﴿إِنَّ الَّذِينَ يَكْفُرُونَ بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ وَيُرِيدُونَ أَنْ يُفَرِّقُوا بَيْنَ اللَّهِ وَرُسُلِهِ وَيَقُولُونَ نُؤْمِنُ بِبَعْضٍ وَنَكْفُرُ بِبَعْضٍ وَيُرِيدُونَ أَنْ يَتَّخِذُوا بَيْنَ ذَلِكَ سَبِيلًا (١٥٠) {Dájúdájú àwọn t'ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n fẹ́ ṣòpínyà láààrin Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń wí pé: "A gbàgbọ́ nínú apá kan, a sì ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan," wọ́n sì fẹ́ mú ọ̀nà kan tọ̀ (lẹ́sìn) láààrin ìyẹn (150)أُولَئِكَ هُمُ الْكَافِرُونَ حَقًّا وَأَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا مُهِينًا﴾ {Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́. A sì ti pèsè Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́}[An-Nisā': 150-151].
Nitori naa awa musulumi ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun ati ọjọ ikẹyin – gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun ṣe pàṣẹ - a sì tun ni igbagbọ si gbogbo ojiṣẹ ati awọn iwe ti o ṣaaju, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:﴿آمَنَ الرَّسُولُ بِمَا أُنْزِلَ إِلَيْهِ مِنْ رَبِّهِ وَالْمُؤْمِنُونَ كُلٌّ آمَنَ بِاللَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْ رُسُلِهِ وَقَالُوا سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا غُفْرَانَكَ رَبَّنَا وَإِلَيْكَ الْمَصِيرُ﴾ {Òjíṣẹ́ náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: "A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá."}[Al-Baqorah: 285].
Ki ni Kuraani Alapọn-ọnle?
Kuraani Alapọn-ọnle ni ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ati imisi Rẹ ti O sọkalẹ fun igbẹyin awọn ojiṣẹ tii ṣe Muhammad, oun si ni ami iyanu ti o tobi julọ ti n tọka si ododo ijẹ anabi rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe Kuraani Alapọn-ọnle ododo ni nibi awọn idajọ rẹ, ootọ sì ni nibi awọn irọyin rẹ,Ati pe Ọlọhun ti pe awọn ti wọn pe e nirọ n'ija pẹlu pe ki wọn o mu iru rẹ wa koda bo ṣe suurah kan ti o jọ ọ, ti wọn si kagara lati ṣe iyẹn; latari titobi akosinu rẹ ati kikari ọrọ inu rẹ fun gbogbo nkan ti o nii ṣe pẹlu ọmọniyan ninu iṣẹmi aye ati ọjọ ikẹyin, ati pe o ko sinu gbogbo awọn pàápàá igbagbọ ti nini igbagbọ ninu rẹ jẹ dandan,Gẹ́gẹ́ bí o ṣe ko sinu awọn aṣẹ ati awọn eewọ ti o jẹ dandan ki ọmọniyan o maa rin lori rẹ nibi nkan ti o wa laarin rẹ ati Oluwa rẹ tabi laarin rẹ ati ara rẹ, tabi laarin rẹ ati gbogbo ẹda, ti gbogbo rẹ wa pẹlu ìlànà ti o ga nibi didantọ ati alaye lẹkunrẹrẹ,Dajudaju o ko eyi to pọ sinu ninu awọn ẹri ti laakaye ati awọn ododo ti imọ ti wọn tọka lori pe dajudaju iwe yii ko ṣeeṣe ki o jẹ lati iṣẹ ọwọ ẹda bi ko ṣe pe ọrọ Oluwa ẹda- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga- ni.
Ki ni ẹsin Isilaamu?
Isilaamu ni jijupa-jusẹ silẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu imu U ni Ọkan ṣoṣo, ati gbigba fun Un pẹlu itẹle, ati titẹle ofin Rẹ pẹlu iyọnu ati gbigba wọle, ati ṣíṣe aigbagbọ sí gbogbo nnkan ti wọn jọsin fun yàtọ̀ si Ọlọhun.
Dajudaju Ọlọhun gbe awọn ojiṣẹ dide pẹlu iṣẹ-ìránṣẹ́ kan oun ni: Ipepe lọ sibi ijọsin fun Ọlọhun ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati ṣíṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn jọsin fun yàtọ̀ si Ọlọhun.
Isilaamu ni ẹsin gbogbo awọn Anabi, ati pe ipepe wọn ọkan ṣoṣo ni ti awọn ofin wọn jẹ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ati pe ni oni, awọn mùsùlùmí nikan ṣoṣo ni wọn n gba ẹsin ti o ni alaafia mu, eyi ti gbogbo awọn Anabi mu wa, ati pe iṣẹ-ìránṣẹ́ Isilaamu ni asiko yii jẹ ododo, oun si ni iṣẹ-ìránṣẹ́ ipari lati ọdọ Ọba Adẹdaa fun gbogbo ẹda eniyan,Oluwa ti O ran Ibrahim ati Musa ati 'Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba wọn- niṣẹ, Oun naa ni O ran ipari awọn ojiṣẹ Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju ofin sharia Isilaamu wa lati pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ ninu awọn ofin rẹ.
Dajudaju gbogbo ẹsin ti awọn eniyan fi n jọsin lonii- yàtọ̀ si Isilaamu- jẹ awọn ẹsin latara iṣẹ ọwọ ẹda, tabi awọn ẹsin ti wọn ti fi igba kan jẹ ẹsin ti Ọlọhun lẹyin naa ni ọwọ ẹda ti fi wọn ṣeré, ti wọn ti pada di adapọ ìtòjọpelemọ ìtàn àròsọ ati awọn àlọ́ ti wọn jogún, ati awọn igbiyanju ẹ̀dá.
Ṣugbọn ẹsin awọn Mùsùlùmí ni ẹsin kan ti o han ti ko lee yipada, bi o ti jẹ pe dajudaju awọn ijọsin wọn ti wọn fi n jọsin fun Ọlọhun jẹ ọkan, gbogbo wọn ni wọ́n ń ki irun wákàtí márùn-ún, ti wọn n yọ saka awọn dukia wọn, ti wọn n gba awẹ oṣu Ramadan, ronu si iwe òfin wọn tii ṣe Kuraani Alapọn-ọnle, ó jẹ iwe kan ni gbogbo awọn ilu. Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:﴿ٱلۡيَوۡمَ أَكۡمَلۡتُ لَكُمۡ دِينَكُمۡ وَأَتۡمَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ نِعۡمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ ٱلۡإِسۡلَٰمَ دِينٗاۚ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ فِي مَخۡمَصَةٍ غَيۡرَ مُتَجَانِفٖ لِّإِثۡمٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ﴾ (Mo parí ẹ̀sìn yín fun yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fun yín. Mo sì yọ́nú sí 'Islām ní ẹ̀sìn fun yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá kó sínú ìnira ebi (láti jẹ ẹran èèwọ̀), yàtọ̀ sí olùfínnúfíndọ̀-dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run)[Al-Ma'idah: 3].
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ninu Kuraani pe:﴿قُلْ آمَنَّا بِاللَّهِ وَمَا أُنْزِلَ عَلَيْنَا وَمَا أُنْزِلَ عَلَى إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطِ وَمَا أُوتِيَ مُوسَى وَعِيسَى وَالنَّبِيُّونَ مِنْ رَبِّهِمْ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْهُمْ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ (٨٤) (Sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa pẹ̀lú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, 'Ismọ̄'īl, 'Ishāƙ, Ya'ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti 'Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un) (84)وَمَنْ يَبْتَغِ غَيْرَ الْإِسْلَامِ دِينًا فَلَنْ يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ﴾ (Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí 'Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò)(Aal-E-Imran: 84-85).
Ẹsin Isilaamu ni ọ̀nà ti o gbòòrò fun isẹmi ayé, ti o ba adamọ ati laakaye mu, ti awọn ẹmi ti wọn ṣe deedee naa gba a wọle, ti Ọba Adẹdaa ti O tobi ṣe e lofin fun ẹda, oun ni ẹsin daadaa ati oriire fun awọn eniyan lapapọ ni aye ati ọrun, ti ko ṣe ìyàtọ̀ laaarin ẹ̀yà kan si ẹ̀yà kan, tabi awọ kan si awọ kan, awọn eniyan ri bákan náà nibẹ, ẹnikẹni ko yàtọ̀ ninu Isilaamu si ẹlòmíì afi pẹlu ìdiwọ̀n iṣẹ ire rẹ.
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:(مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَنُحۡيِيَنَّهُۥ حَيَوٰةٗ طَيِّبَةٗۖ وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ) (Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé t'ó dára. Dájúdájú A ó sì fi èyí t'ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn)[An-Nahl: 97]
Isilaamu ni oju ọna oriire
Isilaamu ni ẹsin gbogbo awọn Anabi, oun ni ẹsin Ọlọhun fun gbogbo àwọn ènìyàn, ko kii ṣe ẹsin Larubawa nikan.
Isilaamu ni oju ọna oriire tòótọ́ ni aye ati idẹra gbere ni ọrun.
Isilaamu ni ẹsin kan ṣoṣo ti o maa n dahun fun awọn bukaata ẹmi ati ara, ti o si maa n yanjú gbogbo awọn ìṣòro ọmọniyan, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿قَالَ اهْبِطَا مِنْهَا جَمِيعًا بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُمْ مِنِّي هُدًى فَمَنِ اتَّبَعَ هُدَايَ فَلا يَضِلُّ وَلا يَشْقَى (123) ((Allāhu) sọ pé: "Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ pátápátá. Apá kan yín sì jẹ́ ọ̀tá sí apá kan - ẹ̀yin àti Èṣù. Nígbà tí ìmọ̀nà bá sì dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, kò níí ṣìnà, kò sì níí dààmú) (123)وَمَنْ أَعْرَضَ عَنْ ذِكْرِي فَإِنَّ لَهُ مَعِيشَةً ضَنْكًا وَنَحْشُرُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَعْمَى﴾ (Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣẹ́rí kúrò níbi ìrántí Mi, dájúdájú ìṣẹ̀mí ìnira máa wà fún un nílé ayé. A sì máa gbé e dìde ní afọ́jú ní Ọjọ́ Àjíǹde)[Ta-Ha: 123-124].
Ki ni nnkan ti maa ṣe anfaani rẹ latara wiwọ inu Isilaamu?
Wiwọ inu Isilaamu, awọn anfaani ti wọn tobi ni wọn n bẹ fun un, ninu wọn ni:
Erenjẹ ati iyi ni aye pẹlu pe ki ọmọniyan jẹ ẹru Ọlọhun, ti ko ba ri bẹ́ẹ̀ ni, o maa jẹ ẹru fun ifẹ inu ati èṣù ati awọn adun.
Erenjẹ ni ọrun pẹlu pe ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un, ki iyọnu Rẹ si sọkalẹ le e lori, ki Ọlọhun si mu u wọnu alujanna, ki o si jere pẹlu iyọnu ati idẹra gbere, ki ọmọniyan si la kuro nibi iya iná.
Dajudaju olugbagbọ maa wa pẹlu awọn Anabi ni ọjọ igbende ati pẹlu awọn olododo ati awọn ti wọn ku iku ṣẹhidi ati awọn ẹni rere, ki ni o dun to o ninu alabawapọ, ẹni ti ko ba ni igbagbọ yoo wa pẹlu awọn òrìṣà ati awọn ẹni buruku ati awọn ọdaran ati awọn ọbayejẹ.
Awọn ti Ọlọhun ba mu wọ inu alujanna, wọn ma maa ṣẹmi ninu idẹra gbere laisi iku tabi aarẹ tabi inira ati ogbo tabi ibanujẹ, O si ma maa da wọn lohun gbogbo nnkan ti wọn ba fẹ, ati pe awọn ti wọn ba wọ ina, wọn ma maa wa ninu iya gbere laini dawọ dúró.
O n bẹ ninu alujanna awọn igbadun kan ti oju kan ko ri rí, ti eti kan ko gbọ́ ri, ti ko rú wúyẹ́ ninu ọkan èyíkéyìí ọmọniyan kan ri. Ninu awọn ẹri ìyẹn ni ọrọ Rẹ- ti ọla Rẹ ga- pé:﴿مَنْ عَمِلَ صَالِحًا مِنْ ذَكَرٍ أَوْ أُنْثَى وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَنُحْيِيَنَّهُ حَيَاةً طَيِّبَةً وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَجْرَهُمْ بِأَحْسَنِ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ﴾ (Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé t'ó dára. Dájúdájú A ó sì fi èyí t'ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn)[An-Nahl, Ayah 97].Ọba ti ọla Rẹ ga tun sọ pe:﴿فَلَا تَعۡلَمُ نَفۡسٞ مَّآ أُخۡفِيَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعۡيُنٖ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ﴾ (Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere))[Suurat As-Sajdah: 17]
Ki ni nnkan ti mo maa padanu ti mo ba kọ lati gba Isilaamu?
Ọmọniyan maa padanu eyi ti o tobi julọ ninu imọ ati amọdaju, oun ni amọdaju ati imọ nipa Ọlọhun, yio si padanu ini igbagbọ ninu Ọlọhun ti o maa n fi ifọkanbalẹ tọrẹ fun ọmọniyan ati ifayabalẹ ni aye ati idẹra gbere ni ọrun.
Ọmọniyan maa padanu riri eyi ti o tobi julọ ninu iwe ti Ọlọhun sọ ọ kalẹ fun awọn eniyan, ati ini igbagbọ ninu iwe ti o tobi naa.
O maa padanu ini igbagbọ ninu awọn Anabi ti wọn tobi gẹgẹ bi o ṣe maa padanu iwa pẹlu wọn ninu alujanna ni ọjọ igbende, o maa wa pẹlu awọn èṣù ati awọn ọdaran ati awọn òrìṣà ninu ina jahanamọ, o ma buru ni ilé ati imuleti.
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿قُلْ إِنَّ الْخَاسِرِينَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ وَأَهْلِيهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَلا ذَلِكَ هُوَ الْخُسْرَانُ الْمُبِينُ (15) (" Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn t'ó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ará ilé wọn lófò ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́! Ìyẹn, òhun ni òfò pọ́nńbélé) (15)لَهُمْ مِنْ فَوْقِهِمْ ظُلَلٌ مِنَ النَّارِ وَمِنْ تَحْتِهِمْ ظُلَلٌ ذَلِكَ يُخَوِّفُ اللَّهُ بِهِ عِبَادَهُ يَا عِبَادِ فَاتَّقُونِ﴾ (Àwọn àjà Iná máa wà ní òkè wọn. Àwọn àjà yó sì wà ní ìsàlẹ̀ wọn. Ìyẹn ni Allāhu fi ń dẹ́rù ba àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ (báyìí pé:) "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, ẹ bẹ̀rù Mi)[Az-Zumar: Ayah 15-16].
Ẹni ti o ba fẹ là ni ọrun, o jẹ dandan fun un lati wọnu Isilaamu ki o si tẹle Anabi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
Ninu awọn ododo ti gbogbo awọn anabi ati ojiṣẹ panu pọ lori rẹ ni pe ko si ẹni ti yio la ni ọjọ ikẹyin ayaafi awọn musulumi ti wọn gba Ọlọhun gbọ - Ọba ti O ga - ti wọn ò si mu ẹnikẹni mọ Ọn ni orogun nibi ijọsin Rẹ, ti wọn si tun gba gbogbo awọn anabi ati ojiṣẹ gbọ, nitori naa gbogbo awọn olutẹle awọn ojiṣẹ awọn ti wọn gba wọn gbọ ti wọn si gba wọn lododo, wọn o wọ alujanna, wọn o si la kuro nibi ina.
Awọn ti wọn wa ni igba anabi Mūsa ti wọn si gba a gbọ ti wọn si tẹle awọn ofin rẹ, awọn eleyii musulumi ni wọn, onigbagbọ ododo eniire ni wọn, ṣugbọn lẹyin ti Ọlọhun gbe Ēsa dìde, o jẹ dandan fun awọn olutẹle Mūsa ki wọn o gba Ēsa gbọ ki wọn si tẹle enitori naa awọn ti wọn gba Ēsa gbọ awọn wọnyi ni musulumi eniire, ati pẹ ẹni ti o ba ko lati gba Ēsa gbọ ti o wa sọ pe maa wa lori ẹsin Mūsa ẹni bẹ́ẹ̀ o kii ṣe mumini; nítorí pé o ti kọ lati ni igbagbọ ninu ojiṣẹ kan ti Ọlọhun ran an niṣẹ,Lẹyin naa lẹyin ìgbà tí Ọlọhun gbe igbẹyin awọn ojiṣẹ dide tii ṣe Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gbogbo èèyàn ló gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ati pe Ọlọhun ti O ran Mūsa ati Ēsa, Òun náà ni O ran igbẹyin awọn ojiṣẹ tii ṣe Muhammad, nitori naa ẹni ti o ba ṣe aigbagbọ si ijẹ ojiṣẹ Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o wa sọ pe maa wa lori titẹle Mūsa tabi Ēsa, ẹni bẹ́ẹ̀ Kii ṣe olugbagbọ.
Ati pe ko lee to ki ọmọniyan o sọ pe dajudaju oun n ṣe apọnle awọn musulumi, ko si tun lee to fun un lati la ni ọjọ ikẹyin ki o maa ṣe saara ati ki o maa ran awọn alaini lọwọ, bi ko ṣe pe o gbọdọ jẹ ẹni ti yio ni igbagbọ si Ọlọhun ati awọn tira Rẹ ati awọn ojiṣẹ Rẹ ati ọjọ ikẹhin; ki Ọlọhun le baa tẹwọ gba ìyẹn lọwọ rẹ! Ati pe ko si ẹṣẹ ti o tobi ju mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe aigbagbọ pẹlu Ọlọhun ati dida imisi ti Ọlọhun sọkalẹ pada tàbí titako jijẹ anabi igbẹyin awọn anabi tii ṣe Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lọ.
Nitori naa awọn Yahudi ati Nasara ati awọn to yatọ si wọn, wọ́n gbọ́ nipa igbedide Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti wọn si kọ lati gba a gbọ ti wọn si tun kọ lati wọ inu ẹsin Isilaamu, wọn yio maa bẹ ni inu ina Jahannama ti wọn yio ṣe gbere nibẹ, ati pe eleyii ni idajọ Ọlọhun ko si kii ṣe idajọ ẹda eniyan kankan, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:﴿إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ وَالْمُشْرِكِينَ فِي نَارِ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ أُولَـٰئِكَ هُمْ شَرُّ الْبَرِيَّة﴾ {Dájúdájú àwọn t'ó ṣàì gbàgbọ́ (wọ̀nyí) nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá t'ó burú jùlọ.}[Al-Bayyinah: 6].
Níwọ̀n ìgbà tí iṣẹ ti o gbẹyin ti sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun si awọn ẹda, nitori naa o jẹ dandan fun gbogbo eeyan ti o ba gbọ nipa Isilaamu ti o si tun gbọ nipa isẹ anabi igbẹyin tii ṣe Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ki o gba a gbọ ki o si tun tẹle ofin rẹ ki o si tun tẹle e nibi aṣẹ rẹ ati kikọ rẹ, tori naa ẹni ti o ba gbọ nipa iṣẹ igbẹyin yii ti o wa kọ ọ, Ọlọhun o nii gba nkankan ni ọwọ rẹ, yio si tun fi iya jẹ ẹ ni ọjọ ikẹyin.
Ninu awọn ẹri ìyẹn ni ọrọ Rẹ- ti ọla Rẹ ga- pe:﴿وَمَنْ يَبْتَغِ غَيْرَ الْإِسْلَامِ دِينًا فَلَنْ يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ﴾ (Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí 'Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò)[Aal-E-Imran, Ayah 85].
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:﴿قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ تَعَالَوْا إِلَى كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ أَلَّا نَعْبُدَ إِلَّا اللَّهَ وَلَا نُشْرِكَ بِهِ شَيْئًا وَلَا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ﴾ (Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlu-l-kitāb, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan t'ó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu." Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: "Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa)[Aal-E-Imran: 64].
Ki ni nnkan ti o jẹ dandan fun mi lati jẹ ki n di Musulumi?
Lati wọnu Isilaamu, ini igbagbọ ninu awọn origun mẹfa yii jẹ dandan:
Ini igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati pe Oun ni Adẹdaa Olupese Oluṣeto Olukapa, ko si nnkan kan ti o da bii Rẹ, ko si iyawo tabi ọmọ fun Un, ati pe Oun nikan ṣoṣo ni O lẹtọọ si ijọsin, wọn ko gbọdọ jọsin fun ẹni ti o yàtọ̀ si I pẹlu Rẹ, ati lati ni adisọkan pe dajudaju ijọsin fun gbogbo nnkan ti wọn jọsin fun yàtọ̀ si I jẹ ijọsin ti ibajẹ.
Ini igbagbọ ninu awọn mọlaika pe dajudaju ẹru Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni wọn, O ṣẹda wọn latara imọlẹ, O si fi sinu iṣẹ wọn pe ki wọn maa sọkalẹ pẹlu imisi fun awọn Anabi Rẹ.
Ini igbagbọ ninu gbogbo awọn iwe ti Ọlọhun sọ wọn kalẹ fun awọn Anabi Rẹ (gẹgẹ bii Taorah ati Injil- ṣíwájú ìyípadà wọn-) ati pe igbẹyin awọn iwe naa ni Kuraani Alapọn-ọnle.
Ini igbagbọ ninu gbogbo awọn ojiṣẹ gẹgẹ bii Nuh ati Ibrahim ati Musa ati Isa ati pe igbẹyin wọn ni Muhammad, ẹda eniyan ni gbogbo wọn, O kun wọn lọwọ pẹlu imisi O si fun wọn ni awọn ami ati awọn iṣẹ iyanu ti wọn n tọka si sisọ ododo wọn.
Ini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin nígbà tí Ọlọhun maa gbe awọn ẹni akọkọ ati awọn ẹni ìkẹyìn dide, ti Ọlọhun maa ṣe idajọ laaarin awọn ẹda Rẹ, ti O maa mu awọn olugbagbọ wọ alujanna ati awọn alaigbagbọ wọ ina.
Ini igbagbọ ninu kadara ati pe dajudaju Ọlọhun mọ gbogbo nnkan ninu nnkan ti o wa ni asiko ti o ti lọ ati nnkan ti o maa wa ni ọjọ iwaju, ati pe dajudaju Ọlọhun ti ní imọ O si ti kọ ìyẹn O si fẹ ẹ O si da gbogbo nnkan.
Ma ṣe lọ ipinnu rẹ lára!
Ile aye ko kii ṣe ile gbere...
Ati pe gbogbo nnkan ti o rẹwa maa to pamọ, gbogbo adun maa to tán....
Ti ọjọ ti wọn maa ṣe ìṣirò iṣẹ ọmọniyan lori gbogbo nnkan ti o ti tì ṣíwájú maa de, oun ni ọjọ igbende, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pé:﴿وَوُضِعَ الْكِتَابُ فَتَرَى الْمُجْرِمِينَ مُشْفِقِينَ مِمَّا فِيهِ وَيَقُولُونَ يَا وَيْلَتَنَا مَالِ هَذَا الْكِتَابِ لاَ يُغَادِرُ صَغِيرَةً وَلاَ كَبِيرَةً إِلاَّ أَحْصَاهَا وَوَجَدُوا مَا عَمِلُوا حَاضِرًا وَلاَ يَظْلِمُ رَبُّكَ أَحَدًا﴾ (A máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá kalẹ̀ (fún wọn). Nígbà náà, o máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn yóò máa bẹ̀rù nípa ohun tí ń bẹ nínú ìwé iṣẹ́ wọn. Wọn yóò wí pé: "Ègbé wa! Irú ìwé wo ni èyí ná; kò fi ohun kékeré àti ńlá kan sílẹ̀ láì kọ ọ́ sílẹ̀?" Wọ́n sì bá ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ níbẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣàbòsí sí ẹnì kan)[Al-Kahf: 49].
Dajudaju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ti sọ pe dajudaju eniyan ti kò ba gba Isilaamu, ibupadasi rẹ ni gbere ni inu ina jahanamọ titi laelae.
Ofo ko rọrun bi ko ṣe pe o tobi, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pé:﴿وَمَن يَبْتَغِ غَيْرَ الْإِسْلَامِ دِينًا فَلَن يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ﴾ (Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí 'Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò)[Aal-E-Imran: 85].
Isilaamu ni ẹsin ti Ọlọhun ko nii gba òmíràn yàtọ̀ si i ninu awọn ẹsin.
Ọlọhun ni O ṣẹda wa, ọdọ Rẹ naa ni a o ṣẹri pada si, ati pe ile aye yìí jẹ idanwo fun wa.
Ki ọmọniyan lọ mọ amọdaju pe: Dajudaju iṣemi yii kuru gẹgẹ bii àlá... Ati pe ẹnikẹni ko nimọ nipa igba ti o maa ku!
Ki ni o maa jẹ idahun rẹ fun Aṣẹda rẹ ti O ba bi i leere ni ọjọ igbende pé: Nitori ki ni ko ṣe tẹle ododo? Nitori ki ni ko ṣe tẹle ìkẹyìn awọn Anabi?
Pẹlu nnkan wo ni yoo fi da Oluwa rẹ lohun ni ọjọ igbende, ti O si ti ṣekilọ kuro nibi awọn abajade aigbagbọ pẹlu Isilaamu, O si sọ pe ibupadasi awọn alaigbagbọ ni ìparun sinu ina titi laelae?
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:﴿وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ﴾ (Àwọn t'ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀)[Al-Baqarah, Ayah 39].
Ko si awawi fun ẹni ti o ba gbe òtítọ́ silẹ ti o wa wo awokọse awọn baba ati awọn baba baba
Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ fun wa pe ọpọlọpọ ninu awọn eniyan, wọn kọ wiwọnu Isilaamu silẹ latara ipaya agbegbe ti wọn n ṣẹmi nibẹ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn si kọ Isilaamu nitori àìní ìfẹ́ si yiyi awọn adisọkan wọn pada, eyi ti wọn jogun rẹ lọdọ awọn baba wọn tabi ti wọn gba a latara awọn agbegbe wọn ati awọn àwùjọ wọn, ti wọn ti wa ba a saaba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu wọn ni ìgbónára fun irọ ti wọn jogún rẹ n kọdi wọn lati gba Isilaamu.
Gbogbo awọn wọnyi pata ko si awawi fun wọn nibi ìyẹn, wọn si maa duro si waju Ọlọhun laini awijare.
Ko kii ṣe awawi fun alainigbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun lati sọ pe maa wa lori ainigbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun nitori pe wọn bi mi sinu idile alainigbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun! Bi ko ṣe pe o jẹ dandan fun un lati ṣamulo laakaye ti Ọlọhun bun un, ki o si woye si titobi awọn sanmọ ati ilẹ, ki o si ronu pẹlu laakaye rẹ ti Aṣẹda rẹ bun un lati le mọ pe dajudaju Aṣẹda kan n bẹ fun ile aye yii,Gẹgẹ bẹ́ẹ̀ naa ni ẹni ti o ba n jọsin fun awọn okuta ati awọn òrìṣà, ko si awawi fun un nibi ikọṣe awọn baba rẹ, bi ko ṣe pe o jẹ dandan fun un lati ṣewadii nipa ododo ki o si bi ara rẹ leere pe: Bawo ni maa ṣe maa jọsin fun nnkan ọbọrọgidi ti ko gbọ mi, ti ko si ri mi, ti ko ṣe mi ni anfaani pẹlu nnkan kan?!
Gẹgẹ bẹ́ẹ̀ naa ni Nasara ti o ni igbagbọ ninu awọn alamọri ti wọn tako adamọ ati laakaye, o jẹ dandan fun un lati bi ara rẹ leere pe: Bawo ni o ṣe rọrun fun oluwa lati pa ọmọ rẹ ti ko da ẹṣẹ kan kan nitori ẹṣẹ awọn eniyan mìíràn?! Eleyii wa ninu abosi! Bawo ni o ṣe rọrun fun awọn eniyan kan lati kan ọmọ olúwa mọ agbelebuu ati lati pa a?! Njẹ Olúwa ko ni ikapa lati fori jin awọn ẹṣẹ awọn ẹda lai fun wọn ni iyọnda pipa ọmọ rẹ?! Njẹ Olúwa ko ni ikapa lati gbeja ọmọ rẹ ni?
Nnkan ti o jẹ dandan fun onilaakaye ni lati tẹle ododo, ki o si ma kọṣe awọn baba ati awọn baba baba lori ibajẹ.
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا إِلَى مَا أَنْزَلَ اللَّهُ وَإِلَى الرَّسُولِ قَالُوا حَسْبُنَا مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ شَيْئًا وَلَا يَهْتَدُونَ﴾ (Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: "Ẹ máa bọ̀ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. (Ẹ máa bọ̀ wá) sí ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ náà." Wọ́n á wí pé: "Ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ti tó wa." Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò nímọ̀ kan kan, tí wọn kò sì mọ̀nà?)[Al-Ma'idah, Ayah 104].
Ki ni nnkan ti ẹni ti o ba fẹ gba Isilaamu maa ṣe, ti o si n bẹru fun ẹmi rẹ kuro nibi awọn ṣuta awọn mọlẹbi rẹ?
Ẹni ti o ba fẹ gba Isilaamu ti o si n paya agbegbe ti o wa ni ayika rẹ, o rọrun fun un lati gba Isilaamu ki o si pa Isilaamu rẹ mọ títí ti Ọlọhun yoo fi ṣe oju ọna daadaa ni irọrun fun un ti yoo da wa nibẹ fun ara rẹ ti o si maa fi Isilaamu rẹ han.
Ninu nnkan ti o jẹ dandan fun ọmọniyan ni lati gba Isilaamu ni kíákíá, ṣùgbọ́n ko jẹ dandan lati sọ fun ẹni ti o wa ni ayika rẹ pẹlu gbigba Isilaamu rẹ tabi ki o fi han, ti o ba ṣe pe inira maa wa nibi ìyẹn fun un.
Lọ mọ pe dajudaju ọmọniyan ti o ba gba Isilaamu yoo jẹ ọmọ iya fun mílíọ̀nù awọn Mùsùlùmí, ti yoo si rọrun fun un lati kan si mọsalasi tabi ile-iṣẹ ti Isilaamu ni ilu rẹ ti yoo si beere fun imọran lọdọ wọn ati iranlọwọ ti ìyẹn yoo si dun mọ wọn ninu.
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿وَمَنْ يَتَّقِ اللَّهَ يَجْعَلْ لَهُ مَخْرَجًا {Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fún un ní ọ̀nà àbáyọ (nínú ìṣòro).وَيَرْزُقْهُ مِنْ حَيْثُ لَا يَحْتَسِب﴾ Ó sì máa pèsè fún un ní àyè tí kò ti rokàn.}[At-Tolāq: 2, 3]
Irẹ oluka alapọn-ọnle
Ṣe kii ṣe pe yiyọ Ọlọhun Adẹdaa ninu - Ẹni ti O ṣe idẹkun fun wa pẹlu gbogbo idẹra Rẹ, ti O n fun wa ni jijẹ nígbà tí a wa ni ọlẹ ninu ikun awọn iya wa ti O si tun n pese atẹgun ti a n fa simu fun wa báyìí- ṣe kii ṣe pe yíyọ Ọ nínú ni o pataki ju iyọnu awọn eeyan si wa lọ ni?
Ṣe kii ṣe erenjẹ aye ati ọjọ ikẹyin ni o tọ lati fi gbogbo nkan ti ko to o ni awọn adun aye ti yio tan silẹ fun un ni? Bẹẹ lo ri o, mo bura pẹlu Ọlọhun!
Nitori naa ko tọ ki ọmọniyan o jẹ ki iṣẹmi rẹ ti o ti lọ o kọdi rẹ lati ṣe atunṣe aṣiṣe rẹ ati lati ṣe nkan ti o tọ.
Ki ọmọniyan o yaa jẹ olugbagbọ ododo (tootọ) ni òní! Ki o si ma fun satani ni aaye lati da a lọ́wọ́ kọ́ kuro nibi itẹle ododo!
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:﴿يَا أَيُّهَا النَّاسُ قَدْ جَاءَكُمْ بُرْهَانٌ مِنْ رَبِّكُمْ وَأَنزلْنَا إِلَيْكُمْ نُورًا مُبِينًا (174) {Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. A sì tún sọ ìmọ́lẹ̀ t'ó yanjú kalẹ̀ fun yín (174)فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا بِاللَّهِ وَاعْتَصَمُوا بِهِ فَسَيُدْخِلُهُمْ فِي رَحْمَةٍ مِنْهُ وَفَضْلٍ وَيَهْدِيهِمْ إِلَيْهِ صِرَاطًا مُسْتَقِيمًا﴾ Ní ti àwọn t'ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, tí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì Í, Ó máa fi wọ́n sínú ìkẹ́ àti ọlá kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó sì máa fi wọ́n mọ ọ̀nà tààrà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.}[An-Nisā': 174-175].
Njẹ o ṣetan lati ni ìpinnu ti o tobi ju ninu iṣẹmi aye rẹ?
Ti o ba ṣe pe gbogbo eyi ti o ṣíwájú ba laakaye mu, ti ọmọniyan ti da òtítọ́ mọ ninu ọkan rẹ; o jẹ dandan fun un lati gbe igbesẹ akọkọ láti di Musulumi.
Ẹni ti o ba fẹ iranlọwọ lori ṣiṣe eyi ti o daa julọ ninu ipinnu ni iṣẹmi aye rẹ ati ìtọ́sọ́nà rẹ lọ si bi o ṣe maa di Musulumi
Ki o maa jẹ ki awọn ẹṣẹ rẹ maa kọdi rẹ kuro nibi wiwọ inu Isilaamu, ati pe Ọlọhun ti sọ fun wa ninu Kuraani pe Oun maa fori jin awọn ẹṣẹ ọmọniyan patapata ti o ba gba Isilaamu ti o si ronupiwada lọ sọ́dọ̀ Adẹdaa rẹ, koda lẹyin gbigba Isilaamu rẹ, Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan, nítorí pé èèyàn ni wá kì í ṣe áńgẹ́lì tí kò lè ṣàṣìṣe.Ṣùgbọ́n nnkan ti wọn n wa lọdọ wa ni ki a tọrọ aforijin lọdọ Ọlọhun ki a si ronupiwada lọ sọ́dọ̀ Rẹ, ti Ọlọhun ba ti ri lara wa pe a tete lọ gba ododo ti a si wọnu Isilaamu, ti a si ti pe ijẹrii mejeeji, dajudaju O maa kun wa lọwọ lori gbigbe awọn ẹṣẹ miiran ju silẹ, ẹni ti o ba dojú kọ Ọlọhun ti o si tẹle ododo, O maa fi i ṣe kongẹ fun alekun daadaa, nitori naa ki ọmọniyan ma ṣe iyemeji nipa wiwọnu Isilaamu nsinyii.
Ninu awọn ẹri ìyẹn ni ọrọ Rẹ- ti ọla Rẹ ga- pé:﴿قُلْ لِلَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ يَنْتَهُوا يُغْفَرْ لَهُمْ مَا قَدْ سَلَفَ﴾ (Sọ fún àwọn t'ó ṣàì gbàgbọ́ pé tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), A máa ṣàforíjìn ohun t'ó ti ré kọjá fún wọn)[Al-Anfal, Ayah 38].
Ki ni nnkan ti mo maa ṣe lati di Musulumi?
Wiwọnu Isilaamu àlámọ̀rí rẹ rọrun ti ko bukaata si awọn ààtò ìsìn tabi awọn àlámọ̀rí kan tí o ba ofin mu, tabi loju ẹnikẹni, nnkan ti o jẹ dandan fun ọmọniyan nikan ni ki o pe ijẹrii mejeeji ni ẹni ti o mọ ìtumọ̀ rẹ ti o n ni igbagbọ ninu rẹ, ìyẹn ni ki o sọ pe: (Ash-hadu an laa ilaaha illallohu wa ash-hadu anna Muhammadan rosuulullah), ti o ba rọrun fun ẹ lati sọ ọ pẹlu ede Lárúbáwá o daa bẹ́ẹ̀, ti ìyẹn ba nira fun ẹ, o ti to ki o pe e pẹlu ede rẹ, pẹlu ìyẹn waa di Musulumi, lẹyin naa o jẹ dandan fun ẹ lati kọ ẹsin rẹ ti o maa jẹ ipilẹ oriire rẹ ni aye ati igbala rẹ ni ọrun.
Tani o da agbaye? Taa si ni o da mi? Ati pe ki ni idi ti o fi da mi?
Oluwa Adẹdaa Olupese yii ni Allahu- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga-
Oluwa Ọba ti a n jọsin fun jẹ́ Ẹniti O ni awọn iroyin pipe
Nitori ki ni Adẹdaa ti O tobi yii ṣẹ dá wa? Ati pe ki ni nnkan ti O n fẹ lati ọdọ wa?
Nitori ki ni awọn ojiṣẹ ṣe pọ?
Eniyan ko lee di olugbagbọ titi yoo fi ní igbagbọ ninu gbogbo awọn ojiṣẹ
Ki ni nnkan ti maa ṣe anfaani rẹ latara wiwọ inu Isilaamu?
Ki ni nnkan ti mo maa padanu ti mo ba kọ lati gba Isilaamu?
Ki ni nnkan ti o jẹ dandan fun mi lati jẹ ki n di Musulumi?
Ko si awawi fun ẹni ti o ba gbe òtítọ́ silẹ ti o wa wo awokọse awọn baba ati awọn baba baba
Njẹ o ṣetan lati ni ìpinnu ti o tobi ju ninu iṣẹmi aye rẹ?
Ki ni nnkan ti mo maa ṣe lati di Musulumi?